Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ikọ̀ aláàbò ilẹ̀ Ibadan tuntun, Ibadan Community Guard

Oríṣun àwòrán, Oba Rashidi Adewolu Ladoja
Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja ti ṣe ifilọlẹ ikọ alaabo ilẹ Ibadan to pe orukọ rẹ ni Ibadan Community Guard.
Nibi ifilọlẹ naa ni wọn tun ti ṣe ifilọlẹ eto ọrọ aje ilẹ Ibadan ti wọn pe ni Ibadan Economic Investment and Business Development Desk ati Ibadan Food Security Initiative to fi mọ Gaari Ibadan.
Aafin Olubadan to wa ni Oke Aremo niluu Ibadan ni wọn ti ṣe eto naa.
Wọn ni awọn ẹṣọ alaabo agbegbe naa ni wọn yoo pin kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ mọkanla to wa nipinlẹ Oyo fun aabo to peye.
Igbesẹ yii lo n waye latari bi eto aabo ṣe mẹyẹ nipinlẹ Oyo, o si jẹ ọna lati daabo bo awọn eeyan Ibadan ati agbegbe rẹ.
Iwọyin ni awọn ohun to yẹ ki o nipa ikọ alaabo Ibadan Community Guard
Nigba ti BBC Yoruba kan si aafin Olubadan, agbẹnusọ Olubadan, Adeola Oloko sọ pe nnkan bii oṣu mẹwaa sẹyin ni Kabiesi gbe igbimọ kan dide lori ọrọ naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, lẹyin iwadii lori nnkan to faa ti awọn ileeṣẹ nlanla fi n kogba wọle, iwadii naa fi han pe eto abo to mẹhẹ lo faa ti ọpọ ileeṣẹ fi n kuro ni ipinlẹ Oyo.
O fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa lo ṣe idanilẹkọọ fun awọn ẹṣọ alaabo tuntun naa, abọ akoso awọn ọlọpaa ati ikọ Amotekun ni wọn yoo si wa.
Lara ojuṣẹ awọn agbofinro ilẹ Ibadan ni ṣiṣẹ ọfintoto awọn ibi ti wahala ti maa n waye lati maa sin ilu ni gbẹrẹ ipako lori ohunkohun to ba n lọ lagbagbe ti wọn b awa.
Oloko sọ pe "Ohun ti wọn n ṣe ni pe, wọ n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọpaa, tabi Amotekun, wọn o da iṣẹ ara wọn ṣe, ko si si ohun to le fa gbọnmisi omi-o-to laarin awọn atawọn agbofinro ti ijọba yan.
Agbenusọ Olubada ṣalaye pe ibaṣepọ to dan mọran ni yoo wa laarin ikọ naa atawọn agbofinro miran.
O fidi rẹ mulẹ pe ajọ to n gbogun ti lilo egboogi oloro, NDLEA, ti ṣabẹwo si Olubadan wọn si ti ṣeleri fun un pe awọn yoo ṣiṣẹ papọ awọn ẹṣọ alaabo ọhun.
Nipa ohun ija oloro ti wọn yoo maa lo, Oloko sọ pe kii ṣe ibọn tabi ada bikoṣe nnkan ibilẹ ilẹ Yoruba.
O ni "Awọn nnkan iṣẹnbaye ti awọn baba wa naa ti lo ni wọn yoo lo, wọn ki n ṣe eeyan lasan, wọn ti bura fun ilu Ibadan pe wọn yoo ṣe alami fun ọlọpaa ti wọn ba gbọ pe wọn ji eeyan gbe.
"Wọn o gbe kumọ, wọn o gbe kondo, wọn o gbe ibọn paapaa, ṣugbọn wọn ti gba ọpọlọpọ idanilẹkọ lọwọ awọn ọlọpaa ati Amotekun.
Bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn ẹṣọ alaabo naa ni wọn jẹ agbalagba, o ni wọn ni okun daadaa, wọn si ni iriri nipa eto aabo daadaa.


























