Ta ni Kingsley Chinda tó kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ sí APC láti du ipò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Rivers?

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kingsley Chinda,
Adari ẹgbẹ oṣelu to kere julọ nile igbimọ aṣojuṣofin, Kingsley Chinda, ti fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ninu lẹta kan ti Kingsley Chinda kọ sile ọhun lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 yii amọ ti wọn ka ninu ile ọhun lana ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 lo ti fidi ọrọ naa lede.
Lẹyin to kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lo kọwe fi ipo silẹ gẹgẹ bii adari awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu to kere julọ ninu ile ọhun.
Chinda, to jẹ korikosun minisita fun FCT, Nyesom Wike ni wọn ti fun ni tikẹẹti lati dije du ipo gomina ipinlẹ Rivers lọdun 2027.
Bo tilẹ jẹ pe oun nikan lo n du ipo naa, ọgọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun lo tu jade lati wa dibo wọn fun.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa ọkunrin naa ree
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 1966 ni wọn bi Chinda si idile Oloye Thompson Worgu Chinda ati Caroline Ihuchi Chinda.
Chinda lọ sile ẹkọ St. Marks State School Elelenwo ko to tẹsiwaju ẹkọ rẹ nile ẹkọ Municipal Council School I, Orogbum.
Nigba to kuro nibẹ, o lọ si Stella Maris College, Port Harcourt lọdun 1979 ko to tun lọ si Rivers State School of Basic Studies laarin ọdun 1984 si ọdun 1986.
Lati ibẹ lo ti lọ si Rivers State University of Science & Technology, Nkpolu, Port Harcourt lati kẹkọọ nipa imọ ofin to si kawe jade pẹlu maaki '3rd class.'
Fasiti lo ti bẹrẹ oṣelu lẹyin to darapọ mọ ẹgbẹ akẹkọọ National Association of Nigerian Students (NANS).
Lọdun 2008, gomina ipinlẹ Rivers, Chibuike Rotimi Amaechi yan an gẹgẹ bii kọmiṣọna fun ọrọ ayika, lati asiko naa lo ti n goke agba ninu oṣelu ipinlẹ ọhun.
Awọn mii to fi ẹgbẹ oṣelu kan silẹ lọ omiran nile aṣojuṣofin
Anthony Adebayo Adepoju, to n ṣoju Ibarapa nipinlẹ Oyo kuro ni PDP lọ si APM, Adedeji Stanley Olajide to n ṣoju Ibadan North-West/Ibadan South kuro ni PDP lọ si APM nigba ti Makanjuola Sunday Ojo to n ṣoju Ogo-Oluwa/Surulere kuro ni PDP lọ si ẹgbẹ APM.
Bakan naa, Najimdeen Oyeshina Oyedeji, to n ṣoju Iseyin/Itesiwaju/Kajola/Iwajowa; Folajimi Oyekunle, to n ṣoju Ibadan North; Abass Adekunle Adigun, to n ṣoju Ibadan North-East/Ibadan South-East ti gbogbo wọn wa lati ipinlẹ Oyo ni wọn ti kuro ni PDP lọ si APM.


























