Wo ìdí tí Trump ṣe kọ lẹ́tà, kan sáárá sí Tinubu lórí gbígbógun ti ìgbéṣúmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Bola Tinubu/Facebook
Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ti ni Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti gboriyin fun akitiyan Aarẹ Bola Tinubu lori gbigbogunti iwa igbeṣumọmi ati ipenija aabo to n koju awọn eeyan kan paapaa awọn Kristẹni.
Agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga ninu atẹjade kan to fi soju opo X rẹ ni Trump kan saara si Tinubu lorukọ awọn ọmọ Naijiria.
Onanuga to ṣagbejade lẹta ti Trump kọ si Tinubu naa lọjọ Kẹfa, oṣu Keje ṣafihan pe lẹta naa jẹ idahun si lẹta ti Tinubu ti kọkọ kọ ranṣẹ si Trump amọ Onanuga ko fi lẹta ti Aarẹ Naijiria kọkọ kọ naa lede.
Ninu lẹta naa, Trump gboriyin fun akitiyan ijọba Naijiria lati koju awọn ipenija aabo to n koju Naijiria paapaa eyi to n koju awọn ọmọlẹyin Kristi.
Igbesẹ yii lo n jẹ ayipada si bi Trump ṣe n bu ẹnu lu ijọba Naijiria lori ọna ti wọn n gba lati koju awọn ikọlu to n waye paapaa sawọn ọmọlẹyin Kristi. Ni ọdun to kọja, Trump fẹsun kan pe ijọba Naijiria ko ṣe awọn ohun to yẹ lati da aabo bo awọn Kristẹni to ati pe pipa awọn Kristẹni lọna aitọ n waye. Ijọba Naijiria jiyan awọn ẹsun naa.
Gẹgẹ bi Trump ṣe sọ, o ni ọ jẹ ohun iwuri fun oun lati duro ti Tinubu lori gbigbogunti awọn agbeṣumọmi ati lati ri daju pe orilẹ ede Naijiria duro ire, to si bọ lọwọ iwa igbeṣumọmi.
Awọn ibaṣepọ to ti waye laaarin Naijiria ati Amẹrika laaarin ọdun to kọja si asiko yii
Amọ igboriyin Trump yii lo n waye lasiko ti ibaṣepọ Naijiria ati Amẹrika gbokun si lẹyin awọn awuyewuye to waye lẹyin ti Trump bu ẹnu atẹ lu Naijiria.
Ni oṣu Kọkanla ọdun to kọja, Naijiria ati Amẹrika fẹnuko lati ṣe idasilẹ igbimọ ti wọn jọ maa ṣiṣẹ papọ eyi ti awọn olubadamọran aarẹ orilẹ ede mejeeji dari rẹ lojuna ati mu igbega ba akitiyan gbigbogun ti igbeṣumọmi.
Ibaṣepọ orilẹ ede mejeeji da lori idanilẹkọọ, ṣiṣe ikọlu sawọn agbeṣumọmi papọ, pẹlu erongba lati mu adinku ba ikọlu awọn oniṣẹ ibi naa.
Ni oṣu Kejila ọdun to kọja, orilẹ ede mejeeji pawọpọ ṣekọlu si ikọ agbeṣumọmi Islamic State of West Africa Province, ISWAP ni iwọ oorun ariwa Naijiria.
Bakan naa ni wọn tun jọ ṣe ikọlu sawọn ikọ agbeṣumọmini ẹkun Lake Chad nibi ti wọn ti ṣekupa ogbontarigi agbeṣumọmi, Abubakar Al-Minoki, ẹni ti orilẹ ede mejeeji juwe bii ọkan lara olori ikọ awọn agbeṣumọmi naa.
Bẹẹ naa ni wọn ni ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ lo tun ba ikọlu naa lọ.
Ni ọsẹ to kọja, igbakeji akọwe ijọba Amẹrika fun Africa, Frank Garcia ṣe abẹwo si Abuja nibi to ti ṣepade pelu awọn alaṣẹ ijọba Naijiria, to si jẹjẹẹ ibaṣepọ to danmọran laaarin orilẹ ede mejeeji lori ọrọ aabo atawọn ibaṣepọ mii.





























