Ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ sí í wó àwọn ilé tó ti rẹ̀ nítòsí èyí tó wo pa èèyàn mẹ́sàn-án l'Eko

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lati le dena itẹsiwaju ijamba ati iku ojiji, ijọba ibilẹ Eko ti n wo awon ile to wa nitosi ile alaja mẹta to wo lulẹ lagbegbe Alakija, Satellite Town, l'Ojobo, eyi to pa o kere tan, eeyan mẹsan-an, ti eeyan to to mẹtadinlọgbọn si farapa.
Ọjọ Ẹti ni igbesẹ awọn ile ti wọn n wo naa ti wọn ni ewu loko Longẹ ni wọn, bẹrẹ.
Ọga agba nileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Olufemi Oke-Osanyintolu, ṣalaye pe igbesẹ yii n waye lẹyin ayẹwo tawọn ajọ bii LASEMA, LASBCA to n ri si ile kikọ l'Eko atawọn ajọ mi-in ṣe sawọn ile ọhun.
Eyi to ni o fi han pe ẹgẹrẹmiti to kun fun ewu niwọn.
Ewu wa fawọn ẹṣọ alaabo to n ṣiṣẹ nitosi ile alaja mẹta to wo bi a ko ba wo awọn to ti di ẹgẹrẹmiti lẹgbẹẹ rẹ- Osanyintolu
Nigba to n ṣalaye idi ti awọn ile to sunmọ eyi to wo naa gbọdọ fi di wiwo lulẹ, Osanyintolu to lewaju ile wiwo naa sọ pe ewu nla lo jẹ fawọn oṣiṣẹ alaabo to n ṣeranwọ nibi ile alaja mẹta to kọkọ wo.
O ni o ṣee ṣe kawon ile naa ṣe ijamba nla fawọn oṣiṣẹ pajawiri to n ṣiṣẹ nibẹ, bẹẹ lo tun jẹ ewu fawọn eeyan to n gbe nibẹ atawọn to mule ti wọn.
Bakan naa lo ni araalu paapaa ko moribọ ninu ewu tawọn ile naa mu lọwọ, idi si niyẹn tawọn alaṣẹ fi tete gbe igbesẹ ti yoo dena ipayinkeke miran.
Osanyintolu ṣalaye pe nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ Ẹti ni wiwo awon ile to wa nitosi naa bẹrẹ, pẹlu abojuto awọn ẹka to yẹ.
"Igbesẹ idena ijamba leyi, ti a gbe lati le dena ile wiwo miran."
Oke-Osanyintolu lo sọ bẹẹ.
O rọ araalu lati jẹ ki eto yii ye wọn, ki wọn ma ṣe ri i bi iwa ika rara.
Ọga agba LASEMA naa sọ pe fun aabo ẹmi ati dukia ni ijọba ṣe n ṣe eyi.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Lojiji ni iroyin gbode nirọlẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, pe ile alaja mẹta kan nikorita Alakija, Satelite Town, niluu Eko, ti wo lulẹ.
Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ sọ pe eeyan mẹjọ lo ku ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn si doola ẹmi eeyan mẹrindinlọgbọn (26).
Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ Ẹti, onka eeyan to ku ti di mẹsan-an, bẹẹ ni eeyan 27 ni wọn ni wọn ti doola amọ ti wọn fi ara pa.
Ṣaaju igbese ile wiwo yii ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti pe fun ayẹwo awon ile to yẹ ni wiwo yii, to si ni o ṣee ṣe kawọn to n gbebẹ kawọ pọnyin rojọ lọjọ ijọba.
Sanwo-Olu sọ pe ijọba ti ni kawọn to n gbe nile alaja mẹta to wo naa kuro nibẹ ṣaaju akoko yii, aigbọrọ si ijọba lẹnu lo ni o fa a ti ile naa fi pada wo, to si mu awọn ẹmi kan lọ si ọrun aremabọ lojiji.
Àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ẹ̀mí yọ èèyàn 26 lábẹ́ ilé alájà mẹ́ta tó wó l'Eko, èèyàn mẹ́jọ kú

Oríṣun àwòrán, NEMA/X
Ajọ LSFRS to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ti doola eeyan mẹrindinlọgbọn nigba ti eeyan mẹjọ padanu ẹmi wọn nibi ile alaja mẹta to wo lagbegbe Alakija lopopona Ojo si Satellite Town l'Ọjọbọ niluu Eko.
Ọga agba LASEMA, Ọmọwe Olufemi Oke-Osanyintolu, naa sọ iye eeyan to ku nibi iṣẹlẹ naa wi pe mẹjọ ni wọn.
O ni awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi si n tẹsiwaju lati yọ awọn eeyan labẹ ile to wo naa.
Ọmọwe Oke-Osanyintolu ni awọn yoo tun maa fi to araalu leti bi nnkan ṣe n lọ nibi iṣẹlẹ naa.
Ajọ LSFRS sọ pe ilegbee ni ile ọhun eyi tawọn eeyan n gbe inu rẹ lasiko ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
Eeyan mẹwaa ni wọn kọkọ yọ labẹ ile to wo naa, wọn si ti ko wọn lọ sile iwosan fun itọju.
Ajọ naa ni iṣẹ si n lọ lati yọ awọn eeyan mii ti wọn le ha sabẹ ile to wo naa.
Àjọ LSFRS sọ pé ní nǹkan bíi ago méjìlá ọ̀sán kùdíẹ̀ kó lù ni àwọn gba ìpè wí pé ilé kan ti dàwó ní Satellite Town.
Ọ̀gá àgbà àjọ náà, Margaret Adeseye, sọ pé lọ́gán làwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà ti dé ibẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìdóòlà ẹmí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ti ile kan dawo niluu Port Harcourt nibi ti ẹnikan ti padanu ẹmi rẹ nipinlẹ Rivers.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post




























