'Mi ò tiẹ̀ mọ ibi ti mo ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀,' MoBimpe sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó bí ìbẹ́ta

Tọkọtaya Adedimeji pẹlu awọn ibẹta wọn ati aworan ọmọ lọwọ MoBimpe

Oríṣun àwòrán, MoBimpe/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Inu ẹni ki I dun ka pa a mọra, paapaa nigba ti oore ojiji ti awọn kan ko fi gbogbo ara gbagbọ ba ṣẹlẹ sini.

Lori ikede ọmọ mẹta lẹẹkan ṣoṣo ti Lateef Adedimeji ati Bimpe Oyebade (Mo Bimpe) iyawo rẹ fi sita lọjọ Ẹti, Mo Bimpe ti jade sori ayelujara lati dupẹ lọwọ awọn to n ba wọn yọ latigba ti iroyin ayọ naa ti gbode.

Ana ode yii ti I ṣe ọjọ Abamẹta ni Mo Bimpe kọ ọrọ idupẹ si oju opo Facebook rẹ.

O kọ awọn ọrọ idupẹ naa lati fi bi inu rẹ ṣe dun to si awọn to n ba a yọ han, ko si tun le jẹ aridaju fun awon to n ṣiyemeji pe ṣe loootọ ni oṣere tiata naa bi ibẹta lẹyin ọdun marun-un igbeyawo.

Mo Bimpe dúpẹ́ lọ́wọ́ àwon olólùfẹ́ rẹ̀, lẹ́yìn ìkéde ìbẹ́ta tó bí

Ọrọ idupẹ ti Mo Bimpe kọ si oju opo Facebook rẹ.

Oríṣun àwòrán, Mo Bimpe/ Facebook.

Loju opo Facebook rẹ to ti fi ẹmi imoore han ni Mo Bimpe ti kọ ọ pe:

"Àwọn ọrẹ, ẹbi titi kan awon ti a ko tiẹ mọ ri lo n ba wa yọ. Awọn kan tiẹ n sunkun paapaa. Mi o tiẹ mọ ibi ti mo ti le bẹrẹ.

"Mi o mọ bi mo ṣe fẹẹ dupẹ lọwọọ yin tan. Ifẹ ati idunnu lo yi mi kan.

" Ẹ jọwọ ẹ fun mi lasiko ki n le fi imoore han si kaluku."

Bẹẹ ni Mo Bimpe kọ ọ soju opo Facebook rẹ naa, to si tun fi aworan ibi ti oun ati Lateef ti gbe awon ibẹta naa si ẹsẹ han, pẹlu ibusun ti wọn ṣe fun awọn ọmọ mẹtẹẹta.

Ṣe loootọ ni Mo Bimpe gbe oyun ibẹta naa funra rẹ ?

Mo Bimpe, ọkunrin kan ati Lateef

Oríṣun àwòrán, Mo Bimpe /Facebook

Latigba ti iroyin ibẹta naa ti gbode ni awọn kan ti n sọ pe ilana iṣegun oyinbo ti obinrin fi n loyun, ti a mọ si IVF, ni Lateef ati Mo Bimpe fi bi ibẹta.

Igbagbọ awon wọnyi ni pe bi eeyan ba ti n wa oyun fun ọdun pipẹ, to ba bimọ to ju ẹyọkan lọ lẹẹkan naa bi eyi, IVF lo wa nidii rẹ.

Wọn gbagbọ pe awọn obinrin kan ki I le da oyun ọhun gbe, ati pe awọn ti a mọ si (surrogate mother) lo maa n ba wọn gbe e ti oyun naa yoo fi too bi lọmọ.

Eyi ni awuyewuye fi gbode lẹyin ti awon tọkọtaya yii kede pe awon bi ibẹta.

Amọ Mo Bimpe funra rẹ kọ ọ soju opo Facebook rẹ, pe oyun fi oju oun ri nnkan, amọ ju gbogbo ẹ lọ, Oluwa ni ọpẹ tọ si.

"Igba wo ni Mo Bimpe loyun debi ti yoo bi ibẹta"

Mo Bimpe pẹlu ẹnu rẹ to wú, oyun rẹ ti Lateef di mu lo wa ni aworan keji, Bimpe so mọ Lateef latẹyin nibi kẹta, nigba ti wọn jọ tẹ awọn ibẹta si ẹsẹ ninu aworan kẹrin.

Oríṣun àwòrán, Mo Bimpe/Facebook

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun ti awon kan n beere leyi, lẹyin ẹgan ati ọrọ buruku ti won ti sọ si Mo Bimpe lori ayelujara pẹlu aibimọ rẹ latigba to ti ṣegbeyawo.

Bẹẹ ni awon miran n sọ pe o daju pe ẹnikan lo ba tọkọtaya Adedimeji gbe oyun naa, pe Mo Bimpe ko gbe oyun kankan.

Ṣugbọn ọpọ fidio ati aworan lo wa lori ayelujara, to jade lẹyin ikede ibẹta yii, to n to ṣafihan Bimpe pẹlu oyun.

Inu oṣere naa tobi daadaa ninu awon foto ati fidio mi-in, bẹẹ ni gbogbo ara rẹ jo ti oloyun pẹlu.

Awọn fidio kan tilẹ wa to jẹ pe oko ere ti a mọ si Location ni Mo Bimpe wa ninu rẹ, pẹlu inu rẹ to ri gẹrugẹru, ti ọkọ rẹ si wa lẹgbẹẹ rẹ.

Tẹ o ba si gbagbe, agba oṣere ilẹ wa kan, Jaye Kuti, ti kọkọ kede pe tọkọtaya Adedimeji ti di ọlọmọ laye, iyẹn ni nnkan bii oṣu Kẹta ọdun yii.

Ọpọ awon akoroyin ori ayelujara lo sare gbe iroyin naa nigba naa, amọ ko pẹ rara ti Jaye Kuti tun fi pa ikede naa rẹ loju opo re, ti awon to ti kọkọ gbe e jade si tọrọ aforiji fun ṣiṣẹ bẹẹ.

Ṣugbọn lọtẹ yii, lati ijẹta Tọkọtaya Adedimeji ti kede iroyin ibẹta yii, wọn ko jiyan pe ko ri bẹẹ, wọn ko si pa ikede naa rẹ loju opo wọn.

Kaka bẹẹ, ikini ku oriire lo gba oju ayelujara kan.

Awọn to n ba wọn yọ ni tootọ ko janpata nipa ọna ti awon ibẹta gba wa saye, adura pe ki awọn ọmọkunrin mẹta to de naa ba wọn kalẹ ni won n ṣe fun wọn.

Ọpọ awọn oṣere bii Ọga Bello, Mama Ereko, Dayo Amusa, Wolii agba, Itele ati bẹẹ bẹẹ lọ lo ti ki Baba ati Iya Ibẹta Adedimeji ku ayọ ọmọ.

Tọkọtaya gbajúmọ̀ òṣèré, Lateef Adedimeji àti aya rẹ̀, Adebimpe bí ìbẹta

Lateef Adedimeji ati aya rẹ, Mobimpe

Oríṣun àwòrán, Adedimeji Adetola Lateef/InstagramLateef

Yoruba ni lẹyin onisuuru ni Ọlọrun wa tori bi ẹkun pẹ titi di alẹ, ayọ n bọ ni owurọ.

Bẹẹ ni ọrọ ri ni agboole tiata bayii bi gbajumọ osere meji se gbalejo ọmọ tuntun mẹta lanti-lanti.

Lateef Adedimeji ati aya rẹ, Adebimpe Oyebade Adedimeji si ni Ọlọrun fi ẹbun ọmọ mẹta kẹ ni ẹẹkan soso.

Baba ati iya ibẹta naa si ni ọpọ awọn ololufẹ wọn ti n ki ku oriire naa.

Bawo ni ikede ayọ naa se de ori ayelujara?

Baba ibẹta, Lateef Adedimeji lo fi ikede naa sori ayelujara ninu fidio kan to gbe soju opo Instagram rẹ ni owurọ oni, ọjọ kini osu karun ọdun 2026.

Ninu fidio naa la ti ri Lateef ti aya rẹ fi ọwọ kọ lọrun, ti wọn si dijọ de fila ti wọn kọ akọle Baba ati Mama si lori.

Iya ibẹta, to so ọwọ mejeeji mọ ọkọ rẹ lọrun, lo mu ayẹwo ọmọ mẹta lọwọ, pẹlu aworan fila mẹta, ibọsẹ mẹta ati ibọwọ mẹta.

Koda, orin awa ti bimọ, dandan ni ka yọ fun Ọlọmọ ni wọn kọ sori fidio naa.

Lara ohun ti Lateef kọ sinu fidio naa niyi:

"Awọn ọmọ Adedimeji, a ti n fi nnkan pamọ fun yin.

Lọdun 2026 yii, Ọlọrun fun wa ju ohun ti a beere lọwọ Ọlọrun.

Obinrin yii ti fun mi ni ọmọ mẹta ti maa pe ni awọn ọmọ mi, ọba mẹta ti wọn jẹ ojuse mi"

Ọpọ eeyan si lo ti n ki baba ati iya mẹta naa ku oriire.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Awọn eeyan ti bu ẹnu atẹ lu Mo Bimpe, ti wọn ti pe e ni agan tẹlẹ, ti wọn to ki ku ayọ ọmọ mẹta bayii

Ọkan lara awọn oṣere tiata ti awọn eeyan fẹran pupọ bii lọkọlaya ni Lateef Adedimeji ati Mo Bimpe.

Latigba ti wọn ti ṣegbeyawo lọdun 2021 ni wọn ti di ẹni ti ọpọ eeyan n fẹran lori ayelujara fun bi wọn ṣe jọ maa n ṣiṣẹ pọ.

Bi iroyin ayọ si ṣe bẹrẹ si i ti idile Adedimeji jade wa bayii, niṣe ni gbogbo aye n ki wọn ku oriire aladipele to wọle tọ wọn wa.

Awọn eeyan ti wọn si ti bu ẹnu atẹ lu Mo Bimpe, ti wọn ti pe e ni agan tẹlẹ ti n ki I ku ayọ ọmọ mẹta bayii.

Bẹẹ ni wọn n pe Lateef naa ni Baba Ibẹta lẹẹkan ṣoṣo

Lateef Adedimeji wọ agbada toke tilẹ funfun, o de fila asọ oke Ẹtu, o si fi ilẹkẹ pupọ sọrun

Oríṣun àwòrán, Lateef Adedimeji/Facebook

Ta a ni Lateef Adedimeji?

Lateef Adetola Adedimeji jẹ ọmọ bibi ilu Abeokuta, ọjọ Kin-in-ni oṣu Keji ọdun 1986 ni wọn bi i.

Ọdọ langba lo wa to ti bẹrẹ si I kopa ninu ere ori itage. Ọpọ ami ẹyẹ lo si pada gba, bo tilẹ jẹ pe o ti figba kan jẹ ẹni ti aye ko mọ ri.

Lateef kẹkọọ gboye ninu iṣẹ iroyin.

Oṣere tiata to mọ bi wọn ṣe n gbe ipa ọlọkan-o-jọkan kalẹ ni, paapaa to ba di abala ki eeyan sunkun bii pe ohun to n ṣẹlẹ ninu fiimu naa n ṣẹlẹ si I loju aye ni.

Adedimeji ti kopa ninu ọpọ ere Yoruba, odu ni nibẹ ko too di pe oun ati iyawo rẹ, Mo Bimpe fi ifẹ wọn han saye.

Nibẹrẹ ajọṣepọ Lateef ati Bimpe, wọn fi ifẹ naa pamọ.

Bi ọpọ akọroyin to n ri wọn pọ si ṣẹ n beere pe ṣe ifẹ wa laaarin wọn ni, niṣe ni awọn mejeeji maa n sọ pe iṣẹ lo da awọn pọ, ifẹ kọ.

Ṣugbọn nigba ti 2021 n lọ sopin, Lateef ati Mo Bimpe kede pe awọn fẹ ṣegbeyawo, wọn si pada ṣe e loṣu Kejila ọdun 2021.

Latigba naa ni awọn eeyan ti n foju sọna pe ki wọn di ọlọmọ laye, amọ ko ri bẹẹ.

Ko too di ọjọ kin-in-ni oṣu Karun-un ọdun 2026 yii, ti Lateef kede pe oun ati Mo Bimpe ti di Baba ati Iya Ibẹta!

Adebimpe Oyebade Adedimeji wọ kaba leesi funfun ati gele rẹ

Oríṣun àwòrán, ADEBIMPE OYEBADE her/Instagram

Ta a ni Mo Bimpe?

Adebimpe Oyebade gan-an ni orukọ rẹ, ọmọ bibi Ijero Ekiti, nipinlẹ Ekiti ni.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta ọdun 1997 ni wọn bi i.

Adebimpe kẹkọọ gboye ninu ede oyinbo nile ẹkọ Fasiti ipinlẹ Ekiti.

Oṣere tiata ni Bimpe Oyebade tawọn eeyan mọ si Mo Bimpe, bẹẹ lo si tun mọ nipa irin oge (Modelling).

Oniṣowo ni pẹlu.

Ọdun 2016 lo di gbajumọ oṣere lagbo tiata Yoruba, ti wọn n lo o ninu awọn sinima ọlọkan -o-jọkan kiri.

Oun ati Lateef Adedimeji ti wọn jọ maa n wa papọ, ti aarin wọn si gun rege ni wọn pada jọ fẹra wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn mejeeji maa n sọ pe ko si nnkan kan laarin awon ju iṣẹ tiata lọ ni.

Wọn ṣegbeyawo loṣu Kejila ọdun 2021, amọ ko si ọmọ ninu ajọṣepọ naa fun ọdun marun-un gbako.

Ọpọ igba ni awon eeyan ti sọrọ kobakungbe si Mo Bimpe lori ayelujara pẹlu aitete bimọ rẹ.

Bawọn kan ṣe sọ pe o ti lo ile ọmọ rẹ fun okiki ni ẹnikan sọ fun un ri pe ko ni itiju ati irori rara.

Ẹni naa sọ pe Bimpe ko mọ ju aṣọ lọ.

Ṣaaju Ibẹta to bi yii, iroyin ti jade ri pe oṣere naa loyun, awọn mi-in si ṣo pe o ti bimọ.

Ṣugbọn Lateef ati iyawo rẹ ko fidi iru rẹ mulẹ ri, afi ni bayii ti ọkọ gbe fidio jade, to n kede ibẹta lantilanti.