Wo àwọn ẹlẹ́sẹ̀ ayò ti wọ́n ti rọ́wọ́mú nidije World Cup

Agbabọọlu Uruguay
Àkọlé àwòrán, Eyi kọja bẹẹ, gbogbo ara la fi n gbá bọọlu lasiko yii
Published

Ìdíje mẹrin ló ti wáyé báyìí látigba ti World cup 2018 ti bẹ̀rẹ̀ ni Russia.

Ìdije laarin orilẹ-ede Russia to ń gbàlejò àti Saudi Arabia ni wọn kọkọ fi ṣide ife ẹyẹ agbaye World Cup 2018.

Lẹyin èyí ni àwọn orilẹ-ede mẹfa miran jọ ná an tán bi owó pẹlu èsì wọnyii:

Awọn orilẹ-ede to gbegba oroke ri atilẹyin awọn ẹlẹse ayo bii:

  • Jose Gimenez ati Carlos Sanchez fun Uruguay ti wọn fi jawe olubori.
  • Ẹlẹ́sẹ̀ oró, Aziz Bouhaddouz, ti Morocco to ṣeeṣi gba bọọlu naa sáwọ̀n ile ara rẹ (Morocco).
  • Cristiano Ronaldo to gba bọọlu sáwọ̀n Spain lẹẹmẹta ọtọọto
  • Diego Costa gba meji sáwọ̀n Portugal.
  • Nacho Fernandez gba ọkan sáwọ̀n Portugal ti wọn fi ta ọmi.

Èyí ni díẹ̀ lára àwọn àwòràn àwọn ẹlẹ́sẹ̀ ayò náà lẹnu iṣẹ́ wọn lọkọọkan:

Awon agbabọọlu Russia n yọ
Àkọlé àwòrán, Idunnu ṣubu layọ lẹyin ti Russia sọ bọọlu sáwọ̀n Saudi Arabia
Agbabọọlu Uruguay
Àkọlé àwòrán, 'A kò róhun fáyọ̀ bi ko ba ṣe ọpẹ'
agbaboolu
Àkọlé àwòrán, Ìdí iṣẹ́ ẹni la ti ń mọ ni lọ́lẹ́, ọrọ eré bọọlu ti gba ìṣirò bayii.
Agbabọlu loju iṣẹ
Àkọlé àwòrán, 'Bóò lọ, o yàá mi ni ìṣesí àwọn agbabọọlu to n kopa ninu ìdíje World Cup 2018 ni Russia'
agbboọlu
Àkọlé àwòrán, Ẹni à ń bá ná ọjà là ń wò, a kìí wo ariwo ọjà ràrà ló bá dé nńú ìdíje ife ẹyẹ àgbáyé 2018
Cristiano Ronaldo
Àkọlé àwòrán, Ronaldo ti Portugal, ẹlẹ́sẹ̀ ayò ilẹ̀ Portugal lo ti gbá àmì ayò tó pọ̀jù lọ (3) nidije
Agbabọọlu to n fi gbogbo ara gbaa
Àkọlé àwòrán, Ìrìrì kọjá ẹgbẹ́ abewu lọrọ eré bọọlu di bayii
Awọn agbabọọlu
Àkọlé àwòrán, Ayọ̀ ti kò lẹ́gbẹ́ ni ti èèyàn sọ bọọlu sáwọ̀n ẹlomii
Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Gbolahan Kabiawu: Fífi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ dára fún ẹ̀yà ara
loju ile Amule
Àkọlé àwòrán, Ajanaku kọja mo ri nkan firi ni idje bóólu di bayii