Amẹ́ríkà gbé ìkìlọ̀ tuntun jáde lórí ọ̀rọ̀ àbò ní Nàìjíríà, Ó ní ìlú Abuja àtàwọn ìpínlẹ̀ 23 kan ti di ibi àìgbọdọ̀ wọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀, ìdí rèé

Awọn ọmogun Naijiria meji wọ aṣọ ologun, alupupu kan wa niwaju wọn

Oríṣun àwòrán, US Government/Nigerian Army/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Orilẹede Amẹrika ti paṣẹ wi pe kawọn oṣiṣẹ olu ileeṣẹ orilẹede naa to wa niluu Abuja fi ọfiisi silẹ tori eto aabo to ti mẹhẹ sii ni Naijiria.

Ni irọlẹ Ọjọru ọjọ kẹjọ oṣu Kẹrin ọdun yii ni ileeṣẹ ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ ilẹ okeere fi ikilọ naa sita.

Ijọba Amẹrika ṣalaye pe ikilọ yii ṣe pataki tori bii iṣẹlẹ igbesunmọmi, ijinigbe ati ipaniyan ṣe n pọ si kaakiri Naijiria.

Olu ileeṣẹ Amẹrika ko tii sọ pato igba tawọn oṣiṣẹ Amẹrika ọhun yoo pada si orilẹede wọn.

Bakan naa ni olu ileeṣẹ naa ko tii ṣalaye bo ya ọrọ naa kawọn ọmọ Naijiria to n ṣiṣẹ ni olu ileeṣẹ Amẹrika naa.

Amẹrika fi Naijiria si ipele ''Level 3'' eyi to tumọ si orilẹede tawọn ọmọ Amẹrika gbọdọ ronu si daadaa ki wọn to rinrin ajo lọ sibẹ.

Ipinlẹ 23 ti Amẹrika ni kawọn ọmọ orilẹede o gbọdọ rinrin ajo lọ ni Naijiria

Ijọba Amẹrika ti kede wi pe ipinlẹ mẹtalelologun lo wa ni ipele ''Level 4'' eyi to tumọ si pe awọn ọmọ Amẹrika ko gbọdọ rinrin ajo lọ sibẹ rara nitori bi eto aabo ti mẹhẹ nibẹ.

Awọn ipinlẹ lati ẹkun iwọ oorun ariwa ati aarin gbungbun Naijiria bii Plateau, Jigawa, Kwara, Niger ati Taraba wa lara awọn ipinlẹ ti Amẹrika ti sọ pe eto aabo ti buru julọ.

Awọn ipinlẹ yii ti darapọ mọ ipinlẹ Borno ati Yobe ni isọri awọn ipinlẹ ti eto aabo ti buru julọ tawọn alakatakiti ẹsin agbesunmọmi ti n ṣọṣẹ.

Wọnyi ni ẹkunrẹrẹ awọn ipinlẹ ti Amẹrika ni kawọn ọmọ orilẹede ma rinrin ajo lọ ni Naijiria: Abia, Adamawa, Anambra, Bauchi, Bayelsa, Borno, Delta, Enugu, Gombe, Imo, Jigawa, Kaduna, Kano, Katsina, Kogi, Kwara, Niger, Plateau, Rivers (yatọ fun Port Harcourt), Sokoto, Taraba, Yobe, ati ipinlẹ Zamfara.

Ikilọ yii ko ṣẹyin isẹlẹ ipaniyan to waye nipinlẹ Plateau ati Benue lẹnu ọjọ mẹta yii nibi ti ọpọ ẹmi ti ṣofo.

Bakan naa ni ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ati ISWAP si n ṣe ikọlu si awọn eeyan, awọn ọmogun atawọn oṣiṣẹ to n ṣeranwọ fawọn eeyan lẹkun ila oorun ariwa Naijiria papaa julọ nipinlẹ Borno.

''Awọn agbesunmọmi le ṣe ikọlu ninu ọja, nile itura, nile ijọsin, nile ẹkọ ati ni ibudokọ nigba kugba ni Naijiria''

Ijọba Amẹrika sọ pe awọn agbesunmọmi le ṣe ikọlu ninu ọja, ile itura, nile ijọsin, nile ẹkọ ati ni ibudokọ nigba kugba ni Naijiria.

Ọpọ lo tun n kọminu wi pe o sẹe ṣe ki ikilọ yii kan awọn eeyan to fẹ rinrin ajo wa si Naijiria naa lati orilẹede Amẹrika.

Ikilọ lori eto aabo yii jade bo tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ologun Amẹrika n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọmogun Naijiria lati le koju awọn agbesunmọmi to n ṣọṣẹ kaakiri Naijiria papaa julọ lẹkun ariwa.

Ijọba orilẹede Naijiria ko tii sọrọ lori ikilọ ti Amẹrika fi sita naa.

Awọn oṣiṣẹ ijọba lẹka eto aabo ti sẹyin wi pe lọpọ igba ni iru ikilọ Amẹrika yii kii sọ nipa aṣeyọri ijọba lori eto aabo lawọn ẹkun kan ni Naijria, amọ, ibanilorukọjẹ lo maa n saba jẹ fun Naijiria.

Ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria gbagbọ pe ikilọ Amẹrika yii tumọ si pe ijọba ni lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ kaakiri orilẹede Naijiria.