Lẹ́yìn ò rẹyìn, Mahmoud Sadis Buba, tó mi orí ayélujára tìtì yọwọ́ nínú ètò ìdìbò 2027, ṣàlàyé ìdí abájọ

Oríṣun àwòrán, Mahmoud Sadis Buba/Facebook
Gbajumọ oloṣelu, Mahmoud Sadis Buba ti ọpọ mọ si ''Abin Al'ajabi'' to fẹ dupo ile aṣoju-ṣofin l'Abuja ti yọwọ ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Buba kede igbesẹ rẹ yii loju opo Facebook rẹ lọjọ kẹrindinlogun oṣu Karun un ọdun yii.
Igbesẹ yii wa ninu lẹta to kọ si alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kaduna.
Buba sọ pe igbesẹ oun lati ma dije mọ fun ipo aṣoju-ṣofin l'Abuja wa ni ibamu pẹlu nnkan ti ẹgbẹ oṣelu APC fẹ.
''Igbesẹ mi yii ko rọrun rara, mo gba lati ma dupo oṣelu mọ ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ lẹyin tawọn alẹnulọrọ ninu bawa yanju ede-ai-yede to wa ninu ẹgbẹ.
Mo pinnu lati ma dije mọ fun ipo aṣoju-ṣofin niluu Abuja lẹyin ti mo ti ba ẹbi, awọn abẹnugan lagbo oṣelu atawọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ.
Mo gbagbọ wi pe o dara ki gbogbo wa ninu ẹgbẹ ṣe atilẹyin fun ẹni ti yoo ba dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC,'' Buba ṣalaye.
Ọdọmọde oloṣelu naa to wa lati ipinlẹ Kaduna ni ọpọ eeyan ti n sọ nipa rẹ lori itakun ayelujara lẹyin ti fidio kan ṣafihan rẹ nibi ti ẹgbẹ APC ti n ṣayẹwo fun un niluu Zaria lati dije fun ipo aṣoju-ṣofin l'Abuja.
Lara nnkan to jẹ ki ọpọ eeyan maa sọ nipa fidio naa ni bi ọkunrin naa ti ni ara kekere ati ariyanjiyan nipa ọjọ ori rẹ.
Awọn eeyan kan sọ pe ọkunrin naa to to iye ọmọ ọdun ti wọn pe e, oriṣiiriṣii iwe lawọn eeyan n gbe sori ayelujara nipa ọjọ ori rẹ.
Amọ, ko sẹni to le sọ ni pato ọjọ ori ọdọkunrin naa.
''Bi ara mi se ri kii kọmi lominu, tori Eledua lo dami bẹẹ''
Ṣaaju ko to kede pe oun ko ni dije mọ ni o ti sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC wi pe ẹni ọdun mẹẹdọgbọn loun, oun si koju oṣuwọn lati dupo naa gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ṣe laa kalẹ.
Bakan naa lo tun sọ pe ara oun to kere ko ni ṣakoba fun oun lati ṣoju awọn eeyan oun toun ba wọle.
O ni lati inu ẹbi oun papaa julọ lati ọdọ baba baba oun loun ti jogun iru ara bẹẹ.
Buba fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan oun gan an lo sọ pe ko dije tori iṣẹ to pọ nilẹ lati ṣe.
''Bi ara mi se ri kii kọmi lominu, tori Eledua lo dami bẹẹ.
Kaka ki n maa ronu nipa bi ara mi ṣe ri, o maa n jẹ nnkan iwuri fun mi ni.
Awọn eeyan mii maa n bu mi wi pe lara kekere ni mi, wọn ni mo kuru mọlẹ.''
Buba ni iṣẹ awakọ loun n ṣe tẹlẹ, amọ, oun ni alaga ẹgbẹ to n polongo ibo fun Aarẹ Bola Tinubu ati Uba Sanni fun eto idibo ọdun 2027 bayii.


























