Àwọn òṣèré òde òní nílò láti máa ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn tí wọ́n ń kọ, a kìí ṣe eégún oníhòhò - Lere Paimo

Àwọn òṣèré òde òní nílò láti máa ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn tí wọ́n ń kọ, a kìí ṣe eégún oníhòhò - Lere Paimo

Tí a bá ń sọ̀rọ̀ eré tíátà àti sinimá nílẹ̀ Yorùbá, òdú ni àgbà òṣèré Lere Paimo, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Eda Onile Ola, kìí ṣe àìmọ̀ fún olóko.

Ó ti lé ní ogójì ọdún tí àgbà òṣèré náà ti ń kópa ribiribi nínú sinimá Yorùbá, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń rántí àwọn ipa mánigbàgbé tí ó kó níú àwọn eré bíi Ogbori Elomoso, Saworoide, Agogo Eewo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí àgbà òṣèré náà ṣe pẹ̀lú BBC News Yorùbá ló ti ṣàlàyé bí ìrìnàjò sínú eré tíátà ṣe bẹ̀rẹ̀ àti ibi tó dé dúró lónìí.

Àgbà òṣèré náà ṣàlàyé pé láti ìgbà tí àwọn tí òun ti wà ní kékeré ni òun ti fẹ́ràn láti máa ṣe eré fíìmù èyí tó mú kí òun pa iṣẹ́ olùkọ́ tí òun lọ kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni tì.

Lere Paimo ní ifẹ́ eré tíátà ni ó gbé òun dé ọ̀dọ̀ Oyin Adejobi kí òun tún tó bọ́ sí ọ̀dọ̀ olóògbé Duro Ladipo láti máa ṣe eré tíátà.

Ó sọ pé ọ̀dọ̀ Duro Ladipo ni òun wà títí tí òun fi dá dúró láàyè ti òun náà, tí òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé fíìmù tí òun jáde.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ọjọ́ tí Inú rẹ̀ bàjẹ́ jùlọ láyé, Alàgbà Lere Paimo ní ọjọ́ tí òun lọ ra ọkọ̀ kejì àmọ́ tí àwọn ní ìjàmbá ọkọ̀ tó gbẹ̀mí májínà òun ni inú òun bàjẹ́ jùlọ.

Bákan náà ló ní ọjọ́ tí ìjọba fi oyè MFR dá òun lọ́la pẹ̀lú àwọn èèkàn ìlú míì ni inú dùn jùlọ.

Àgbà òṣèré náà tún sọ ọ́ pé òun kò ì tíì pa eré ṣíṣe tì gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn kan ṣùgbọ́n tó kàn jẹ́ pé ìtàn tó bá ní ìtumọ̀, tí wọ́n sì pe òun sí nìkan lòun máa ń kópa nínú rẹ̀ báyìí.