Àkọlé àwòrán, Fayose gbe ètò olóògùn ebi "Stomach infrastructure" kalẹ ni ibẹrẹ saa keji iṣejọba rẹ
Published
Àkọlé fídíò, È gbọ àlàyé lẹnu àwọn ti ójúẹlẹgba leko irú iṣẹ ti oògùn olóró má n ṣé lara.
Eto oloogun ebi yoo tẹsiwaju lẹyin iṣejọba Gomina Ayodele Fayose.Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọjọgbọn Kọlapọ Oluṣọla Eleka, lo ṣeleri yii, lasiko ti o n ba awọn oṣiṣẹ kan sọrọ nilu Ado Ekiti.
Eto "oloogun ebi" eleyi ti adape rẹ lede Gẹẹsi jẹ "stomach infrastructure" ni gomina Fayose gbe kalẹ ni ibẹrẹ saa keji iṣejọba rẹ, eyi to si da ọpọlọpọ họwu-họwu silẹ nigba naa.
Àkọlé àwòrán, Eleka ni ko si ohun to buru ninu ka bu irẹsi igba Naira, ati ẹwa diẹ fun araalu lati fi gbenuro
Iṣọla Eleka to tun jẹ igbakeji ijọba to n kogba wọle lọwọ nipinlẹ Ekiti sọ pe atunṣe ranpẹ yoo ba eto naa eleyi ti yoo gbee kuro ni anfani ipinlẹ nikan lọ si awọn ẹka ijọba ibilẹ gbogbo to wa l'Ekiti.