Àwọn agbẹ́bọn tún pa ọ̀dọ́ l'Ondo, aráàlú fi ẹ̀hónú hàn

Oloogbe T Dollar lapa osi, o ṣerun rẹ bii ti dada. O wọ aṣọ funfun o si fi ẹgba ọrun si ọrun rẹ. Lapa ọtun ni awọn araalu to n ṣewọde pẹlu awọn mọto ati ọkada ti ko rọna lọ.

Oríṣun àwòrán, Damilola Adedoyin/ BBC

Àkọlé àwòrán, Oloogbe T Dollar ti wọn pa ati awọn araalu to n ṣewọde
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Inu ibanujẹ ati iporuru ọkan ni awọn olugbe Imafon, Igushin ati Ilado nipinlẹ Ondo wa bayii latari awọn agbebọn to tun sekupa ọdọ kan tawọn eeyan mọ si T Dollar.

Iku T Dollar pẹlu awọn eeyan marun-un ti agbebọn ti kọkọ pa ni awọn agbegbe yii lo mu awọn eeyan ibẹ ko aya soke, ti wọn si pada ṣe iwọde lonii ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin ọdun 2026.

Lati le fopin si ikọlu ati ijinigbe tó n waye lemọlemọ naa, ati lati kesi ijọba fun ojutuu lo jẹ kawọn olugbe agbegbe yii gbegi di opopona to lọ si ofiisi Gomina, niluu Akure, lati fi ehonu han.

Lasiko ifehonuhan naa, awọn ọdọ, awọn obìnrin ati gbogbo awọn olugbe ilu naa gbegidi opopona naa, awọn onimoto ati olokada ko si ribi gba kọja.

Bawo ni wọn ṣe pa T Dollar?

Ọkan lara olugbe agbegbe naa to ba BBC News Yoruba sọrọ; Arabinrin Adebola Kolawole, salaye pe lasiko ti ọgbẹni T Dollar n wa ọkọ rẹ wọle ni awọn agbebọn yii kọlu u.

Arabinrin Kolawole sọ pe ilé awọn mejeeji wa lẹgbẹ ara wọn ni, ati pe niṣe lawọn agbebọn naa yinbọn mọ T. Dollar laya nigba to n wa mọto rẹ wọle.

O ni ọkunrin naa pe fun iranlọwọ sugbọn ko sẹni to le jade lati ran an lọwọ, nitori niṣe ni awọn agbebọn naa n yinbọn lakọlakọ.

Kolawole ni àwọn osisẹ Amotekun tó wà ní ayika naa ko yọju, sugbọn lẹyin ti awọn adari ilu pe wọn, wọn sọ fun wọn pe awọn ko ni ọta ninu ibọn awọn, idi niyẹn tawọn ko ṣe le yọju sawọn agbebọn naa.

"Ti aago meje alẹ ba ti lu, ẹru a maa ba gbogbo araalu ni, nitori asiko naa ni awọn agbebọn maa n bẹrẹ iṣẹ wọn.

"A rọ ijọba Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa lati wa ojutuu si ọrọ ipaniyan yii."

Bẹẹ ni Arabinrin Kolawole wi.

"Eeyan marun-un ni agbebọn ti pa lẹnu lọọlọ yii''

Awọn olufẹhonuhan naa ree ti wọn ja ewe dani lẹyin ti wọn di oju ọna to lọ si ọfiisi Gomina Lucky Aiyedatiwa.

Ọkan lara awọn adari ọdọ ni agbegbe naa, salaye pe eeyan marun-un ni awọn agbebọn ti sekupa lẹnu lọọlọ yii.

O ni lara awọn marun-un naa ni iya ati ọmọ tí wọn pa ni Ọjọbọ ọsẹ yii, ti wọn si tun pa awọn miran ni ana ode yii ti I ṣe ọjọ Ẹti.

O kesi ijọba ati awọn agbofinro lati se isẹ wọn, kí wọn si dide fun iranlọwọ ipinlẹ Ondo nipa pipese aabo to peye fun awọn olugbe ibẹ, paapaa awọn ibi ti ikọlu ti n waye lemọlemọ yii.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Ni Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni ariwo ọfọ sọ ni ilu Igunshin,ipinlẹ Ondo, nigba ti awọn agbebọn sẹkupa iya ati ọmọ ninu ọgba ti wọn ti n sin adiẹ fun iṣẹ oojọ wọn.

Iṣẹlẹ yii lo tun ti fa ibẹru bojo ni agbegbe naa, awọn eeyan bẹrẹ si I sa asala fun ẹmi wọn, wọn si n kọminu lori ipo ti aabo ipinlẹ Ondo wa.

Ọkan lara olugbe ilu naa salaye, pe awọn agbebọn marun-un ni wọn yabo ibi ti wọn ti n sin adiyẹ naa, wọn si fo iganna ọgba naa wọle lasiko ti awọn ti wọn sekupa n ṣiṣẹ lọwọ pẹlu awọn osisẹ to ku.

O salaye pe eeyan mẹta ni awọn agbebọn naa jigbe lasiko ikọlu naa, eyi to sọ ilu naa sinu ipayinkeke.

Ṣugbọn ọfọ nla sẹlẹ nigba ti wọn ri oku ẹni to ni ile adiyẹ naa naa ati ọmọ rẹ.

Iṣẹlẹ yii ati awọn iṣẹlẹ miran lo ti waye ni agbegbe yii, eyi lo mu ki awọn olugbe agbegbe naa faraya, to si wọn si ṣe iwọde ifẹhonu han bayii pẹlu.