Òní lòní n jẹ́ nibi ètò òdun Sango tó ń wáyé nílùú Oyo Alaafin....

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Gbogbo eto lo ti to nibi asekagba ayẹyẹ ọdun Sango agbaye eyii ti o nwaye ninu gbagede to wa ninu aafin Alaafin Oyo.
Oba Akeem Owoade to jẹ Alaafin ti Oyo, ojo pa ṣẹkẹrẹ ọmọ Atiba lo n gbalejo gbogbo olujọsin ati ololufẹ oriṣa Sango kaakiri agbaye lonii nibi gbagede eto ọlọdọọdun naa.
Eto ọdun Sango ti 2026 lo ti bẹẹrẹ lati ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ, ọdun yii pẹlu oriṣiiriṣii eto.
Diẹ lara awọn to ti waye ṣaaju ni eto ti wọn ti ṣe ayajọ ọjọ Ọya, ṣiṣe ayajọ ọdun Aje eyi to ma n waye ninu ọja Akesan niluu Oyo nipinlẹ Oyo ni guusu iwọ oorun Naijiria.
Ọpọ eeyan lo ti n peju sibi ayẹyẹ yii ti yo kadi ayajọ naa nile fun ọdun 2026.

Gbogbo ohun to ba ṣẹlẹ nibẹ ni BBC yoruba yoo mu wa fun igbadun ẹyin ololufẹ rẹ


























