Wo ìpínlẹ̀ méje tí yóò wà nínú òkùnkùn birimù fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà

Oríṣun àwòrán, X
Ajọ NISO to n ri si ọrọ ina ọba ti kede wi pe ipinlẹ meje ọtọọtọ ni ko ni n'ina mọnamọna fun ọsẹ mẹfa ni Naijiria latari atunṣe ileeṣẹ ipese ina Jos-Gombe 330kV to n lọ lọwọ.
Ajọ naa sọ pe ko ni si ina ọba lawọn ipinlẹ yii lati ago mẹsan an aarọ si ago mẹfa irọlẹ lati le ṣiṣẹ lori waya amunawa nileeṣẹ ipese ina ọhun.
NISO kede wi pe lati ọjọ kẹsan an oṣu Kẹrin yii ni atunṣe yii ti bẹrẹ, yoo si pari ni ọjọ kejilelogun oṣu Karun un ọdun 2026 yii.
''Ko ni si ina ọba fun ọsẹ mẹfa lati le jẹ ki iṣẹ atunṣe awọn waya ti a n ṣe nileeṣẹ ipese ina ọba kẹsẹjari"
Awọn ipinlẹ meje naa ni Plateau, Gombe, Bauchi, Borno, Adamawa, Taraba, ati Yobe.
Ajọ NISO sọ pe atunṣe naa wa lara eto ti ijọba n ṣe lati fun ileeṣẹ ipese ina ni Naijiria lagbara sii.
''Ko ni si ina ọba fun ọsẹ mẹfa lati le jẹ ki iṣẹ atunṣe awọn waya ti a n ṣe nileeṣẹ ipese ina ọba kẹsẹjari.
Ti a ba pari iṣẹ atunṣe ti a fẹ ṣe, ileeṣẹ apinaka yoo tubọ ni ina lati maa pin kaakiri sii.
Bakan naa atunṣe ti a n ṣe yoo jẹ ki a tete maa mọ ti ina ba ti bajẹ nibi kibi,'' ajọ NISO lo sọ bẹẹ.
''Fun anfaani araalu ni iṣẹ atunṣe ta fẹ ṣe, tori yoo jẹ ki ina ọba dara sii''
Bo tilẹ jẹ pe, ileeṣẹ mọnamọna ṣeleri lati wa ọna mii tawọn araalu yoo fi maa ri ina lo lasiko atunṣe ana, ajọ NISO ni ina perete nileeṣẹ mọnamọna le mu wa lasiko naa.
Ajọ NISO sọ pe iṣẹ atunṣe naa ko ni jẹ ki ileeṣẹ mọnamọna ni ina to pọ lati pin fun araalu lawọn ipinlẹ meje tọrọ kan naa.
Ajọ NISO ni oun n ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ apinaka ati ileeṣẹ TCN to n ri si ipese ina ni Naijiria lati ri pe iṣẹ atunṣe tawọn fẹ ṣe ko ni ṣakoba to pọ ju fun araalu.
Iru ipenija yii saba maa n jẹyọ nigba kugba ti atunṣe ba n lọ lọwọ lawọn ileeṣẹ to n pese ina ọba ni Naijiria.
Amọ, ajọ NISO ti sọ pe fun anfaani araalu ni iṣẹ atunṣe tawọn fẹ ṣe, tori yoo jẹ ki ina ọba dara sii.
Ajọ naa tun sọ pe iṣẹ atunṣe yii yoo tun jẹ ki awọn ẹrọ amunawa dabi ti igbalode sii tawọn ba ṣetan.
Nigba to n tọrọ aforijin lọwọ araalu, ajọ NISO bẹ awọn olugbe ipinlẹ meje naa lati fọwọ sọwọ pọ pẹlu ajọ naa tori awọn naa ni yoo pada jere nnkan tawọn fẹ ṣe.

























