Ìjọba Aiyedatiwa fẹ́ lé wa kúrò ní Agọ Ireti, ó tún kọ̀ láti fún wa ní owó oṣù wa – Àwọn olùgbé Agọ Ireti

Àkọlé fídíò, Agọ Ireti Akure
Ìjọba Aiyedatiwa fẹ́ lé wa kúrò ní Agọ Ireti, ó tún kọ̀ láti fún wa ní owó oṣù wa – Àwọn olùgbé Agọ Ireti
Published

Awọn olugbe Agọ Ireti, to wa niluu Akure, nipinlẹ Ondo, ti rawọ ẹbẹ si ijọba ipinẹ ọhun ko ma le wọn kuro nibi ti wọn n gbe lọwọ yii.

Ago Ireti ni inu ọgba ti awọn agbalagba ti wọn ni arun ẹtẹ atawọn arun mii n gbe, eyii ti wọn ṣagbekalẹ rẹ lọdun 1943 lati ṣeranwọ fun awọn eeyan naa to da bii pe o ti tan fun.

Amọ lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn olugbe Agọ Ireti naa ṣe iwọde niluu Akure lẹyin ti wọn ni awọn gbọ pe ijọba ipinlẹ ọhun fẹ le awọn kuro nibẹ lọ si agbegbe mii.

Nigba ti BCC Yoruba lọ si Agọ Ireti lati ba awọn olugbe inu ọgba ọhun sọrọ, wọn ni ijọba ipinlẹ Ondo ti pa awọn ti, koda, niṣe ni wọn n tọrọ bara bayii ki wọn to le jẹun.

Ọkan lara awọn olugbe Agọ Ireti to ti n gbe nibẹ lati ọdun 1979, Victori Dada sọ pe bii igba ti eeyan ba gba idajọ iku ni yoo ri ti ijọba ba le awọn kuro ninu ọgba ọhun.

Arabinrin Dada ni ko si ibomii ti oun le lọ nitori gbogbo awọn to le tọju oun ni wọn ti jade laye.

Ẹlomii ti a tun ba sọrọ nibẹ, Abayomi Olawoye sọ pe iwọnba owo kereje ti awọn n gba tẹlẹ ni wọn tun ti gbẹsẹlẹ, koda, o ni oun ti ni aisan ẹjẹ riru bayii.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti a ba bọ lati Ago Ireti.