Ogun Abẹ́lé Sudan: Akọ̀ròyìn tó há sínú ogun fún ọdún mẹ́ta sọ ohun tójú rẹ̀ rí

Mohamed Suleiman gbójú sókè láti wo ẹ̀rọ ayàwòrán, ó da aṣọ bora.

Oríṣun àwòrán, Mohamed Suleiman

Àkọlé àwòrán, Mohamed Suleiman kọminú lórí bí àgbáyé kò sẹ wá bí ogun abẹ́lé Sudan ṣe máa wá sópin tó sì ń wọ ọdún mẹ́rin lọ báyìí.
    • Author, Barbara Plett Usher
    • Role, Africa correspondent
    • Author, Mohamed Zakaria
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Níṣe ni Mohamed Suleiman bú skkún gbaragada ní kété tó wọ ọ̀fíìsì iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ ní Port Sudan lọ́jọ́ Kẹtàlá, oṣù Kìíní.

Kò gbọ́ kí fóònù rẹ̀ dún láti ìgbà tí ogun Sudan ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn láàárín iléeṣẹ́ ológun àtàwọn ikọ̀ Rapid Support Forces, RSF.

Suleiman, tó jẹ́ akọ̀ròyìn, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ríbi jáde sí Port Sudan ti há sí ìlú el-Fasher, ìlú tí kò ti sí ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ níbẹ̀ láti ìgbà tí ogun náà ti ń wáyé. Suleiman kò ríbi bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí ó ń kojú nínú ibi tó wà lásìkò náà.

"Níṣe ni gbogbo rú mi lójú bí mo ṣe ri tí àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù wọn," ó sọ fún BBC.

"Fóònù mi kò dún fún gbogbo ọdún mẹ́ta náà. Omi ẹkún kàn ń dà lójú mi bí mo ṣe fi síìmù sínú fóònù mi ni."

Bí fóònù rẹ̀ ṣe tàn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ láti ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ń wọ orí fóònù náà. Onírúurú ìròyìn nípa àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀, àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tó ti jáde láyé, àwọn ọ̀rẹ́ tó ń bèèrè bóyá ó ṣì wà láyé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

"Ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni èèyàn kan pè mí tó ń sọ pé òun rò pé mo ti kú, àwọn èèyàn kan sọ fún pé mo wà ní Port Sudan ṣùgbọ́n kò gbàgbọ́ pé èmi ni òun ń bá sọ̀rọ̀ àyàfi ìgbà tí mo pè é padà lórí fídíò."

Suleiman ní àìgbọ́ nǹkankan nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri àgbáyé náà burú bíi ogun tó ń lọ.

Ó júwe bí wọ́n ṣe ń lo dúróònù àti àdó olóró pa àwọn èèyàn àti bí wọ́n ṣe ń fi ìsémọ́ gbẹ̀mí àwọn èèyàn ní el-Fasher látọwọ́ àwọn ọmọ ogun RSF fún odidi ọdún kan àbọ̀ bíi ohun tó burú gidi.

Ó ní ọjọ́ táwọn ọmọ ogun náà padà gba àkóso ìlú náà pátápátá nínú oṣù Kẹwàá ọdún tó kọjá dàbí pé àwọn ń gba ìdájọ́ lójú ayé ni.

Ọjọ́ tí el-Fasher ṣubú ni ọ̀kan lára àwọn àsìkò tó burú jùlọ láti ìgbà tí ogun abẹ́lé náà bẹ̀rẹ̀ ní olú ìlú Sudan, Khartoum lọ́jọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2023.

Kò pẹ́ tó fi tàn dé àwọn ẹkùn míì ní orílẹ̀ èdè náà pàápàá ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Darfur tí àwọn ọmọ ogun RSF ti lágbára púpọ̀ tó sì jẹ́ ibi tí el-Fasher wà.

Bí ogun náà ṣe ń wọ ọdún mẹ́rin lọ báyìí, ogun náà ti pín sí ọ̀nà méjì láàárín ẹkùn táwọn iléeṣẹ́ ológun ń ṣàkóso àti ibi tí àwọn ikọ̀ RSF ń ṣe àkóso rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Sudan ni wọ́n ti fọ́nká káàkiri báyìí, àwọn míì ti sá lọ sí orílẹ̀ èdè mìíràn lójúnà àti bọ́ lọ́wọ́ ìpèníjà tó ń bá gbogbo ayé fínra.

Obìnrin Sudan kan tó sá kúrò ní ilé àwọn aṣàtìpó ní Zamzam tó ń lọ sí Tawila nítorí ogun tó ń wáyé láàárín àwọn iléeṣẹ́ Sudan àti RSF ní North Darfur, Sudan lọ́jọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹrin, 2025.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Many people have fled their homes to escape the fighting and ended up in camps either inside or outside Sudan
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbogbo ìgbìyànjú Amẹ́ríkà láti fòpin sí ogun náà ní tùbí-ǹ-nùbí ló ti já sí pàbó, bí àwọn alágbára ní ẹkùn kọ̀ọ̀kan ń ṣe àtìlẹyìn fún wọn láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ogun náà.

Ohun tí Mohamed Suleiman sọ yìí jẹ́ ohun tó burú jùlọ nípa ogun náà, tó sì ṣàlàyé bí ogun ṣe ń gba oúnjẹ, ilé, ìgbé ayé lọ́wọ́ àwọn èèyàn.

Àwọn aráàlú ní el-Fasher ni wọ́n kojú ìkọlù láàárín àwọn RSF àti ikọ̀ alájàńgbilà lábẹ́nú èyí tó mú káwọn ọmọ ogun rí ìlú náà gbà.

Báwọn alájàngbilà ṣe ń sé àwọn èèyàn mọ́lé ni àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN ti kéde agbègbè náà bíi ibi tí iyàn ti ń wáyé.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n ń wá ọ̀nà láti sá kúrò ní agbègbè náà bí àwọn RSF ṣe ń súnmọ́ wọn sí.

"A rí òkú àwọn ọmọdé ní ojú ọ̀nà," Suleiman sọ.

"A rí àwọn obìnrin tí wọ́n ń sunkún nítorí ebi àti àìrí omi mu, tí wọn kò lè gbé àwọn ọmọ wọn nítorí kò sí agbára fún wọn, tí wọ́n sì fi àwọn ọmọ náà sílẹ̀ lójú ọ̀nà.

"Àwọn èèyàn tí a mọ̀ ni wọ́n ṣùgbọ́n a ò lè pèsè ohunkóhun fún wọn.

"Kò sí oúnjẹ, omi tàbí ohunkóhun láti fi gbé wọn. A kàn ń gba orí wọn kọjá, sunkún, a sì ń kọjá lọ," Suleiman ṣàlàyé.

Òun náà kojú irú ewu yìí ní oṣù Keje, ọdún 2025 nígbà tí àdó olóró kan dbọ́ sílẹ̀ ní ibi tí kò jù ìwọ̀n mítà méjì sí ibi tó wà lọ.

Àwọn èèyàn tó ń sá kúrò ní ilé àwọn aṣàtìpó tó wà ní Zamzam nígbà táwọn ikọ̀ RSF ẹ ìkọlù síbẹ̀ lọ́dún 2025

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbìyànjú láti sálọ sí ibi tí ààbò wà díẹ̀, ìlú Tawila. Gbogbo àwọn ọ̀nà náà ni ó kún fún òkú àwọn èèyàn àtàwọn tó farapa.

Suleiman sọ pé tó bá jẹ́ pé àwọn ní ọ́nà láti pè fún ìrànlọ́wọ́ fún àwọn èèyàn náà, àwọn kò ní fi àwọn tó farapa sílẹ̀ láì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn.

Ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan ni òun kò lè sọ nítorí bí wọ́n ṣe burú tó, tó sì sọ pé gbogbo àgbàyé ni kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní el-Fasher títi di àsìkò yìí.

Ikọ̀ RSF gbà pé títẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀ wáyé nígbà tí wọ́n fẹ́ gba ìlú el-Fasher ṣùgbọ́n tí wọ́n ní àwọn ń ṣe ìwádìí bí àwọn nǹkan náà ṣe burú tọ àti pé kò tó bí àwọn ikọ̀ ológun ṣe kéde rẹ̀.

Igun méjéèjì ni wọ́n ti fẹ̀sùn títẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀ kàn tó fi mọ́ fífi àdó olóró láti ojú òfurufú gbẹ̀mí àwọn aráàlú.

Láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀ ni kò tis í ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán ní ìlú náà nítorí ogun àti àìsí epo láti fí tan iná.

Àwọn èèyàn míì gbé Starlink wọlé láti fi kàn sójú òpó ayélujára àmọ́ owó rẹ̀ pọ̀ tó sì jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun ló ń ṣe àkóso rẹ̀ nígbà tí ìlú náà ṣì wà ní àkóso wọn.

Suleiman sọ fún BBC pé gbogbo àwọn tí ikọ̀ RSF bá ríi lọ́wọ́ wọn ni wọ́n ń gbà, tó sì jẹ́ pé àwọn akọ̀ròyìn wà nínú ewu tí wọ́n bá fi lè ri lọ́wọ́ wọn.

Suleiman mú fóònù lọ́wọ́, ó ń wo alagbalúgbú omi

Oríṣun àwòrán, Muhamed Eid

Suleiman kọminú pé kò sí ohun tó ń òfin àgbáyé.

"Kò sí nǹkan tó ń jẹ́ ìṣọ̀kan àgbáyé. Tó bá jẹ́ pé àwọn òfin wà tó de àgbáyé ni, kò sí bí àwọn èèyàn yóò ṣe máa jáde láyé ní ojoojúmọ́ ní el-Fasher láì sí oúnjẹ, omi, tí wọ́n sì ń ju àdó olóró àti dúróònù sí wọn.

"Kò sí dídáwọ́ ogun dúró, kò sí òògùn, kò sí àwọn ohun tí èèyàn nílò láti fi gbáyé."

Ìlànà láti pè fún àlááfíà tí Amẹ́ríkà, Saudi Arabia, Unted Arab Emirate àti Egypt gbé kalẹ̀ láti wá ojútùú sí ogun náà ni kò so èso rere.

Aṣojú Amẹ́ríkà Massad Boulus ń wà ọ̀nà láti rip é àwọn igu méjéèjì dáwọ́ ogun úró fún ìgbà kan ná àmọ́ èyí kò ì tíì bọ́ si.

Sudan tí Mohamed Suleiman ń rí báyìí yàtọ̀ sí ohun tó mọ̀ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú bí gbogbo àwọn èèyàn ṣe ti fọ́nká àmọ́ tó ní bí òun ṣe lè sọ̀rọ̀ nípa wọn ń fún òun ní ìwúrí láti ṣe ohun kan fún àwọn èèyàn náà.