Queen Elizabeth II: Wo àwòrán bí àwùjọ àgbáyé ṣe ń dárò ikú Ọbabinrin

Afẹnifẹre kan n gbe ododo kalẹ si iwaju ileesẹ ijọba Gẹẹsi nilu Washington DC
Àkọlé àwòrán, Afẹnifẹre kan ree to n gbe ododo kalẹ si iwaju ileesẹ ijọba Gẹẹsi to wa nilu Washington DC ni Amẹrika
Published

Kaakiri orilẹede agbaye ni isẹ ibanikẹdun ti n wa lẹyin iku ọba ilẹ Gẹẹsi, Ọbabinrin Elizabeth to papoda.

Ọkunrin kan n fa asia wa silẹ ni olu ilu orilẹede Amẹrika, Washington DC
Àkọlé àwòrán, Ọkunrin kan n fa asia wa silẹ ni olu ilu orilẹede Amẹrika, Washington DC

Wọn ti fa ọpọ asia de idaji lawọn ibudo lorisirisi, to fi mọ ile ijọba Amẹrika ati ileesẹ ijọba ni Washington DC.

Ẹrọ ikede kan ree ni ikorita Times Square, nilu New York, to n bu ọla Ọbabinrin
Àkọlé àwòrán, Ẹrọ ikede kan ree ni ikorita Times Square, nilu New York, to n bu ọla Ọbabinrin

Awọn ero ti n kora jọ pọ lati se idaro, ti wọn si n gbe ododo silẹ ni iranti Ọbabinrin Elizabeth.

Ile gagara to wa nilu Tel Aviv, lorilẹede Israel ni wọn tan ina si bii ami asia ilẹ Gẹẹsi
Àkọlé àwòrán, Ile gagara to wa nilu Tel Aviv, lorilẹede Israel ni wọn tan ina si bii ami asia ilẹ Gẹẹsi
Aworan Ọbabinrin ni wọn gbe siwaju ibudo igbafẹ kan ni Santa Monica, lorilẹede Los Angeles
Àkọlé àwòrán, Aworan Ọbabinrin ni wọn gbe siwaju ibudo igbafẹ kan ni Santa Monica, lorilẹede Los Angeles
Brecken Armstrong n ra ife imumi alawo gẹgẹ bii ẹbun iranti ti wọn ya aworan Ọbabinrin si lagbegbe Pasadena, California
Àkọlé àwòrán, Brecken Armstrong n ra ife imumi alawo gẹgẹ bii ẹbun iranti ti wọn ya aworan Ọbabinrin si lagbegbe Pasadena, California
Olootu ijba orilẹede Canada, Justin Trudeau ka ẹsẹ ọrọ kan lori iku Ọbabinrin
Àkọlé àwòrán, Olootu ijọba orilẹede Canada, Justin Trudeau ka ẹsẹ ọrọ kan lori iku Ọbabinrin

ba to ti pẹ lori itẹ julọ ku ni aafin Balmoral lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun, lẹyin to jọba fun aadọrun ọdun.

President Joe Biden went to the British embassy in Washington to sign a condolences book

Aarẹ Joe Biden lọ si ileesẹ asoju ijọba Gẹẹsi nilu Washington lati fi ọwọ si iwe ibanikẹdun.

Wọn se afihan aworan Ọbabinrin lori amohunmaworan gagara kan ni papa ere bọọlu kan nilu Rome lorilẹede Italy.
Àkọlé àwòrán, Wọn se afihan aworan Ọbabinrin lori amohunmaworan gagara kan ni papa ere bọọlu kan nilu Rome lorilẹede Italy.
Ọkunrin kan n wo ikede iku Ọbabinrin Elizabeth lori Tẹlifisan nilu Nairobi lorilẹede Kenya For Nairobi, Kenya
Àkọlé àwòrán, Ọkunrin kan n wo ikede iku Ọbabinrin Elizabeth lori Tẹlifisan nilu Nairobi lorilẹede Kenya For Nairobi, Kenya