Makinde sọ̀rọ̀ lórí ibi táwọn agbébọn kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso pamọ́ sí

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti sọrọ lori ibi tawọn agbebọn ko awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ni Ahoro-Esinele ati Yawota l'Ogbomoso pamọ si.
Gomina ipinlẹ Oyo sọ ninu atẹjade kan to fi sita fawọn akọroyin pe ninu igbo ijọba Old Oyo National Park lawọn ajinigbe naa wa pẹlu awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso.
Makinde kẹdun pẹlu ẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe naa wi pe o ti n lọ bi oṣu kan bayii tawọn janduku agbebọn ji awọn eeyan wọn gbe lọ.
Gomina ipinlẹ Oyo sọ pe oun mọ pe ninu ipaya ọkan ati inira lawọn ẹbi awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa wa lati ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un to kọja ti wọn ti ji wọn gbe lọ.
Bakan naa ni Makinde tun sọ pe ileri ti ijọba n ṣe ni gbogbo igba lati doola awọn eeyan naa le ma tumọ si nnkankan loju wọn pẹlu bi ọjọ ṣe n gori ọjọ.
Amọ, Makinde fi dawọn loju wi pe awọn ẹṣọ eleto aabo ko dawọ iṣẹ duro lati ri pe awọn eeyan ti wọn ji gbe naa pada wale lalaafia.
''Gbogbo ipa wa ni a n sa lati ri wi pe a doola awọn to wa lakata awọn ajinigbe.
Iṣẹ iwadii ti fidii rẹ mulẹ wi pe ninu igbo ijọba Old Oyo National Park to gba bii ijọba ibilẹ mẹwaa nipinlẹ Oyo kọja lawọn ajinigbe naa si wa pẹlu awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe.
Bi igbo ọba naa ṣe tobi to lo jẹ ko nira fawọn ẹṣọ eleto aabo lati le tete doola awọn ti wọn ji gbe.
Ọrọ naa gba suuru ati ifarabalẹ ki a baa le ri awọn eeyan to wa lakata awọn ajinigbe yii doola,'' Makinde lo sọ bẹẹ.
Gomina wa rọ awọn araalu lati wa lojufo ki wọn si pe nọmba 615 ti wọn ba kofiri ẹnikan tabi nnkankan to mu ifura dani.
Bakan naa ni o tun rọ awọn eeyan wi pe ki wọn ye gbe iroyin ofege kiri lori iṣẹlẹ naa tori o le ṣakoba fun akitiyan awọn ẹṣọ eleto aabo lati doola awọn eeyan ti wọn ji gbe.
Awọn ẹṣọ aabo Iru Ekun nawọ gan awọn afurasi ajinigbe meji
Awọn ẹṣọ aabo Iru Ekun, Iru Ekun Security Network ti nawọ gan awọn afurasi ajinigbe meji, ti wọn si ri eeyan meji gba kalẹ lọwọ awọn ajinigbe naa ni agbegbe Ora-Igbomina, ipinlẹ Osun.
Ni ọjọru ni ẹṣọ aabo naa ni awọn ṣe iṣẹ naa lẹyin ti awọn gba iroyin pe awọn afurasi ajinigbe ji eeyan mẹta kang be ni ilu naa, ti wọn si ko wọn wọgbo lọ.
Olori ẹṣọ aabo Iru Ekun sọ pe awọn afurasi naa ti wọn jẹwọ pe ọmọ orilẹ ede Niger Republic ni wọn ti wa ṣiṣẹ ibi naa ni Naijiria.
O ni awọn ṣi n ẹnikẹta tawọn ajinigbe naa ji gbe, ti wọn si doola meji laaye lai ni ifarapa kankan.

Oríṣun àwòrán, Others
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, ẹni to n ja fun idasilẹ Yoruba Nation, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho, to tun jẹ oludasilẹ Iru Ekun sọ pe awọn ti fa awon afurasi naa le awọn ọlọpaa Oke-Ila lọwọ fun iwadii to peye ati gbigbe igbesẹ ofin to yẹ lori awọn afurasi naa.
Igboho ni ojuṣe awọn ni lati da aabo bo awọn araalu, ki awọn si dena iṣẹ ibi awọn ajinigbe lai fa wahala rara.
O fi kun pe Iru Ekun jẹ idasilẹ lati ṣiṣẹ ni awọn ilu to wa ni ẹsẹ kuku toju awọn ọlọpaa ko le to, ki awọn si ṣe iṣẹ ni ilana ti ofin gbe kalẹ.
O rọ awọn ori ade ọrun ilẹkẹ atawọn araalu ni ipinlẹ Osun ati agbegbe rẹ lati w ani oju lalakan fi n ṣọri, ki wọn si mu alekun ba iṣamulo awọn fijilante ni agbegbe koowa wọn.
Bakan naa lo ni wọn gbọdọ maa fi iroyin, tabi ti wọn ba kẹfin ohun to ṣe ajoji ni agbegbe wọn to awọn ẹṣọ aabo leti ni kiakia.
Iṣẹlẹ ijinigbe ni Ora-Igbomina yii tun ṣafihan bawọn ajinigbe ati agbebọn ṣe n fi awọn igbo ọba to wa lawọn ipinlẹ Osun, Oyo, Kwara ati Ondo ṣe ibugbe, ti wọn si n ṣe awọn araalu lọṣẹ.
Iru Ekun tun fi kun pe iṣẹ ṣi n lọ lati ṣawari ẹnikan to ku ni aaye ati alaafia.



























