Ọdún mẹ́rin kò ní tó fún mi láti pari gbogbo iṣẹ́ takuntakun tí mo ti fọwọ́ bà – Gómìnà Adeleke
Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun ti ṣalaye pe idi ti oun fẹ fi lọ fun saa keji nipo ni lati le pari gbogbo awọn iṣẹ rere ti oun ti rawọ le ni saa akọkọ oun.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba lori ilepa rẹ fun idibo gomina to n bọ lọna.
O ni nnkan to waye l'Ekiti ko lee waye l'Ọṣun nitoripe oun gbagbọ pe oun ti ṣe iṣẹ idagbasoke to ṣee mu yangan fun oun ati ẹgbẹ oṣelu oun lati bori idibo naa.
Gomina Adeleke ṣalaye pe O wu oun ki oun ṣi wa ni ẹgbẹ oṣelu PDP ṣugbọn nigba ti
oun rii pe gbogbo rukerudo to n waye lẹgbẹ le ṣe akoba fun ọjọ ọla irinajo oṣelu oun loun fi fi ookan ko eeji gba ẹgbẹ oṣelu miran lọ.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina Adeleke ni oun fi ọrọ to Aarẹ Bọla Tinubu leti lori igbesẹ ati kuro lẹgbẹ oṣelu PDP nigba naa, ṣugbọn igbiyanju aarẹ ni pe ki oun dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC. Adeleke ni oun ṣalaye fun aarẹ nigba naa pe yoo nira lati ba awọn eeyan bi gomina ana ni ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla, ati oludije fun ẹgbẹ oṣelu naa bayii ṣe pọ bi oun ba darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Amọ o fi kun un pe oun sọ fun aarẹ pe Aarẹ loun yoo ba ṣiṣẹ fun idibo si ipo aarẹ nikan, lẹyin eyi ki ọlọmu di ọmu iya ẹ mu ni.
Mo da ara mi loju pe mo ṣe iṣẹ to n sọrọ
Gomina Adeleke ni ataraalu atawọn oṣiṣẹ ni wọn ri iṣẹ ti oun ṣe ni ipinlẹ Ọṣun.
"Lati ọdun mẹrin ti mo ti de ipo, mo fẹ le sọ pe iṣẹ ni mo fi gbogbo rẹ ṣe"
O ni gbogbo awọn awọn ileri ti oun ṣe silẹ nigba ipade itagbangba BBC News Yoruba lọdun mẹrin sẹyin loun ti mu ṣẹ.
Ẹ wo fidio yii lati mọ sii nipa awọn ileri yii atawọn ti o ti mu ṣẹ ninu rẹ.



