Ọkùnrin kan ṣekúpa èèyàn mẹ́ta nínú ìdílé kan náà, ariwo sọ

Ọwọ́ tí wọ́n kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Níṣe ni gbogbo ìlú Okitipupa ní ìpínlẹ̀ Ondo pa lọ́lọ́, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ bí ọkùnrin kan ṣe ṣá àwọn èèyàn mẹ́ta nínú ẹbí kan náà pa.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, wọ́n ní ọkùnrin tó ṣá àwọn èèyàn náà pa ló jẹ́ ẹbí àwọn èèyàn náà, tí ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ọkùnrin sì wà nínú àwọn tó pa náà.

Àwọn kan ń sọ pé ọkùnrin tó ṣá àwọn èèyàn náà ní àìsàn ọpọlọ ń dà láàmú ṣùgbọ́n BBC New Yoruba kò le fìdí èyí múlẹ̀.

Wọ́n ní inú ilé ni àwọn èèyàn náà wà nígbà tí ọkùnrin náà wọlé tọ̀ wọ́n lọ, tó sì fi àṣá ṣá wọn pa.

Lára àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn náà ni akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ forúkọ sílẹ̀ fún ìdánwò JUPEB àti àwọn ọmọ méjì míì.

Aráàlú kan, tí kò fẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn dárúkọ òun sọ pé ọkùnrin tó ṣe ìkọlù náà ní ìgbàgbọ́ wà pé ó ní àìsàn ọpọlọ, tó sì ṣe ìkọlù sí ọmọ rẹ̀ náà.

Ẹni náà sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kó ìpayà ńlá bá gbogbo ìlú, tí ọkùnrin tó sì ṣèkọlù sáwọn ọmọ náà sálọ lẹ́yìn ìkọlù náà.

Ìwádìí fi hàn pé olórí ẹbí náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Baba Agbeye àti ìyàwó rẹ̀ jáde kúrò nílé lọ sí oko epo wọn lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí.

Ìròyìn ní wọ́n pàdé afurasí náà lọ́nà nígbà tí wọ́n ń padà sílé, tó sì sọ fún wọn pé ilé náà ni òun ti ń bọ̀, tí wọn kò sì mọ̀ pé, ó ti pa àwọn ọmọ sílé.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ̀rọ̀

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, nígbà tí wọ́n ń fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ sọ pé ọjọ́ Keje, oṣù Kẹrin ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà wáyé ní agbègbè New Site, Doctors Road, Okitipupa.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Ondo, Abayomi Jimoh fi léde ṣàlàyé pé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agbeye ló lọ fẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá pé ọmọ òun Femi Agbeye ṣe ìkọlù sáwọn àbúrò rẹ̀.

Ó ní Agbeye sọ fún àwọn ọlọ́pàá pé, Femi, ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, fi àdá ṣá àwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́ta pa lásìkò tí òun kò sí nílé, tó sì ṣokùnfà ikú àwọn ọmọ náà.

Ó sọ pé àwọn ọmọ tó kù náà ni Bose Agbeye, ẹni ogún ọdún, Dupe Agbeye, ọmọ ọdún méje àti Blessing Agbeye ọmọ ọdún márùn-ún.

Jimoh ní kété tí ìròyìn náà tó àwọn ọlọ́pàá létí ni wọ́n lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọ́n sì ti gbé òkú àwọn ọmọ náà lọ sí ibi tí wọ́n máa ń ko àwọn òkú pamọ́ sí ní State Specialist Hospital Morgue, Okitipupa, fún àyẹ̀wò.

Ó fi kun pé ọjọ́ náà ni ọwọ́ tẹ afurasí náà, tí ìwádìí sì ti ń lọ lọ́wọ́ àti pé kété tí ìwádìí bá ti parí ló máa fojú ba ilé ẹjọ́.

Bákan náà ló sọ pé Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Ondo korò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tó sì sọ àrídájú rẹ̀ pé ìdájọ́ òdodo máa wáyé lórí rẹ̀.

Ó tún rọ àwọn aráàlú láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá, kí wọ́n sì máa pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò láti mú kí ìwádìí wọn le rọrùn.