Certificate forgery: Olùpẹ̀jọ́ ni òun kò ṣẹjọ́ mọ pẹ̀lú gómìnà Kwara

Kwara state Governor

Oríṣun àwòrán, Abdulrahaman official

Àkọlé àwòrán, Sááju àsìkò yiìí ni Abdulrazaq ti ni ìppejọ́ náà ni ọwọ́ òṣèlú nínú ti ó sì fẹ́ dènà ati dibò wolé gẹ́gẹ́ bi gomina ìpínlẹ̀ Kwara to wáye ninu oṣù kẹta

Ilé ẹjọ́ giga to fi ilu Ilọrin se ibujoko, ti wọgile ẹjọ kan to ni gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, lo ayederu sabuke láti fi dije dupo Gomina ni ipinlẹ Kwara. Èyí wáye lẹ́yìn ti olùpẹjọ ní òun ko ṣe ẹjọ mọ.

Lásìkò tó n da ẹ́jọ naa, adájọ Adenike Akinpelu ni Adekunle Abraham, to jẹ ọmọ ẹgbẹ òṣèlú People's Democratic Party( PDP) to pe ẹjọ náà, ti kọ̀wé si ilé ẹjọ pe oun ko ṣẹjọ mọ.

Sááju àsìkò yiìí ni Abdulrazaq ti ni ìpejọ́ náà ni ọwọ́ òṣèlú nínú, tó sì fẹ́ dènà ìyànsipò òun gẹ́gẹ́ bi gomina ìpínlẹ̀ Kwara, eyi to wáye ninu loṣù Kẹta ọdun 2019.