Ọdún méjìdínlógún ni mo fi wojú Ọlọ́run fọ́mọ kí n tó bí ìbejì - Ricardo Agbor

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gbajumọ oṣere tiata, Ricardo Agbor ti ṣalaye ohun ti oju rẹ leyin ko to di ọlọmọ laye leyin ọdun mejidinlogun to ṣegbeyawo.
Ninu ifọrọwerọ kan ti agba oṣere naa ṣe pẹlu AfricanAList lo ti ṣalaye irinajo rẹ ninu sinima ṣiṣe ati igbeaye rẹ lai si ninu sinima.
Nibẹ naa lo tun ti sọrọ nipa ilakaka rẹ ko to di ọlọmọ laye ati bi oun ati iyawo ṣe woju Ọlọrun fọmọ fun ọpọ ọdun lẹyin igbeyawo.
O sọ pe bi o tilẹ jẹ pe oun ati iyawo oun ko wa lati iran kan naa ṣugbọn awọn ko ri idaamu kankan lasiko ti awọn n duro woju Ọlọrun fun ọmọ naa.
O ni lati kekere lo ti maa n wu oun lati bi ibeji, ti oun si gbadura fun ibeji ni gbogbo asiko ti oun n duro de oore Ọlọrun naa ti Ọlọrun si gba adura nigba to maa fi ọmọ ta oun lọrẹ.
"Ọdun mejidinlogun ni mo fi duro ki n to bi awọn ibeji ti Ọlọrun fun mi, mo duro de asiko Ọlọrun, Ọlorun gan mọ pe mo duro, Ọlọrun si fun mi ni awọn ibeji ti mo n beere fun.
"Ni gbogbo igba igba ti mo n woju Ọlọrun fun ọmọ, to ba jẹ ẹlomii o ṣeeṣe ko ti tasẹ agẹrẹ ṣugbọn nigbẹyin, Ọlọrun pada fun mi ni ibeji. Mo ni ọkunrin ati obinrin, mo beere fun oun ti mo fẹ, Ọlọrun si fun mi."
Ricardo Agbor ni bi o tilẹ jẹ pe ọdun mejidinlogun ni oun fi duro ki oun to bimọ, awọn ọmọ naa ti pe ọdun mẹrinla bayii ti inu si maa n dun nigba ti oun ba ranti pe oun ko ṣi iwa wu nigba naa.
Ọjọ ti iya mi ku ni inu mi bajẹ laye
Nigba to n sọrọ nipa oun to dun-un julọ ni igbesi aye rẹ julọ, o ni ọjọ ti iya oun ku ni inu oun bajẹ julọ.
Agba oṣere naa ni iya oun ti n ṣe aarẹ fun bii ọsẹ mẹta laisi iyatọ kankan tawọn dokita si gba oun nimọran lati gbe iya oun lọ si South Africa fun itọju.
O ni nigba ti ko si ayipada kankan lori ilera iya oun ni iya oun sọ fun pe ki wọn gbe oun lọ si ile iwosan mii ninu Surulere ṣugbọn ti iya naa pada dakẹ mọ oun lọwọ nigba ti awọn n gbe sinu ọkọ lati gbe lọ sile iwosan mii.
"Ọwọ mi ni iya mi dakẹ si. Ni ile iwosan, awọn dokita to le ni mẹwaa lo wa n ṣe ayẹwo lara iya mi, a ko ri ayipada lẹyin ọsẹ mẹta.
"Lẹyin ọsẹ mẹta ni wọn sọ fun mi pe ki n gbe iya mi lọ si South Africa fun itọju to peye.
"Mo gbe iya mi lọ si ile iwosan mii ninu Surulere, iya mi lo sọ fun mi funra rẹ pe ki n gbe oun kuro nibẹ.
"Bi mo ṣe n gbe kuro nile iwosan naa lọ sinu ọkọ lo dakẹ mọ mi lọwọ."
Agbor tẹsiwaju pe iku iya oun naa mu ki ọkan oun poruru ati pe igba naa ni oun sunkun fun akọkọ lai ṣe pe oun n ṣere.
"Mo le sọ pe igba akọkọ ti mo sunkun ninu igbe aye mi, mi o kii sunkun. Ti mo ba sunkun boya ninu ere ni amọ mo sunkun nigba ti iya mi ku.
"O jẹ oun to dun mi gidi."




























