Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún mẹ́rin nínú afurasí márùn ún fún ìkọlù ìjọ Kátólíkì nílùú Owo, tí wọ́n ti pa èèyàn 41 lọ́dún 2022

Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Emeka Nwite sọ pe merin ninu awon afurasi yii, wa ninu ẹgbẹ àgbèsunmọmi ti a mọ si Iswab, tí wọn si lọwọ ninu iwa ipaniyan to waye ni ilu ọwọ sugbon eni karun ko lọwọ nibe.
Adajo ni gbogbo ẹ̀sùn mẹsan an tí wọn fi kan àwọn merin yìí ni wọn jẹbí rẹ ,tí adajọ sì dá ẹni Kàrún silẹ.
Ile ẹjọ ti dá ẹjọ ikú fn àwọn merin afurasi wonyi pé ki wọn yẹgi fún wọn títí ti ẹ̀mí yóò fi bọ ninu wọn.
Ile ẹjọ sì ti dá ẹni karùn-ún silẹ pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ti wọn fi kan an.
Oni ni ireti wa pe ile ẹjọ giga ijọba apapọ to fi ikalẹ si ilu Abuja tii ṣe olu ilu orilẹede Naijiria yoo gbe idajọ kalẹ lori awọn afurasi ti wọn fi ẹsun kan pe wọn ṣe ikọlu si ile ijọsin ijọ aguda St. Francis Catholic Church ni ilu Ọwọ ni ipinlẹ Ondo.
Ikọlu naa to waye ni ọjọ karun un oṣu kẹfa ọdun 2022 ninu eyi ti olujọsin mọkanlelogoji ti jade laye ti ogoje miran si farapa.
Ijọba apapọ n fi ẹsun mẹsan an to da lori igbesunmọmi kan awọn marun un naa niwaju Onidajọ Emeka Nwite ti ile ẹjọ giga apapọ kan ni ilu Abuja.
Ijọba apapọ tun sọ niwaju ile ẹjọ ọhun ṣaaju pe awọn afurasi naa, Idris Omeiza, Al-Qasim Idris, Jamiu Abdul Malik, Abdulhaleem Idris ati Momoh Abubakar, wa lara ikọ agbesunmọmi labẹ ẹgbẹ Al-Shabab ni ipinlẹ Kogi.
Onidajọ Nwite ti ile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja lo n gbọ ẹjọ naa.























