Ìrọ́ ni pé PDP dara pọ̀ mọ́ APM l‘Oyo, ẹgbẹ́ wa tóbi ju ká dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan lọ, àwa lá borí ìbò ààrẹ - Gbolarumi

Àkọlé fídíò, Ìrọ́ ni pé PDP dara pọ̀ mọ́ APM l‘Oyo, ẹgbẹ́ wa tóbi ju ká dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan lọ, àwa lá borí ìbò ààrẹ - Gbolarumi
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Eto idibo abẹle fun ẹgbẹ oṣelu PDP waye ni ile ẹgbẹ awọn oniroyin ni ilẹ Ibadan.

Nibẹ ni wọn ti kede Amofin Hazeem Gbolarumi gẹgẹ bi ẹni ti o jawe olubori ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP sí ipo gomina ni ipinle Ọyọ.

Bẹẹ ba gbagbe, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Seyi Makinde ti ko awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APM.

Ti Makinde tikalararẹ si kede ara rẹ gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ati APM, ti wọn ti dara pọ.

Bakan naa ni Makinde ti kọkọ kede Abimbola Adekanbi gẹgẹ bi oludije sipo Gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ati APM.

Sugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti igun miran ninu ẹgbẹ oṣelu PDP kede elomiran gẹgẹ bi Oludije sipo Gomina nipinlẹ Ọyọ.

Idi ree ti BBC News Yoruba fi kan si Azeem Gbolarumi, ẹni ti yoo maa dije fun ipo gomina lorukọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ Oyo.

Amofin azeem Gbolarumi wọ asọ toke tilẹ funfun, o de fila asọ oke sanyan, o na ika meji ọwọ alaafia rẹ soke, o si rẹrin musẹ

"PDP tobi ju ko darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu kankan lọ, sugbọn anfaani wa fun awọn ẹgbẹ to ku, lati wa darapọ mọ ẹgbẹ wa"

Nigbati oun ba akoroyin ile-iṣẹ BBC yoruba sọrọ, Amofin Hazeem Gbolarumi fi idunu rẹ ran lori bi awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu PDP se kede rẹ gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Oyo.

O wa fi dawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ loju pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni yoo jawe olubori ninu eto idibo to n bọ lọna ni ọdun to n bọ.

Gbolarumi wa kede pe ẹgbẹ oṣelu PDP ko dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu kankan o.

O ni ẹgbẹ oṣelu PDP tobi ju ki o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu kankan lọ, sugbọn anfaani wa fun awọn ẹgbẹ oṣelu to ku, lati wa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Oludije sipo gomina naa fi kun pe ẹgbẹ oṣelu PDP maa ni oludije sipo aarẹ ni ọdun 2027, ti oun si nigbagbọ pe ẹgbẹ oṣelu naa ni yoo gba ijọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba lọwọlọwọ.

O wa rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati fi ọwọ sowọpọ lati jẹ ki ẹgbẹ oṣelu PDP gbooro sii, to si rọ gbogbo awọn ti inu bi lati fi ọwọ wọnu ki gbogbo ohun ti wọn fẹ, le tẹ wọn lọwọ.

Amofin Gbolarumi tẹnu mọ pe ko si ija kankan laarin oun ati onimọ-ẹrọ Seyi Makinde rara.

Amofin azeem Gbolarumi wọ asọ toke tilẹ funfun, o de fila asọ oke alawọ buluu, o joko sori aga, o lo awo oju, o si so ọwọ rẹ mejeeji papọ

Hazeem Gbolarumi ati Beulah Adeoye nikan to fifẹ han lati du ipo gomina labẹ ẹgbẹ PDP nipinlẹ Oyo

Alaga feto idibo abẹle fẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Oyo, ọgbẹni Tolulope Awoniyi lo kede esi ibo naa lalẹ ọjọ aiku leyin ti wọn ko gbogbo esi ibo ti wọn di kakiri awọn wọọdu to wa ni ipinle Ọyọ wọle.

Awoniyi sọ pe awon oludije meji pere ni wọn fi erongba wọn han lati dije fun ipo gomina, Awọn mejeeji naa ni amofin Hazeem Gbolarumi ati amofin Beulah Adeoye.

Awọn ajọ eleto idibo (INEC) wa nibi eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP naac, labẹ oludari wọn, onimọ-ẹrọ Olugbenga Keshinro.

Bakan naa, awọn ẹṣọ alaabo naa ko gbẹyin ni bi eto naa.

Gbogbo ibo to gbe amofin Gbolarumi wọle jẹ 3,615, ti amofin Beulah Adeoye sì ni 22 pere.

Idi ree ti wọn se kede Amofin Hazeem Gbolarumi gẹgẹ bi oludije to jawe olubori ninu eto idibo abẹle sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinle Ọyọ.