APC kéde ₦100m bíi owó fọ́ọ̀mù ìdíje ipò ààrẹ, làwọn ọmọ Nàìjíríà bá pariwo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni imurasilẹ fun idibo ọdun 2027 to n bọ lọna, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ti kede pe miliọnu lọna ọgọrun-un kan naira, ₦100m ni owo gbigba fọọmu lati dije fun ipo aarẹ.

Bakan naa ni APC kede ọjọ keẹẹdogun ati ikẹrindinlogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii bii ọjọ ti idibo abẹle (Primary election) ẹgbẹ naa yoo waye.

Akọwe eto apapọ fun APC, Sulaiman Argungu lo buwọlu awọn ikede yii, ti Felix Morka,Akọwe apapọ ẹgbẹ si fi lede lọjọ Aje loju opo X ti i ṣe ti APC.

Ninu ikede naa ni wọn ti sẹ alakalẹ awọn eto naa bi yoo ṣe waye.

Tita fọọmu, ṣiṣe ayẹwo awon oludije ati bi idibo abẹle yoo ṣe waye fun awon ipo ọtọọtọ.

Bi fọọmu tita atawọn eto yoku yoo ṣe lọ

Gẹgẹ bi APC ṣe kede, fifẹ ifẹ han lati dije, tita fọọmu ọlọgọrun-un miliọnu naira fun ipo aarẹ yoo bẹrẹ lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin yii, yoo si pari lọjọ keji oṣu Karun-un ọdun 20026.

Dida fọọmu pada lẹyin ti oludije ti ra a to si ti buwọ lu u yoo wa sopin lọjọ kẹrin oṣu Karun-un.

Ayẹwo awon oludije yoo waye laaarin ọjọ kẹfa si ikẹjọ oṣu Karun-un ọdun 2026 bi wọn ṣe kede, nigba ti ikede esi yoo waye lọjọ kọkanla oṣu Karun-un, tawọn ti ko ba tẹ lọrun yoo si waye lọjọ kejila si ikẹta oṣu Karun -un kan naa.

Ibo abẹle ile igbimọ aṣoju yoo waye lọjọ kejidinlogun oṣu Karun-un, ti ile igbimọ aṣofin agba yoo waye ni ogunjọ oṣu Karun-un.

Eyi to wa fun ipinlẹ yoo waye lọjọ kọkanlelogun, nigba ti ibo abẹle awọn gomina yoo waye lọjọ ketalelogun oṣu Karun-un ọdun 2026 bii APC ṣe la a kalẹ.

Alaye lori owo fọọmu ọlọgọrun-un miliọnu naira

Fun awon oludije to fẹ dupo aarẹ ninu APC, ₦100 million ni won gbe e si pẹlu alaye pe ọgbọn miliọnu (30m) wa fun fifi ifẹ han lati dije, nigba ti aadọrin miliọnu (₦70 million) wa fun ifanikalẹ.

Fun awon to fẹ dupo gomina, aadọta miliọnu naira (₦50 million) ni owo fọọmu, nigba ti owo idije fun ile igbimọ aṣofin agba jẹ ogun miliọnu (N20M), ti awọn ti ile igbimọ aṣoju yoo si san miliọnu mẹwaa(N10 million).

"Awọn oludije obinrin, awọn ọdọ atawọn ti ẹya ara pe nija yoo sanwo fifi ifẹ han lati dije ati idaji owo ti a la kalẹ fun ipo kọọkan."

Bẹẹ ni atẹjade APC wi.

Wọn fi kun u pe ofin oriléede Naijiria ni awọn tele lati gbe alakalẹ eto naa jade, ati ofin eto idibo ile wa ti 2026, pẹlu itọni ajọ eleto idibo INEC.

Bo tilẹ̀ jẹ pe ko ti i si ọmọ ẹgbẹ APC kankan to fifẹ han lati ra fọọmu lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ, awọn agba ẹgbẹ kan ti ni awọn fontẹ lu Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati lọ fun saa keji rẹ.

Tinubu funra rẹ naa ko ti I kede gbangba pe oun yoo lọ fun saa keji, amọ o ṣo lọsẹ to kọja pe ẹru o bodo.

Aarẹ ni ẹru awọn alatako ko ba oun rara ni.