'Mi ò ní ìgboyà rẹ̀': Alicia Lissu sọ̀rọ̀ lórí ipa tí ètò òṣèlú Tanzania ní lórí ìdílé rẹ̀

- Author, Beryl Munoko
- Role, Senior Journalist
- Author, Valeria Cardi
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Fun ọdun kan bayii, Alicia Lissu ko i tii ri ọkọ rẹ tabi ba a ọkọ rẹ, Tundu Lissu, ẹni to jẹ olori ẹgbẹ oṣelu alatako ni Tanzania, to si n koju igbẹjọ diditẹ mọ ijọba.
Alicia, ẹni to n farapamọ si Belgium, ori foonu tabi ọdọ aburo ọkọ rẹ tabi awọn agbẹjẹro ọkọ rẹ lo ti maa n gbọ nipa bi igbẹjọ ọkọ rẹ ṣe n lọ.
O sọ pe oṣu mẹta akọkọ jẹ ohun to lagbara fun oun.
Lissu, ẹni ọdun mejidinlọgọta, ti wa ni ahamọ lati oṣu Kẹrin, ọdun 2025 nigba to n ṣe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu rẹ, Chama cha Demokrasia na Maendeleon – akọmọna Chadema ni "Ko si Atunto, Ko si idibo."
"Ọkan mi gbọgbẹ, o sọ. Kii ṣe igba akọkọ ti wọn maa fi Lissu si ahamọ niyi amọ eyi yatọ."
Ko si aaye fun gbigba beeli, wọn ko jẹ kawọn eeyan maa yọju si, to si n koju igbẹjọ to ṣeeṣe ki wọn dajọ iku fun-un labẹ ofin Tanzania.
Ijọba Tanzania sọ fun BBC ninu oṣu Kiini, ọdun 2026 pe "Labẹ iṣejọba Aarẹ Samia, aaye gba awọn oloṣelu ju ti tẹlẹ lọ bo ṣe fi aaye gba awọn eeyan atawọn oloṣelu lati maa ṣe iwọde ati ipolongo ibo. Tanzania lo n lewaju ninu awọn orilẹ ede to fi aaye gba awọn akọroyin julọ ni ekun ila oorun Africa."
Ijọba naa fi kun pe ofin gbọdọ jẹ titẹle. "Aarẹ Samia pe Tundu Lissu pada si Tanzania lati ibi to ti n ṣatipo lati tẹsiwaju pẹlu eto oṣelu rẹ amọ ko si ẹni to kọja ofin. Ẹjọ Tundu Lissu

Nigba to gbọ pe wọn ti fi ọkọ rẹ si ahamọ, kaka ko lọ si Tanzania, Alicia gbera kuro ni Brussels to ti n gbe lati ọdun 2018 lọ si Amẹrika nibi ti awọn ibeji wọn ti n kẹkọọ. Ọkan ninu awọn ọmọ naa n mura idanwo lọwọ, to si ro pe iroyin naa le da ọkan wọn ru.
O ni ọpọlọpọ ibeere ni wọn n beere lọwọ oun, ti wọn fẹ mọ boya loootọ wọn maa fi baba awọn silẹ.
"Mo sọ fun awọn ọmọ wa pe baba wọn ni oun ti ọpọ awọn ko ni. Mi o ni iru igboya to ni. Mi o ni awọn ebun rẹ. O yẹ ka maa gboriyin fun ni.
Lẹyin awọn aridaju yii, oun n koju awọn igbeaye tuntun ti oun gan funra rẹ ko ro tẹlẹ.
"Fun igba akọkọ, mo ba ara mi ninu nnkan ti mi o ri atilẹyin kankan lati ọdọ Lissu, ko si nibi pẹlu ara, mi o ri atilẹyin owo kankan latọdọ rẹ, mo si ni lati tọju ara mi atawọn ọmọ mi."
Agbeyẹwo igbe aye ajafẹtọọ ọmọniyan

Oríṣun àwòrán, Alicia Lissu
Igba akọkọ ti Alicia Lissu maa ri bi ọkọ rẹ ṣe le ja fun ominira to ni igba to n kẹkọọ imọ ofin, to n sa pamọ fun awọn ọlọpaa nigba to ṣi w ani akẹkọọ.
Ni ọdun 1990 nigba naa, to wa ninu yara rẹ ni ile ẹkọ fasiti University of Dar es Salaam nigba to gbọ pe eeyan n kan ilẹkun rẹ kikankikan.
"Tundu n mi hẹlẹhẹlẹ, o sọ fun mi pe oun kan nilo ibi ti oun le fara pamọ si."
Awọn akẹkọọ lo n ṣe iwọde ifẹhonuhan ti wọn si pe awọn ọlọpaa lati dawọn lẹkun. Awọn ọlọpaa naa ko aja dani.
O ni o jẹ oun to dunmọ oun pe o ni igboya, to si fẹ kopa ninu eto oṣelu ile ẹkọ.
"Oun ti mo sọ fun ni pe Tundu, o nilo lati ṣọra. Awọn eeyan le ṣe ọ ni ijamba."
Kii ṣe igba yii nikan lo n kọminu lori aabo rẹ.
Ọgbọn ọdun leyin naa, Alicia n sọrọ lati Belgium. Lati maa ṣatipo ni orilẹ ede mii ko si lara erongba rẹ, bẹẹ naa ni ko si fifi si ahamọ, erongba lati gbẹmi rẹ tabi pe yoo maa koju igbẹjọ diditẹ mọ ijọba.
Bi o ṣe n woye nipa igbe aye wọn papọ, ohun to ri kii ṣe itan nipa olori to fi ara silẹ fun igbagbọ rẹ ninu oṣelu, o jẹ itan nipa iyawo to ti pinnu lati gbe agbelebu nipa fifẹ ẹni to fẹ ṣe atunto.
"Oun to wu mi lara Lissu ni pe o jẹ ẹni to nimọ pupọ," Alicia Lissu sọ.
Lasiko ti wọn n sin ilẹ baba won ni awọn mejeeji kọkọ pade, ki wọn to tun pade ni ile ẹkọ imọ ofin iyẹn law school. Wọn jọ maa n lọ kawe ni yara ikawe ni irọlẹ, wọn gbabẹ di ọrẹ ko to di pe wọn w ani lọkọlaya.
O gbagbọ pe igbe aye to gbe nigba to wa ni kekere ninu ilu kekere to gbe ni Tanzania ati baba rẹ to kọ iyanjẹ wa lara ohun to sọ ọ di ẹni to kọ iyanjẹ ati ipa to n tọ.
Ọdun 1995 lo kọkọ dije sile aṣofin amọ to fidi remi. Nigba ti wọn fi maa ṣegbeyawo ni 1997, Alicia ti mọ pe oṣelu maa kopa ribiribi ninu igbe aye wọn.
Ni 2008, Lissu bẹrẹ si ni sọrọ nipa pipada sinu oṣelu to si n gbiyanju lati dije si ile aṣofin. O ṣeranti pe oun ko ronu nipa oṣelu to bẹẹ bikoṣe lati tọ awọn ọmọ wọn.
"Titọ ọmọ pẹlu oloṣelu kii ṣe ohun to maa rọrun rara," o sọ.
Aisi nile fun ọpọ igba nipasẹ ṣiṣe irinajo kaakiri Tanzania lati wa atilẹyin awọn eeyan fun ẹgbe oṣelu rẹ, Chadema ṣokunfa ki o ma si nile fun ọpọ igba.
"Ọdun 2008 ni igba ti a kọkọ jọ ṣe ọdun tuntun lọtọọtọ."
Awọn ẹbi rẹ ko ri fun igba pupọ bi erongba oṣelu rẹ ṣe n kẹsẹ jari.
Igba ti wọn bẹrẹ si ni fi si ahamọ

Oríṣun àwòrán, Alicia Lissu
Ọdun 2010 ni wọn dibo yan-an gẹgẹ bi aṣofin lati ṣoju ẹkun Singida East, to si tete fi ara rẹ han gẹgẹ bi oloṣelu alatako to mu lẹnu.
Alicia ni lẹyin ti oloogbe John Magufuli di aarẹ lọdun 2015 ni ohun gbogbo yipada fun Lissu gẹge bi Alicia ṣe sọ.
Bi Lissu ṣe n sọrọ nipa awọn ipinnu ati iṣe ijọba lo di pe wọn bẹrẹ si ni fi si ahamọ.
"Ọdun 2016 jẹ ọdun to le fun ẹbi mi."
Ọpọ igba ni wọn fi panpẹ ofin gbe e. Ọkan lara ẹsun ni igba to sọ pe wọn ti gba ọkọ ofurufu ijọba kan kalẹ ni Canada nitori gbese ti ijọba jẹ ti wọn ko san.
O sọ pe oṣu kan wa to jẹ pe gbogbo igba ni oun n lọ si agọ ọlọpaa, ile ẹjọ.
Ọdun 2017 ni o tun peleke nigba ti Lissu sọ fun oun pe awọn eeyan kan n tẹle oun.
Pẹlu pe Lissu lọ koju ẹni to wa ninu ọkọ to n tẹle, to si pe fun iwadii, sibẹ ko si ohunkohun to waye.
Alicia ni lati igba naa ni ẹru ti n ba oun fun Lissu ṣugbọn niṣe ni Lissu ṣagidi pe oun ko ni ye wi tẹnu oun.
Ọjọ ti ohun gbogbo yipada
Ni ọjọ Keje, oṣu Kẹsan-an, 2017, Lissu kuro nile aṣofin ni Dodoma lati maa lọ sile. Awọn agbebọn ṣina ibọn bolẹ fun-un, igba mẹrindinlogun ni ibọn ba a ni ikun ati ẹsẹ.
Fun Alicia, wahala rẹ bẹrẹ nigba ti atẹjiṣẹ kan wọ ori foonu rẹ. Nigba ti awọn aworan to ṣafihan ọkọ rẹ ninu aṣọ ti ẹjẹ bo, ẹru ba a pe o ṣeeṣe ki nnkan buruku ti ṣẹlẹ sii.
"Mo pariwo pe wọn ti yinbọn fun Lissu."
Titi di asiko yii, Alicia ko le juwe nnkan to ṣẹlẹ lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye. O wo bi awọn eeyan ṣe pejọ siwaju ile wọn.
O ni igba ti oun de ile iwosan ni Dodoma ti wọn sọ fun oun pe ọkọ oun wa laye, ọkan oun balẹ diẹ ṣugbọn awọn pada nilo lati gbe lọ si Nairobi fun itọju to peye.
Lẹyin itọju rẹ ni Kenya ni wọn fi ranṣẹ si Belgium fun ọpọ ọdun atawọn ọpọlọpọ iṣẹ abẹ.
Fun Alicia, awọn egbo kan ko le jina laelae.
O ni ko i tii si iwadii kankan lori awọn iṣẹlẹ naa, iyẹn si ni ko le jẹ ki egbo naa jina lọkan oun.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Lati ibi to ti n ṣatipo lọ sọgba ẹwọn
Idile naa pada fẹnuko lati maa gbe Belgium bi Lissu ṣe n ṣiṣẹ abẹ ati gbigba itọju.
O ni bi o tilẹ jẹ pe asiko otutu ni awọn de orilẹ ede naa sibẹ ọkan oun balẹ.
Fun igba akọkọ lẹyin ọpọ ọdun, wọn ni afojusun si riri itọju to peye dipo kikan maa gbe lasan.
Lẹyin ti Aarẹ John Magufuli papoda lọdun 2021, ẹni to gba ipo lẹyin rẹ, Samia Suluhu Hassan, ti asiko rẹ si jọ pe o fi aaye gba eto oṣelu, to si rọ awọn to wa ni aajo lati dari pada sile.
Ni oṣu Kiini 2023, ọdun marun-un lẹyin ti wọn yinbọn fun-un, Lissu pada si Tanzania.
O sọ fun mi pe oun nilo lati pada lati lọ ṣatilẹyin oun ati lati lọ lo imọ ofin oun lati ri pe oun gbogbo pada sipo.
O jọ bi ẹni pe igba ọtun ti de pada fun wọn amọ niṣe ni ikọlu mii tun wa niwaju fun Lissu.
Ni bayii, to ba n sọrọ nipa ọkọ rẹ, pẹlu bi igbẹjọ nipa diditẹ mọ ijọba ko ṣe foju han, Alicia ṣi maa n ri ọdọkunrin to sa wa ba a ninu yara nile ẹkọ giga lẹyin iwọde awọn akẹkọọ.
Ọkunrin to ni igbagbọ pe ojuṣe oun ni lati pe iwa irẹnijẹ nija.

Fun Alicia, itẹnumọ yii gan-an ni orisun iwuri ati inira to n koju.
Ohun lo sọ ọ di oloṣelu to da.
"Eyi kii ṣe Lissu to maa n paya, kii ṣe Lissu ti ẹ ko ni da lohun."
Lẹyin ọpọlọpọ igbiyanju lati ba ijọba Tanzania sọrọ, wọn ni ki a ba MInisita fọrọ abẹle, olori ile aṣofin ati Minisita fun ipinlẹ sọrọ papọ ni ẹẹkan naa. BBC kọ lati fọrọ wa awọn mẹtẹẹta lenuwo papọ wi pe ko ba oju mu. Fun idi eyi ijọba kọ lati b awa sọrọ.

























