Òṣìṣẹ́ báǹkì tó di ẹni tó ń ta pọ̀nmọ́ aláta lọ́jà nílùú Ibadan

Àkọlé fídíò, Òṣìṣẹ́ báǹkì tó di ni tó ń ta pọ̀nmọ́ lọ́jà nílùú Ibadan
Òṣìṣẹ́ báǹkì tó di ẹni tó ń ta pọ̀nmọ́ aláta lọ́jà nílùú Ibadan
Published

Akọṣẹmọṣẹ imọ nipa idiyele ati akoso ileegbe ni Ọgbẹni Adeloye Adekunle, Ile ifowopamọsi lo si ti n ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun ki ọrọ to ba ibomiran yọ fun un ti iṣẹ si bọ lọwọ rẹ. Ọna ati wa jijẹ mimu kiri lo mu ko ya ẹgbẹrun lọna ogun naira lọwọ iyawo rẹ lati fi bẹrẹ owo pọnmọ alata sise ta ti o fi di ẹni ti ọpọ eeyan mọ si pọnmọ alakọwe lọja Gbagi nilu Ibadan.

Ninu ifọrọwerọ yii, Ọgbẹni Adeloye Adekunle ṣalaye irinajo rẹ lati inu banki nibi ti owo gbe n so titi de idi aro nibi to ti n fi irungbọn fẹ ina pọnmọ alata.