Póòpù ń ṣàbẹ̀wò sílẹ̀ Africa pẹ̀lú ìwáásù àlááfíà àti ìṣọ̀kan

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
- Author, Nomsa Maseko (Algeria) and Paul Njie (Cameroon)
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ní ọjọ́ Ajé, Póòpù ìjọ Àgùdà, Pope Leo XIV yóò bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò sáwọn orílẹ̀ èdè Africa mẹ́rin - Algeria, Cameroon, Angola àti Equatorial Guinea.
Ìjọ́ Àgùdà sọ pé ìrìnàjò ọlọ́jọ́ mẹ́wàá náà jẹ́ ojunà láti pe àkíyèsí gbogbo àgbáyé sí ilẹ̀ Africa ni.
Ohun tó lé ní ìdá ogún ni àwọn ọmọ ìjọ Àgùdà tí wọ́n ń gbé ní ẹkùn Africa, tí wọ́n sì júwe wọn bíi èyí tó ní akitiyan, tó sì ń jí gìrì sí ojúṣe wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ìjọ náà, bí àwọn èèyàn ṣe ń darapọ̀ mọ́ ìjọ náà ń lékún síi ju ti ẹkùn kankan káàkiri àgbáyé.
Wọ́n ní àbẹ̀wò yìí jẹ́ èyí tó ṣe pàtàkì sí Pope Leo fúnra rẹ̀.
Orílẹ̀ èdè Algeria ni Póòpù máa kọ́kọ́ balẹ̀ sí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ìjọ Àgùdà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní orílẹ̀ èdè yìí, àmọ́ ó ṣe pàtàkì sí ìtàn àwọn onígbàgbọ́.
Algeria ni wọ́n bí onímọ̀ nípa ẹ̀sìn Kristi, Saint Augustine sí, ẹni tí ipa rẹ̀ wà lára ohun tó
ṣe àtiwáyé ìgbàgbọ́ Póòpù nínú "Augustinian Order".
Ìgbà àkọ́kọ́ tí póòpù yóò ṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè yìí rèé, tí ọ̀kan lára àwọn kókó tó fi ń ṣàbẹ̀wò síbẹ̀ ni ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí orílẹ̀ èdè àti bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣe ìrìnàjò lẹ́kùn Mediterranean.
Gẹ́gẹ́ bí àmì sí ìfarajìn rẹ̀ sí fífi ààyè gba ìjíròrò láàárín ẹ̀sìn méjéèjì, Póòpù Leo yóò ṣe àbẹ̀wò sí mọ́ṣáláṣí ńlá Algiers ìyẹn "Great Mosque of Algiers".
"Ohun ìwúrí ńlá ni yóò jẹ́, ó máa pọnkún ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn ẹ̀sìn méjéèjì, tí wọ́n ní ìtàn tó so wọn papọ̀," olùgbé Algeria kan, Marwa Melki sọ.
Basilica of Our Lady of Africa tó wà ní olú ìlú orílẹ̀ èdè Algeria ni póòpù ti máa bá àwọn ọmọ Àgùdà sọ̀rọ̀.
Ọ̀gá àgbà Basilica náà, Fadá Peter Claver Cough ni ohun tí òun ń retí níbi àbẹ̀wò póòpù ni láti wá gba àwọn níyànjú láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àfojúsùn àwọn láti mú àyípadà bá ayé ni dáadáa, kí àwọn gbé ayé nínú àlááfíà, tí gbogbo èèyàn yóò máa gbé ní ìrẹ́pọ̀.

Àbẹ̀wò yìí ló ń wáyé lásìkò táwọn èèyàn kan ń kọminú lórí bí Algeria ṣe ń ṣe àwọn ẹlẹ́sìn tí kò pọ̀.
Àwọn mùsùlùmí tó jẹ́ Sunni ló pọ̀jù ní Algeria. Nígbà kan rí, àwọn ilé ẹjọ́ ní Algeria ti sọ àwọn kristẹni àtàwọn mùsùlùmí Ahmadi sí ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn pé wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn tí wọn kò fọwọ́ sí [tàbí pé wọ́n lòdì sí Islam.
Nínú àtẹ̀jáde kan láìpẹ́ yìí, àjọ Human Rights Watch sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn tí kò pọ̀ ń kojú ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà, tí wọ́n sì ń fi òfin dè wọ́n, èyí tí kò jẹ́ kí wọ́n le ṣe ẹ̀sìn wọn bó ṣe yẹ, àti pé wọn ò lè ṣe ẹ̀sìn wọn ní gbangba.
Bákan náà ni wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn tó ń ṣe àtìpó àtàwọn arìnrìnàjò ń kojú lẹ́yìn tí wọ́n lé ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn èèyàn tó fi mọ́ àwọn ọmọdé àtàwọn olóyún kúrò ní orílẹ̀ èdè náà lọ́dún 2024 àti 2025.
Ọ̀nà láti pè fún ìpẹ̀tùsááwọ̀

Oríṣun àwòrán, Michel Mvodo/BBC
Lẹ́yìn náà ni Póòpù máa balẹ̀ sí Cameroon pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlááfíà àti ìṣọ̀kan.
Cameroon, tí àwọn èèyàn rẹ̀ tó tó ìdá ogójì jẹ́ ọmọ ìjọ Àgùdà, ló ti ń kojú ìpèníjà àwọn alákatakiti tí wọ́n ń pè fún ìpínyà ní ẹkùn àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn tó ń sọ èdè Faransé.
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN sọ p'r kò dín ní èèyàn 6,000 tó tib á ìkọlù náà lọ àti pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti di aláìnílé lórí mọ́.
Póòpù máa dé Bamenda, olú ìlú ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá Cameroon, níbi tí ìwà ipá náà ti ń wáyé.
Níbẹ̀ ni ó ti máa ṣe ìsìn láti pè fún àlááfíà àti ìdájọ́ òdodo ní pápákọ̀ òfurufú Bamenda, tó sì jẹ́ pé aṣojú gbogbo ẹ̀sìn ni wọ́n pè síbẹ̀.
Àwọn aráàlú sọ pé àwọn ní ìrètí pé ìsìn náà máa jẹ́ ìlànà fún ìpẹ̀tùsáàwọ̀ tó ti ń wáyé gún ìgbà pípẹ́.
Obìnrin kan, Ernestine Afanwi, ẹni tó sá kúrò ní ìlú rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jo ilé àti ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ sọ pé òun gbàgbọ́ pé gbogbo ìṣòro agbègbè náà ló máa ní ìyanjú pẹ̀lú àbẹ̀wò póòpù.
Láti bíi ọdún mẹ́ta báyìí ni Afanwi àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fà ti ń gbé ní ilé àwọn aṣàtìpó tó wà ní Yaoundé, olú ìlú Cameroon.
"Ti mob á ní àǹfààní láti fo ojú rinjú pẹ̀lú Póòpù, mà á sọ gbogbo ìṣòro mi fun, mà á sì sọ fun kó ya ilẹ̀ yìí sí mímọ́," ó sọ.

Oríṣun àwòrán, Michel Mvodo/BBC
Ìpèníjà tó ń wáyé ní ẹkùn àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Cameroon jẹ́ ohun tí àgbáyé kò kọbi ara sí.
Àmọ́ Póòpù tó gbésẹ̀, Pope Francis máa ń kọminú lórí rẹ̀, tó sì máa ń rọ ìjọ láti gbàdúrà kí ìjíròrò àti ìpẹ̀tùsááwọ̀ le wáyé lórí rẹ̀.
Àwọn àlùfáà ìjọ Àgùdà wà lára àwọn tí wọ́n máa ń ṣe ìkọlù sí níbẹ̀, tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀ wọ́n gbé.
Ní oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 tí wọ́n jí àwọn àlùfáà ìjọ Àgùdà mẹ́fà àti àlùfáà ìjọ onítẹ̀bọmi kan gbé, Póòpù Leo pè fún ìtúsílẹ̀ wọn kíákíá.
Ṣáájú àbẹ̀wò Póòpù, wọ́n ti ń rọ ìjọba àtàwọn alájàngbilà náà láti ṣe sùúrù kí àfojúsùn Póòpù le wá sí ìmúṣẹ.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Willibroad Dze-Ngwa, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìtàn àti ìpẹ̀tùsááwọ̀ rọ ààrẹ Cameroon, Paul Biya láti tú àwọn tó wà lẹ́wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ òṣèlú sílẹ̀ pàápàá àwọn tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìkọlù tó ń lọ lọ́wọ́.

Oríṣun àwòrán, Michel Mvodo/BBC
"Àmì ìrètí ni póòpù jẹ́, àmì àlááfíà àti ìpẹ̀tùsááwọ̀ káàkiri àgbáyé.
"Nítorí náà mor ò ó pé tí àbẹ̀wò rẹ̀ bá wáyé lásìkò kan náà pẹ̀lú tútú àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà sílẹ̀, ó máa ní ìtumọ̀ tó pọ̀ sí póòpù, ààrẹ wa àtàwọn tí wọ́n wà ní àhámọ́ náà," ó sọ.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí póòpù máa ṣàbẹ̀wò sí Cameroon.
Pope John Paul II ṣàbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè náà ẹ̀ẹmèjì – ní ọdún 1985 àti 1995 – tí Pope Benedict XVI náà sì ṣàbẹ̀wò síbẹ̀ lọ́dún 2009.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ààrin gbùngbùn Africa máa ń rí àbẹ̀wò póòpù sí ọ̀nà láti ṣe ìgbéléwọ̀n ṣọ́ọ̀ṣì àti ipa rẹ̀ ní àwùjọ.
Yàtọ̀ sí ṣíṣe àbẹ̀w]o sáwọn ibi tí wàhálà ti ń wáyé ní Cameroon, Pope Leo máa ṣe ìsìn ní Yaoundé àti Douala.
Láti Cameroon ni pope ti máa ṣe ìrìnàjò lọ Angola, tó sì máa parí ìrìnàjò rẹ̀ sí Equatorial Guinea. Angola àti Equatorial Guinea ni wọ́n ní ọmọ ìjọ Àgùdà tó pọ̀.























