Gbajúgbajà Akéwì asùnjálá ọdẹ, Alabi Ogundepo jade láyé, àwọn mọ̀lẹ́bí sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Ayekooto Akindele/Facebook
Lasiko ti awọn eeyan ṣi n ṣe idaro agba oṣere nni, Taiwo Hassan tọpọ mọ si Ogogo to jade laye, paapaa nibi eto isinku rẹ, naa ni ogbontarigi akewi nni, Oloye Alabi Ogundepo tun faye silẹ lojiji.
Alabi Ogundepo lo jade laye lẹyin aisan rampẹ lẹni ọdun mẹrinlelọgọrin (84)
Awọn mọlẹbi agba akewi, onkọwe ati onkọtan naa lo kede iku ọmọ bibi ilu Saki nipinlẹ Oyo ọhun lọjọ Aje, ọsẹ yii.
Ogbontarigi ni Ogundepo, kii ṣamọ foloko nilẹ Naijiria, paapaa lagboole Akewi, amuludun, igbelarugẹ aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba.
Ninu atẹjade ti Dupe Ogundepo Falana fi sita lorukọ mọlẹbi naa lọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 lo ti sọ pe ẹdun ọkan ni iku baba naa jẹ fun wọn.
"Ọmọ bibi ilu Saki nipinlẹ Oyo, Oloye Alabi Ogundepo jẹ agba akẹwi olohun didun ninu Ewi ati kikọ, pẹlu idupẹ si aṣa Yoruba, iṣe, ede, itan ati iriri awọn ẹda," atẹjade naa sọ bẹẹ.
"Nipa awọn agbekalẹ lọna ara ọtọ, ati awujọ, o ko ipa to jọju nipa didaabo bo ati igbelarugẹ aṣa pẹlu iṣe ohun ajohunba awọn eeyan."
Mọlẹbi naa wa fi idunnu han si ọpọ awọn eeyan, ajọ, ileeṣẹ, awọn ọba alaye ati oloye, agboole ẹkọ aṣa, ọrẹ, to fi mọ awọn afẹnifẹre ti wọn ki wọn lori iku baba wọn.
Wọn jẹ ko di mimọ pe ipa rere ni Oloye Ogundepo fi silẹ ko too jade laye, ti wọn si lawọn ipa naa ko le ṣee gbagbe titi lai.
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn mọlẹbi yoo kede eto isinku laipẹ, ti wọn si n tọrọ pe ki awọn eeyan gbadura fun wọn.

























