Kí ni Cute Abiola ṣe, tí omíjé fi ń dà lójú rẹ̀ àmọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ̀rọ̀ si?

Oríṣun àwòrán, thecuteabiola/Instagram
Laipẹ yii ni ọdọmọde alawada nni, Abdulgafar Abiola tawọn eeyan mọ si Cute Abiola, kede pe iyawo oun bimọ keji, bẹẹ lo si tun ṣafihan ohun ti oju obinrin naa ri lasiko ibimọ ọhun.
Iṣẹ abẹ ni iyawo Cute Abiola torukọ rẹ n jẹ Khudrah Mosunmola fi mọ, ko si too di pe wọn gbe e wọ yara iṣẹ abẹ naa ni oun ati ọkọ rẹ ti bẹrẹ fidio to n ṣafihan bi igbesẹ oyun naa ṣe n lọ han.
Ibi kan tiẹ wa ti Cute Abiola funra ẹ ti n sunkun ninu fidio ọhun, to n sọ pe iyawo oun ti n rọbi o, k'Oloun ma jẹ ko gbabẹ ku, nitori oun ko le da ọmọ tọ.
Bi Cute Abiola ṣe n sunkun ni iyawo rẹ to wa ni yara igbẹbi naa n ke irora, gbogbo bi inu rẹ si ṣe ri lo han ninu fidio naa, titi kan ibi ti ọkọ rẹ ti n ke Kurani si I leti lati inu foonu.

Oríṣun àwòrán, Cute Abiola/ Facebook
Ki lo de ti Cute Abiola fi ṣe fidio to lagbara naa?
Gẹgẹ bi Cute Abiola tawọn eeyan tun mọ si Lawyer Kunle ṣe ṣalaye, iṣẹ abẹ ti iyawo rẹ n ṣe yii ni ẹlẹkẹẹta ti yoo ṣe laaarin ọdun mẹrin.
Idaamu, ibẹru ati ai le sọ ohun ti yoo tun ṣẹlẹ bi oyun keji ti Khudrah fẹ bi ṣe tun la iṣẹ abẹ lọ, lo mu Cute Abiola ṣe fidio, to si n fi omijẹ bẹbẹ pe kawọn ololufẹ oun ba oun ṣadua ki iya bi layọ, koun si gbọ ohun ọmọ tuntun layọ pẹlu.
Ninu fidio to le ni wakati kan ti Cute Abiola fi si ori Tube lo ti ni:
"Iyawo mi ti wa ninu yara iṣẹ abẹ… mo bẹ ọ Ọlọun, jọọ.
Mo fẹ kiyawo mi bi layọ. Mo fẹ ko jade layọ. Ko ma si iṣoro kankan."
Bi iyawo ṣe n jẹrora ibimọ lori bẹẹdi, adẹrinpoṣonu naa tẹsiwaju ninu fidio rẹ:
"Mo ti n gbọn. Ara mi o gba a mọ.Mo kan n sunkun ni… Allah."
Bẹẹ ni Cute Abiola wi tẹkun-tẹkun ninu aṣọ yara igbẹbi to wọ.
Amọ bi fidio naa ṣe mu eeyan lọkan to, ti awọn ẹlomi-in ko tiẹ le wo o paapaa, bẹẹ naa ni Cute Abiola n sọ pe ki wọn maa lọ ba oun wo o loju opo You Tube oun.
O ni ẹkunrẹrẹ rẹ wa loju opo naa lati ibẹrẹ de opin.
Ninu wiwo fidio naa ni owo yoo ti wọle fun un.

Oríṣun àwòrán, thecuteabiola/Instagram
Iyawo bimọ, o loun ro pe oun yoo ba oyun naa lọ ni
Ni itẹsiwaju fidio ọhun, Khudrah naa sọ iriri rẹ lasiko to n jẹ irora.
Ọmọkunrin lanti-lanti lo fi oyun ọhun bi.
" Mo tilẹ ti fẹ sọ pe ko o ba mi tọju ọmọ mi, mo ro pe ọmọ maa yè, pe ọta mi ko ni i yè ni tiẹ ni. Oriiṣiriṣii ero buruku lo n wa si mi lọkan.
"Mo kan wo pe ki n ma sọ nnkan ti ko daa ni, nitori ti mo ba sọ ọ, o ma ṣẹlẹ.
Lawyer Kunle naa pada kede pe awọn ti bimọ ọkunrin.
Awọn eeyan bu ẹnu atẹ lu fidio naa, wọn ni o ya awọn lẹnu pe Cute Abiola fi irora iyawo rẹ pawo

Oríṣun àwòrán, Cute Abiola/ Facebook
Bi fidio naa ṣe fẹrẹ le maa gba omije loju awon eeyan to ri I to, ki won ṣaa maa lọ wo o nilana owo pipa naa bi ọpọ eeyan ninu.
Ọpọ eeyan to sọrọ lori fidio naa ni wọn sọ pe ṣe owo ti Abiola fẹ pa lo tori ẹ ṣe fidio ni, abi irora iyawo rẹ ko tilẹ ka a lara rara.
Awijare awọn eeyan naa ni pe iru nnkan bayii kọ ni eeyan fi n ṣe fidio, bo ti wu ki iṣẹ abẹ ti iyawo rẹ ti ṣe ti pọ to.
Awọn mi-in sọ pe owo lo jẹ ẹ logun ju ohun to n ṣẹlẹ si iyawo rẹ lasiko ibimọ lọ.
Cute Abiola fesi
Bi awọn eeyan ṣe binu to lori ayelujara, ti awọn mi-in si ti ro pe Lawyer Kunle yoo tọrọ aforiji fun fidio rẹ naa, ko ṣe bẹẹ rara.
Esi to fi han pe oun ko tiẹ ran awọn to n binu naa niṣẹ ni Cute Abiola fi da wọn lohun.
O ni ki wọn pada soju opo Youtube oun, fidio naa ṣi wa nibẹ, ki wọn tun lọ wo o.
'Fila ma wọbẹ ni mo de' ni Cute Abiola fi ọrọ naa ṣe.
Wọn ti ṣe ikomọ ọmọ naa, wọn sọ ọ ni Abiola Alim Ayodeji.
Ta a ni Cute Abiola?
Gbajumọ ninu awọn ọdọmọde to maa n sọrọ awada atawọn iṣẹ sọrọsọrọ mi-in lori ayelujara ni Abdulgafar Abiola ti inagijẹ rẹ n jẹ Cute Abiola.
Lorii Instagram ati Facebook lo ti gbajumọ ju.
O ti figba kan fẹ ṣe ṣọja ori omi ri, ṣugbọn o kuro nibi ẹkọṣẹ ologun naa laaarin kan, ko si pada sibẹ mọ.
Ọdun 2021 lo fẹ Khudra Mosunmola, wọn si bimọ ọkunrin akọkọ ki wọn too bi ẹlẹẹkeji bayii.
Ọmọ ilu Ilorin nipinle Kwara ni.

























