Wo iye ìgbà tí Dangote ti fi kún owó epo ní Naijiria lọ́dún 2026

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Adari ileeṣẹ ifọpo Dangote, David Bird, ti sọ pe kii ṣe pe awọn ṣadede maa n fi kun owo epo bẹntiro bo ṣe wu awọn ni.
Ninu atẹjade kan ni Bird ti sọ pe ohun to n ṣẹlẹ ninu ọja epo rọbi lagbaye lo maa n sọ iye ti owo epo yoo jẹ lorilẹede kọọkan, ninu eyii ti Naijiria wa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn kii ṣadede joko lati sọ iye ti owo epo yoo jẹ, iye rẹ da lori iye to jẹ lọja epo rọbi agbaye.
Eyii n tumọ si pe bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ naa n ra epo labẹle, o tun maa n ra epo nilẹ okeere lati fọ ni Naijria.
Niwọn igba to ti n ra epo nilẹ okeere, o maa san awọn owo bii owo adojutofo lọja agbaye, to fi mọ awọn owo mii.
Iye ti wọn n ṣe owo dọla ilẹ okeere si naira, owo ti wọn fi n ko epo lati ibikan si omiran atawọn owo pẹpẹpẹ mii lo maa n sọ iye ti wọn yoo maa ta jala epo kan, gẹgẹ bi awọn onimọ nipa epo rọbi agbaye ṣe sọ..
Iye igba ti Dangote ti fikun owo epo bẹntiro latẹyinwa
Nigba ti Dangote kọkọ bẹrẹ si n ta epo fun awọn ọmọ Naijiria, nnkan bii ₦898 lo n ta lita epo kan.
Lẹyin naa lo kede pe oun yoo maa ta lita kan laarin ₦960 si ₦990 fun awọn ti wọn ba fẹ ra epo naa lọpọ yanturu.
Nigba ti yoo di ọdun 2025, owo epo n lọ si oke ati isalẹ nitori awọn idi kan, eyii ti iye ti wọn n ta owo dọla lagbaye wa lara rẹ.
Ni ibẹrẹ ọdun 2026, ₦774 si ₦874 ni Dangote ta epo rẹ amọ nigba ti ogun Amẹrika ati Israel bẹrẹ, owo gbera soke lagbaye, eyii to ṣakoba fun iye ti wọn n ta epo naa ni Naijiria.
Lati igba ti ogun Iran ọhun ti bẹrẹ ni owo epo ti n le si lagbaye ti wọn si n ta agba epo kan laarin $80 si $90.
Dangote dín owó epo bẹntiró kù sí ₦1,075

Oríṣun àwòrán, other
Ileeṣẹ ifọpo Dangote ti din owo epo bẹntiro rẹ ku si ₦1,075 fun jala epo kan lati ₦1,175 to n ta a tẹlẹ pẹlu adinku ₦100.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa Anthony Chiejina sọ fun awọn akọroyin pe epo ti wọn ba n pin lati ori omi ni wọn yoo ta ni ₦1,050.
Ileeṣẹ naa sọ siwaju si pe ₦1,430 lawọn yoo bẹrẹ si n ta epo disu bayii, eyii to jẹ adinku ₦190 si ₦1,620 ti wọn n ta a tẹlẹ.
Wọn ni "pẹlu agbeyẹwo iye owo ti a n ta epo ti a sẹ, a ti din PMS ku lati ₦1,175 si ₦1,075 (adinkun ₦100) fun lita kan.
"A tun ti din iye owo epo disu ku lati ₦1,620 si ₦1,430 (adinku ₦190) fun lita kan."
Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbeṣe naa lo waye latari bi owo epo ṣe n lọ soke-sodo lagbaye.
Dangote sọ pe o ṣe pataki fun awọn gẹgẹ bii ileeṣẹ ti ko ṣe ojukokoro lati din iye owo epo naa ku gẹgẹ bii adinku ṣe n de ba lagbaye.
O sọ siwaju si pe nnkan bii $3 si $6 ni owo epo awọn fi le, bẹẹ ni ijọba ko si san owo iranwọ kankan fun awọn lori owo ti wọn fi n ra epo tabi owo ilẹ okeere lagbaye.
Igba akọkọ ree ti Dangote yoo din owo epo bentiro ku ni Naijiria lẹyin to ṣafinkun iye owo epo naa nigba mẹta ọtọtọ laarin ọsẹ diẹ sẹyin.
Kilode ti bẹntiro gbowo lori ni Naijiria?
Lọjọ Aje ni ileeṣẹ naa gbe owo epo si ₦1,175 fun lita kan lati ₦995 to wa tẹlẹ lọjọ keje oṣu Kẹta, ati ₦874 fun lita kan lọjọ keji, oṣu Kẹta.
Lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹta, adari ileeṣẹ naa, David Bird, sọ pe ohun to n ṣẹlẹ lagbaye nipa owo epo naa kan ileeṣẹ ifọpo Dangote gbọngbọn ni Naijiria.
Owo agba epo to ja walẹ si $90 lagbaye lo mu ki owo epo Dangote naa tun ja walẹ bayii.
Eyii si ni igba akọkọ ti owo epo yoo ja walẹ lagbaye lẹyin ti ogun Amẹrika ati Israel si Iran bẹrẹ.
Ogun to n waye ni Iran ọhun lo fa ọwọngogo owo epo lagbaye, ọwọngogo yii lo si jẹ ki owo epo lọ soke ni Naijiria.


























