Òjò yóò rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́wàá gbáko – Àyẹ̀wò ojú ọjọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ayẹwo oju ọjọ ti sọ pe o ṣeeṣe ki ojo rọ nipinlẹ Eko lojojumọ fun ọjọ mẹwaa gbako, nigba ti iri yoo sẹ lawọn ipinlẹ mi ni Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe ojo ko ni rọ pupọ ju lawọn agbegbe kan, ayẹwo naa fi han pe omiyale yoo ṣẹlẹ lawọn ibomii, nigba ti awọn kan yoo koju omi loju popo ati ọpọlọpọ sunkẹrẹ-fakẹrẹ.
Omiyale tete maa n waye nipinlẹ Eko latari bo ṣe sunmọ eti omi, paapaa alagbalugbu omi okun Atlantic Ocean.
Awọn onimọ sọ pe bi awọn eeyan ṣe n da itọti sinu gọta ati bi awọn kan ṣe kọ ile si awọn ibi to yẹ ki omi gba kọja wa lara awọn nnkan to n fa ọpọ omiyale ni Eko.
Ayẹwo ti awọn onimọ kan ṣe lọdun 2026 fi han pe ida 12% ilẹ to wa nipinlẹ Eko lo wa nibi ti omiyale ti le ṣẹlẹ latari ayipada oju ọjọ ati bi eto agbegbe naa ṣe ri.
Ijoba ipinlẹ Eko ti di ẹbi omiyale to n waye lẹnu lọlọ yii lu bi omi Ọsa ipinlẹ naa ṣe n ga si.
Kọmiṣọna fun eto ayika ipinlẹ Eko, Tokunbo Wahab ṣalaye pe omi Ọsa naa ti ga ni nnkan bii iwọn mita kan, to n tumọ si pe o n ṣe akoba fun awọn omi to n ṣan lati inu gọta lati kọja.
Wahab sọ pe nnkan yoo maa pada bọ sipo lasiko ti iwọn omi Ọsa naa ba ti n lọ silẹ bo ṣe wa ṣaaju.
O wa rọ awọn olugbe ipinlẹ Eko ki wọn ma ṣe sun asungbera.
O fi kun pe ijọba n bojuto ọrọ naa, ijọba si n ṣe nnkan to yẹ lati ri pe iṣẹlẹ omiyale naa ko fi bẹẹ pa araalu lara.
Wayi o, ijọba ipinlẹ naa di ẹbi iṣẹlẹ omiyale le ayipada oju ọjọ lori, to fi mọ bi ipinlẹ ọhun ṣe sunmọ eti Ọsa, idagbasoke ilu atawọn oju gọta ti idọti ti di.




























