"Ẹ má fi ìmọ̀ ẹ̀rọ ìtàkùn àgbàyé Tech wé Yahoo, èdé Yorùbá tí mo fí ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ń mú kí owó wọlé fún wọn"
Ni saa ti a wa yii, imọ ẹrọ nipa ayarabiasa ati itakun agbaye lo gbaye kan, ohun si lo n pese isẹ fun ọpọ eeyan labẹle ati loke okun.
AMọ bi imọ yii se jẹ gbajugbaja si, ni awọn kanda kan wa ninu irẹsi awọn eeyan to n lo itakun agbaye.
Idi ni pe awọn eeyan kan wa to n lo isẹ naa lati fi lu jibiti lori ayelujara ti a mọ si Yahoo tabi 419.
Sugbọn ọpọ eeyan lo ri imọ nipa itakun agbaye yii ti a mọ si IT Technology bii eyi to le koko bii oju ẹja lati mọ.
Sugbọn a ri ọkunrin kan to kẹkọọ gboye imọ ijinlẹ ni fasiti, to si n fi ede Yoruba kọ awọn eeyan lori ayelujara nipa imọ Tech.
BBC News Yoruba ba ọkunrin naa, Theophilus Adegbohungbe sọrọ, lati mọ idi to se n fi ede Yoruba kọ awọn eeyan ni imọ Tech, bawo lo se rọrun si ati pe, bawo ni owo se wa nidi rẹ si?

"Ọpọ eeyan n sọ pe Tech le, amọ nigba ti a bẹrẹ si ni fi ede Yoruba kọ wọn, o rọ loju wọn"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Theophilus Adegbohungbe ni fifi ede Yoruba kọ imọ Tech mu ko rọrun si fawọn eeyan lati ni imọ nipa rẹ
Oludasilẹ ati olukọ agba nibudo ti wọn ti n kẹkọ imọ ẹrọ itakun agbaye Tech in Yoruba naa, sọ bi a ti n kọ awọn eeyan ni isẹ tech ni ede Yoruba pọnbele.
"Ọpọ eeyan maa n wo mi pe, se nitori mo ti wa isẹ, ti mi o ri ni mo se bẹrẹ imọ ẹkọ Tech ni ede Yoruba abi mo fẹ wa maa fi pa owo tabi maa fi pawọn eeyan ni ẹrin ni?
Rara o, kii se ainisẹ lo ba mi de idi Tech ni ede Yoruba.
Ninu ede Tech in Yoruba, a ti ri iyatọ, a si ti ri ohun ti a le fi ede Yoruba se ti a ba fi kọ nnkan.
Ọpọ eeyan lo maa n sọ pe Tech le amọ nigba ti a bẹrẹ si ni fi ede Yoruba kọ wọn, o rọ loju wọn."
"Kii se isẹ lilu jibiti lori ayelujara ti a mọ si Yahoo ni ẹnikẹni to ba n se Tech n se"
Bakan naa ni Theophilus Adegbohungbe salaye ọpọ anfaani to wa ninu nini imọ Tech paapaa fun awọn eeyan ti ko nisẹ lọwọ.
"A maa n kọ awọn eeyan ni isẹ ti wọn le se lati inu ile wọn lai kuro ninu ile, awọn isẹ Tech bii Data Analytic, web develoment, projet management, cyber security ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Kii se isẹ lilu jibiti lori ayelujara ti a mọ si Yahoo ni ẹnikẹni to ba n se Tech n se.
Lootọ ni awọn eeyan miran wa to jẹ pe ti wọn ba ti bori mọle ninu ile wọn, wọn a maa fura si wọn ni adugbo pe se Yahoo ni wọn n se ni.
Koda, wọn le lọ fi ẹjọ rẹ sun awọn agbofinro pe Yahoo lo n se.
Amọ iru awọn to ba n se nnkan bayii, kii se gbogbo wọn lo n se nnkan buruku.
Gẹgẹ bi ẹni to ti wa ninu isẹ Tech fun ọdun mejila, mo n sọ fun yin pe, awọn nnkan wa ni ori ikanni ayelujara ti awọn eeyan n se.
Igba miran, emi gangan funra mi le wa ninu ile, ki n ma jade tori inu ile mi ni isẹ mi wa, n ko si nilo lati maa gan mọto kiri pe mo fẹ lọ sibi kan."
"Afojusun mi fun Tech ni ki awọn eeyan ti ko ri nnkan se, wa si Tech tori ko si ẹni ti ko ni ẹbun lati se"
Adegbohungbe tẹsiwaju nipa awọn afojusun rẹ fun imọ Tech lọjọ iwaju.
"Awọn akẹkọ to wa loke okun maa n ro pe tori a n fi ede Yoruba kọ Tech, boya ibilẹ ni wa, wọn ko si mọ pe mo lọ sile ẹkọ giga fasiti ti Oye Ekiti.
Ti wọn ba ti de, wọn maa n fẹ fi burẹdi ko wa lomi ọbẹ ni, nigba ti wọn ba ri pe a ko kere rara ni apa wọn to maa n jabọ.
Awọn afojusun mi fun Tech lọjọ iwaju ni ki awọn eeyan ti ko ri nnkan se wa si Tech tori mo gbagbọ pe ko si ẹni ti ko ni ẹbun lati se.
Awọn kan maa n ni fun mi ni update, Update kii se owo, information lo n jẹ update."






