Ìdílé oyè fún Gómìnà Adeleke ní gbèdéke ọjọ́ méje láti rọ Apetumodu tó ń ṣẹ̀wọ̀n l'Ámẹ́ríkà lóyè

Aworan Gomina Adeleke ati Apetu to n ṣẹwọn lọwọ lorilẹede Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/ others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Idile oye meji pẹlawọn afọbajẹ ni ilu Ipetumodu ni ipinlẹ Ọṣun, ti fun gomina ipinlẹ naa, Ademọla Adeleke ni gbendeke ọsẹ kan pere lati rọ Ọba ilu naa, Apetu ti ilu Ipetumodu loye ko si kede apere ọba ilu naa gẹgẹbi eyi to ṣofo ki wọn le bẹrẹ igbesẹ lati yan ọba tuntun nibẹ.

Awọn aṣoju ile oye mejeeji, Aribile ati Fagbemirokun pe ipade pẹlawọn akọroyin ni ilu Ipetumodu, nibi ti wọn ti fi ero wọn han, Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan ijọba ipinlẹ Ọṣun pe o mọ̀ọ̀mọ̀ n fi ẹsẹ falẹ lori igbesẹ lati rọpo ọba Joseph Oloyede ti wọn ran lẹwọn lorilẹede Amẹrika lori ẹsun jibiti.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Ọba Oloyede to jẹ ẹni ọdun mejilelọgọta di ero ẹwọn lẹyin ti Onidajọ Christopher A. Boyko ran an lẹwọn ko lọ fi aṣọ penpe roko ọba fun oṣu mẹrindinlọgọta.

Ohun to ṣẹlẹ si itẹ Apetumodu ti n mu ipenija ba ilu Ipetumodu - Idile Oye ilu Ipetumodu

Ọmọọba Dele Oyebade to ka iwe apilẹkọ wọn lasiko ipade naa sọ pe iwe idajọ ile ẹjọ naa ti ijọba beere fun ti wa lọwọ awọn, awọn si ti fun ijọba, sibẹ ijọba ipinlẹ naa kọ jalẹ lati jawe sobi yiyọ ọ.

O ni igbesẹ yii ti ta ẹrẹ ati iwọsi si apeere naa ati gbogbo idile oye ninu ilu naa.

Oni ni Ọjọbọ̀. A si n fun ijọba ipinlẹ yii ni gbendeke ọjọ meje lati gbe igbesẹ lori ohun ti a n beere fun, ki wọn si kede ṣiṣofo ori itẹ Apetumọdu."

O ni ipenija nla ni ilu naa n koju bayii nitori awọn awuyewuye to so rọ mọ aga apetumọdu lọwọ yii.