Ta ni Omowunmi Dada, gbajúmọ̀ òṣèré tí sinimá òun àti Lateef Adedimeji, Itele D Icon, gba àmì ẹ̀yẹ GWR?

Omowunmi Dada wọ aṣọ dudu, o n wo ọọkan pẹlu aworan Adedimeji Lateef ati itẹlẹ D Icon lapa ẹyin rẹ.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Niṣe ni ẹsẹ ko gba ero ni gbagede Tafawa Balewa Square to wa ni ipinlẹ Eko ni opin ọsẹ to kọja yii latari ere fiimu ti wọn gbe jade nibẹ.

Fiimu ti wọn pe akọle re ni "Black Market" ti gbajumọ oṣere fiimu, Omowunmi Dada jẹ ọkan lara awọn to ṣagbatẹru fiimu naa wọn ṣafihan rẹ ni gbọngan naa.

Erongba ṣiṣe afihan fiimu naa ni gbọgan ọhun lati fitan balẹ pẹlu ajọ to n fun awọn eeyan ni aami ẹyẹ agbaye, Guinness World Record lori fiimu tawọn eeyan pọ si julọ lati wo o ninu gbọgan kan ṣoṣo.

Gẹge bi ileeṣẹ Guiness World Record ṣe sọ, ẹgbẹrun mọkanlelaaadọta eeyan lo peju pese si TBS lati wo fiimu naa.

Bi o tilẹ jẹ pe igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Obafemi Hamzat ti oun naa bawọn peju sibi eto naa kede pe eeyan mẹrinlelọgọta lo peju sibi iworan naa ṣugbọn Guinness World Record sọ pe awọn to duro lati ibẹrẹ titi di opin fiimu naa ni awon n ka.

Ṣaaju ni awọn eeyan ti wọn ṣagbekalẹ eto iworan naa sọ pe ẹgbẹrun lọna aadọta (50,000) eeyan ni awọn n reti ko kopa nibi eto naa lati kọja iye akọọlẹ to ti wa tẹlẹ to jẹ 43,624 ni gbọgan Filipino Felix Manalo ni Philippine Arena.

Ọpọ eeyan lo kopa nibi iwora fiimu naa to fi mọ igbakeji gomina Eko, Kọmiṣanna fun aṣa ati eto inaju ni ipinlẹ Eko, Toke Benson, awọn gbajumọ oṣere bii including Lateef Adedimeji, Kunle Remi, Stan Nze, Linda Ejiofor, Gabriel Afolayan ati Kunle Afolayan.

Awọn oṣere to kopa ninu ere naa ni Omowunmi Dada to jẹ ọkan lara awọn olootu ere naa, Linda Ejiofor-Suleiman, Lateef Adedimeji, Scarlet Gomez, Teniola Aladese, Susan Pwajok, Itele D Icon, Uzor Arukwe, atawọn mii.

Ta ni Omowunmi Dada?

Ọjọ keji, oṣu Kẹwaa, ọdun 1989 ni wọn bi Omowunmi Dada ni ipinlẹ Eko .

Ipinlẹ Eko naa lo ti lọ si ile ẹkọ alakọọbẹrẹ titi to fi pari ile ẹkọ giga ni Yunifasiti Eko nibi to ti kẹkọọn nipa iṣẹ ọna.

Oniruuru fiimu ni Omowunmi Dada ti kopa ninu rẹ to fi mọ Oya, Moremi Ajasoro, Ayinla, Omugwo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa lo tun ti gba ọkan-o-jọkan ami ẹyẹ t fi mọ ami ẹyẹ AMVCA nibi to ti gbami ẹyẹ igbakeji olori ere lọdun 2022.

Omowunmi Dada wa lara awọn olootu to ṣe agbatẹru fiimu, Black Market pẹlu ajọṣepọ Fatimah Binta Gimsay ati Abdul Tijani-Ahmed lati fi gba ami ẹyẹ Guinness World Record lori fiimu ti ero pọ si julọ nibẹ lati wo o ni oju kan ṣoṣo.