Akẹ́kọ̀ọ́ Covenant University jáde láyé níbi tó ti ń gbá bọ́ọ̀lù, Ilé ẹ̀kọ́ ṣàlàyé ohun tó fa ikú rẹ̀

Iwájú ìta ilé ẹ̀kọ́ gíga Covenant University

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Covenant University ti sọ̀rọ̀ lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́, Toluwase Jesutunmise Emmanuel, tí wọ́n ṣàlàyé ohun tó ṣokùnfà ikú akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Keje, oṣù Kẹrin, ọdún 2026 ni òkíkí ikú Jesutunmise Emmanuel gba orí ayélujára, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń fẹ̀sùn kàn pé ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì náà lọ́wọ́ nínú ikú rẹ̀.

Ìròyìn tó gba orí ayélujára ni pé lásìkò tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ń kópa nínú bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ló déédé ṣubú lulẹ̀, tí kò sì tètè rí ìtọ́jú tó fi gba ibẹ̀ jáde láyé.

Ohun táwọn èèyàn ń sọ lórí ayélujára ni pé ilé ìwòsàn tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà kò ní 'oxygen' tí akẹ́kọ̀ọ́ náà nílò ló ṣokùnfà ikú rẹ̀.

Àmọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà ti wá jiyàn ẹ̀sùn náà.

Báwo ni ikú Emmanuel ṣe jẹ́?

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, Emmanuel, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Tunmise, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ìpele àṣekágbá ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ 'Building Technology' ṣàdédé ṣubú lulẹ̀ lásìkò tó ń kópa níbi ìdíje bọ́ọ̀lù láàárín ẹ̀ka ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti ẹ̀ka ẹ̀kọ́ 'Computer Engineering' fún ìdíje Chancellor Cup.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan fẹ̀sùn kàn pé wọ́n sáré gbé Emmanuel lọ sílé ìwòsàn ilé ẹ̀kọ́ náà ṣùgbọ́n wọn kò ní oxygen láti fi tètè du ẹ̀mí rẹ̀.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ pé dípò kí wọ́n tètè wá bí wọ́n ṣe máa mójútó, níṣe ni àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní gba àdúrà fún-un títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀.

Ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Okime lórí ìkànnì X, tó pe ara rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ Emmanuel sọ̀rọ̀ sí àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà tó sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé àwọn ni wọ́n pa ọ̀rẹ́ òun.

A ò fi ìlera Emmanuel tàfàlà, ẹ̀mí ti bọ́ lọ́rùn rẹ̀ kó tó dé ilé ìwòsàn - Covenant University

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àmọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà ti jiyàn ẹ̀sùn yìí bí wọ́n ṣe ní àwọn kò fi ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ náà tàfàlà gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń lọ lórí ayélujára.

Àtẹ̀jáde tí ilé ẹ̀kọ́ náà fi sójú òpó X lọ́jọ́rú sọ pé àìsàn ọkàn tí wọn dárúkọ rẹ̀ ló ṣekúpa Emmanuel lòdì sí ìròyìn tó gba orí ayélujára.

Nínú àtẹ̀jáde náà ni gíwá àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Timothy Anake ti júwe Emmanuel bíi akẹ́kọ̀ọ́ tó já fáfá nígbà ayé rẹ̀.

Ilé ẹ̀kọ́ náà ṣàlàyé pé Emmanuel dáwọ́ dúró díẹ̀ láti sinmi lásìkò tí wọ́n ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ eré bọ́ọ̀lù kan lọ́wọ́ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹrin.

Wọ́n ní ó pinnu láti sinmi lẹ́yìn tó ní ẹsẹ̀ ń dun òun àti pé ó ti rẹ̀ òun.

"Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ ni àwọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀ ri pé kò mí mọ́ dáadáa, tí wọ́n sì sáré gbe lọ sí ilé ìwòsàn tó wà ní ẹ̀gbẹ́ pápá ìṣeré tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù náà.

"Ṣùgbọ́n ó ti jáde láyé nígbà tí wọ́n fi máa gbe dé ilé ìwòsàn náà."

Ilé ẹ̀kọ́ náà, tó jẹ́ ti ọkàn lára àwọn pásítọ̀ tó gbajúmọ̀ ní Nàìjíríà, Bíṣọ́ọ̀bù David Oyedepo sọ pé kìí ṣe pé àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún fi ọ̀rọ̀ ìlera Emmanuel ṣeré rárá.

Wọ́n ṣàlàyé pé ẹ̀mí ti bọ́ lọ́rùn Emmanuel kó tó di pé wọ́n gbe dé ilé ìwòsàn rárá, wọ́n sọ pé àwọn dókítà gbìyànjú láti du ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n gbogbo ìgbìyànjú wọn ló já sí pàbó.

Ilé ẹ̀kọ́ náà tún sọ pé kò sí ohun èlò ìtọ́jú kankan tí kò pé sí ilé ìwòsàn àwọn, bí wọ́n ṣe ní gíwá àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà àtàwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún ni wọ́n wà nílé ìwòsàn náà títí tí àwọn òbí ọmọ náà fi wá gba òkú rẹ̀, tí wọ́n fi sín.

Wọ́n ní àwọn bá ẹbí, ọ̀rẹ́ àtàwọn olólùfẹ́ Emmanuel kẹ́dùn lórí ikú rẹ̀.

Bákan náà ni ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ náà, lójú òpó Instagram, ṣe ìdárò Emmanuel, tí wọ́n sì ní àwọn máa ṣe àfẹ́kù rẹ̀ gidi.

Ikú akẹ́kọ̀ọ́ ní Covenant University

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí akẹ́kọ̀ọ́ yóò pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní Covenant University, èyí tó máa ń mú auyewuye dání.

Ní oṣù Kẹfà ọdún 2025 ni àrá san sán akẹ́kọ̀ọ́ ipele keji ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ kan, Mordi Nwense Daniel tó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn nígbà náà fẹ̀sùn kàn pé, káká kí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gbé Daniel lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú, níṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní gbàdúrà fún-un.

Wọ́n ní nígbà tí wọ́n fi máa padà gbe dé ilé ìwòsàn, ó ti pẹ́ jù, tó sì jáde láyé.

Irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó jọ bẹ́ẹ̀ náà wáyé lọ́dún 2017 nígbà ti akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ipele àṣekágbá, Segun Micheals forí gbalẹ̀ níbi tó ti ń lùwẹ́, tí òun náà sì gba ibẹ̀ kú.