Kí ni alága àjọ INEC ṣe tí MURIC ṣe yarí pé lílọ ni yóò lọ àmọ́ táwọn ọ̀dọ́ ìlú rẹ̀ ṣèwọ́de àtìlẹ́yìn fún un?

Awọn ọdọ to n se iwọde gbe akọle lọwọ lati se atilẹyin fun alaga ajọ INEC, Joash Amupitan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ MURIC to n ja fun ẹtọ awọn musulumi ti pe fun iyọnipo alaga ajọ eleto idibo INEC, Ọjọgbọn Joash Amupitan, lori ẹsun wi pe oun lo kọ iwe si orilẹede Amẹrika lati fidi rẹ mulẹ pe awọn alakatakiti ẹsin n ṣe inunibini sawọn kristẹni ni Naijiria.

MURIC sọ ninu atẹjade to fi sita wi pe ''inu wa ko dun pẹlu ijọba lori bi wọn ṣe dakẹ nipa ohun ti ajọ awọn musulumi beere wi pe ki wọn yọ alaga INEC nipo.

Eyi tumọ si pe ijọba ko ka ọrọ tawọn eeyan n sọ kun ni.

Awa musulumi ni Naijiria gbagbọ wi pe ko yẹ ki Amupitan si wa nipo alaga ajọ INEC ni Naijiria.

Koda, eto ayẹwo awọn oludibo ti alaga INEC n ṣagbatẹru rẹ dabi ọna lati fi ẹtọ awọn musulumi to ba fẹ dibo dun wọn.

Amupitan ti di nnkan to lewu to si le ṣakoba fawọn oludibo musulumi ni Naijiria.

''Orilẹede Naijiria ko le lọ siwaju ti awọn eeyan bii Amupitan ba si n dipo alaṣẹ mu"

O ti ta Naijiria ri, o si tun maa ta Naijiria, ẹnikẹni to ba le pe awọn amunisin lati dasi ọrọ orilẹede rẹ nilo akiyesi daadaa.''

Ajọ MURIC wa sọ ninu atẹjade naa wi pe awọn ko ni igbagbọ kankan ninu alaga INEC.

Ajọ naa rọ ijọba apapọ lati fi kristẹni mii rọpo rẹ.

MURIC ni ti ijọba apapọ ko ba yọ ọ nipo gan an, o yẹ ki Amupitan funra rẹ kọwe fipo silẹ latari awọn ẹsun nla ti wọn fi kan an.

''Orilẹede Naijiria ko le lọ siwaju ti awọn eeyan bii Amupitan ba si n dipo alaṣẹ mu.

O yẹ ki Amupitan naa mọ pe ijọba ko le yan an sipo alaga ajọ INEC ti aṣiri nnkan to ṣe sẹyin ba ti tu nipa bo ti kọwe si Amẹrika wi pe awọn kan n ṣe inunibini sawọn kristẹni ni Naijiria.

Ni ṣe lo yẹ ki Amupitan ti kọwe fipo silẹ lẹyin ti aṣiri ti tu sita, amọ, o kọ lati ṣe bẹẹ.

Ọpọ iru awọn eeyan bẹẹ lo ti kọwe fipo wọn silẹ nilẹ okeere, ṣugbọn kii saba ri bẹẹ ni Naijiria.

Amọ, a o ni dakẹ lori ọrọ yii, bo ya nnkan ti alaga INEC n ro ni pe a maa to gbagbe ọrọ naa.

Amupitan gbọdọ fipo alaga INEC silẹ tori o n dunkoko mọ iṣokan ẹsin ni Naijiria,'' MURIC lo sọ bẹẹ.

''Amupitan gbọdọ fipo silẹ lori Ibaṣepọ laarin rẹ ati ẹgbẹ oṣelu APC ṣaaju iyansipo rẹ''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ eeyan lo ti kepe alaga INEC lati kọwe fipo silẹ lori ẹsun wi pe o ti ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu APC ri lọdun 2023.

Awọn to n sọ pe ki Amupitan kọwe fipo silẹ ni o fi han loju opo X rẹ lọdun 2023 wi pe o ṣegbe lẹyin APC ati oludije sipo aarẹ ẹgbẹ naa, Bola Tinubu ṣaaju ati lẹyin ibo aarẹ ọdun naa.

Awọn lẹgbẹ lẹgbẹ, lajọ lajọ, ẹgbẹ oṣelu atawọn eeyan mii lo ti sọ pe Amupitan ni lati kọwe fipo silẹ tori o fi han pe o n ṣegbe lẹyin awọn oloṣelu kan ki o to de ipo alaga INEC.

Wọn ni o ti tapa si ileri to ṣe wi pe oun ko ni ṣegbe lẹyin ẹnikẹni gẹgẹ bi alaga ajọ INEC.

Ẹri tawọn eeyan naa tọka si ni igba ti wọn sọ pe Amupitan fi idahun ''Aṣeyọri Daju'' soju opo X rẹ lọjọ kejidinlogun oṣu Kẹta ọdun 2023 si ọrọ ti adari ọdọ ẹgbẹ oṣelu APC, Dayo Israel sọ pe APC ti jawe olubori lagbege tawọn Igbo pọ si.

Amọ, akọwe ajọ INEC, Adedayo Oketola, ti sọ pe oju opo X naa kii ṣe ti Ọjọgbọn Amupitan rara.

Oketola ni oriṣiiriṣii nnkan ni wọn ti fi oju opo X naa ṣe.

Awọn ọdọ ilu Amupitan ni Aiyetoro Gbede ṣewọde lati ṣatilẹyin fun alaga INEC

Awọn ọdọ ni Aiyetoro Gbede tii ṣe ilu alaga INEC ni ijọba ibilẹ Ijumu nipinlẹ Kogi ti ṣewọde lati ṣatilẹyin fun un latari bawọn kan ṣe n pe fun iyọnipọ rẹ.

Awọn ọdọ naa ti wọn mu iwe ilewọ dani tu yaya jade, wọn si n sọ pe awọn oloṣelu kan lo wa lẹyin bawọn kan ṣe n pe fun iyọnipo Amupitan.

Awọn olufẹhonuhan naa sọ pe awọn to n pe fun iyọnipo Ọjọgbọn Amupitan fẹ da ajọ INEC ru ni.

''Eto idibo ti yoo kẹsẹjari bẹrẹ pẹlu Amupitan'' wa lara awọn ọrọ ti wọn kọ sinu iwe ilewọ tawọn oluwọde naa mu dani.

Adari awọn ọdọ to sọrọ nibi iwọde naa sọ pe awọn ṣetan lati ṣatilẹyin fun Amupitan ati ajọ INEC ti o n dari.

''A gbọdọ daabo bo ajọ INEC, Ọjọgbọn Amupitan jẹ olufọkansin ati ẹni tii kii fi igba kan bọ ọkan ninu.

Awọn to n sọ ọrọ kobakun gbe nipa rẹ n ṣe ikọlu si ijọba awarawa ni ti wọn ko ba mọ,'' adari ọdọ lo sọ bẹẹ.

Awọn ọdọ naa sọ pe irọ to jinna si oootọ lọrọ tawọn kan n gbe kiri wi pe Amupitan n ṣe gbọyii-sọyi.

Ẹwẹ, ajọ INEC naa ti sọ pe ipe fun iyọnipo Amupitan ko ba ofin mu.

Akọwe iroyin INEC, Adedayo Oketola, sọ pe ipe fun iyọnipo alaga INEC tako abala 157 iwe ofin Naijiria ọdun 1999 to sọrọ nipa idari ajọ naa.