Ṣé lóòótọ́ ni pé ìdìbó 2027 tó ń bọ̀ ló jẹ́ kí ètò ààbò mẹ́hẹ ní Naijiria? Ohun tí a mọ̀ rèé

Eekan ti wọn maa n fi so ẹran tawọn agbesunmọmi ti danu sun ati ọkọ kan to ti jona rau rau

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba Naijiria, Godswill Akpabio, lo sọrọ kan laipẹ yii. O ni iṣoro ai si aabo to n peleke si i lorilẹede yii lasiko yii ko deede ri bẹẹ, idibo to n bọ lọna lo fa a.

Akpabio ṣo pe bi idibo ba lọ tan, araalu paapaa yoo ri i pe wọn ko ni i gburoo ado oloro kan ṣoṣo.

O fi kun un pe awọn ọta Aarẹ Tinubu ni wọn fẹ fi rogbodiyan da a duro nibi iṣẹ rere to n ṣe.

Bi Akpabio ṣe sọrọ naa ni awọn eeyan kan ti gba pe bẹẹ lo ri loootọ, ṣugbọn ọpọ araalu ni won ni ohun ti ko ri bẹẹ ni Akpabio sọ.

Ọpọ eeyan gbagbọ pe ojutuu lo yẹ ki ijọba wa si ijinigbe, ipaniyan ati ikọlu ọlọkan-o-jọkan to n waye.

Wọn ni ki i ṣe pe ki wọn maa wa awawi lori ohun to n fa rogbodiyan kaakiri.

Ṣugbọn ṣe idibo ọdun 2027 to n bọ lọna lo n mu igbesunmọmi pọ si i loootọ?

'Idibo maa n ni ipa lori aabo araalu'

Nigba to n ṣalaye ajọṣepọ to wa laaarin eto aabo ati idibo, Ọmọwe Kabiru Adamu, oludasilẹ ileeṣẹ eto aabo Beacon Security, lorilẹede yii, sọ pe iwadii ti fi han pe ajọṣepọ wa laaarin aabo ati idibo loootọ.

Ọmọwe Adamu sọ pe iwadii ti ileeṣẹ oun ṣe, fidi ẹ mulẹ pe eto aabo maa n mẹhẹ ni Naijiria bi idibo ba n bọ.

"Akọsilẹ ti a ko jọ fi han pe lati 2007, bi ayipada ijọba ba ti fẹ waye, iṣoro ai si aabo yoo pọ si i. "

Adamu sọ pe igun meji ni oṣelu pin si, oṣelu abẹle ati ti oke okun.

"Ọtọ lawọn to n ko ẹgbẹ jọ nile ti wọn fi n da wahala silẹ, ọtọ si ni tawọn to n gbe loke okun tawọn naa n ṣe tiwọn."

Bẹẹ ni Dokita Adamu ṣalaye.

Ki lo de to jẹ asiko ibo ni eto aabo maa n mẹhẹ si i?

Alaye ti onimọ nipa eto aabo naa ṣe lori idi ti eto aabo fi maa n buru si i lasiko idibo ni pe awọn kan wa ninu ẹgbẹ to n da wahala silẹ, to jẹ wọn ni nnkan pọ pẹlu oṣelu.

"Ati pe awọn oloṣelu kan lo n da awọn ẹgbẹ yii silẹ, ti wọn n lo wọn lati mu erongba oṣelu wọn ṣẹ."

Adamu lo sọ bẹẹ.

O fi oloṣelu ti wọn o ba fẹran lagbegbe kan ṣalaye, Adamu sọ pe oloṣelu naa le lo gbogbo agbara rẹ lati ri I pe won ko polongo ibo lagbegbe naa.

O ni to ba si ṣee ṣe fun un, yoo ri I pe idibo ko waye nibẹ rara.

"Akawe miran ree, bi wọn ba ji awọn akẹkọọ gbe nile ekọ, ẹ maa ri I pe ijọba yoo pe awọn kan, wọn yoo si fi awọn ọmọ naa silẹ lai jẹ pe nnkan kan ṣe wọn.

"Eyi nikan gan-an to lati jẹ ka mọ pe awọn oloṣelu ni ajọṣepọ pẹlu awọn ẹgbẹ yii, wọn mọ wọn ati ibi ti wọn wa."

"Ko yẹ ki ijọba wa awawi, ọna abayọ lo yẹ ki wọn wa fun aabo ti ko to"

Gẹgẹ bi Ọmọwe Adamu ṣe wi, o ni bo tilẹ jẹ pe oṣelu ti da pọ mọ ai si aabo, sibẹ, awawi ati didi ẹbi ru oṣelu tabi ijọba to kọja kọ ni ojutuu si wahala yii.

"Ofin Naijiria sọ pe kijọba pese aabo fun araalu ni, ko sọ pe ki wọn maa wa awijare kankan lai wa ọna abayọ ti aabo yoo fi wa."

Bẹẹ ni Ọmọwe Kabiru Adamu wi.

O ni ijọba atawọn alakooso nipo agbara kọọkan, gbọdọ wa ọna ti iṣoro ai si aabo yii yoo fi wa sopin, ko yẹ ki wọn dagunla si i.

"Bo tilẹ jẹ pe ọwọ oṣelu wa ninu ai si aabo, iyẹn ki I ṣe idi kan ti ijọba yoo fi maa wi awawi, tabi tabuku oṣelu.

"Ki wọn wa ọna ti iṣoro naa yoo fi wa sopin ni."

Bẹẹ ni Ọmọwe Adamu ṣalaye.