Bàbá gbogbo ayé ni Olúbàdàn àmọ́ yóò ṣá fara mọ́ ẹnìkan láàrin àwa Olùdíje - Sarafadeen Alli
Oludije sipo gomina nipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo ọdun to n bọ, Oloye Sarafadeen Alli, ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe ọmọ Ibadan bii toun ni awọn yoku tawọn jọ n dupo gomina ipinlẹ Oyo, o da oun loju pe oun ni gbogbo Ibadan yoo dibo fun.
Ẹ o ranti pe o le ni oludije mẹwaa to fife han lati dupo gomina ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, ninu wọn ni Adebayo Adelabu, Rauf Aderemi, Oyedele Akeem, Akeem Agbaje atawọn miran.
Amọ nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Oloye Sarafadeen Alli sọ pe APC gan-an lo fa oun kalẹ, ti Olubadan Ladoja naa si faramọ ọn, nitori ibaṣepọ to ti wa laarin awọn tẹlẹ.
Ni itẹsiwaju alaye rẹ nipa pe Olubadan Ladoja fẹran rẹ, Alli sọ pe Baba gbogbo aye ni Olubadan, ọba naa ko si kopa ninu oṣelu mọ.
O ni ṣugbọn Kabiyesi mọ ẹni to daa ju ninu awọn oludije asiko yii.
O fi kun un pe oun ti ba Olubadan ṣiṣẹ ri, ọba naa si ti mọ boun ṣe dangajia to lo ṣe nigbagbọ ninu oun.
Oloye Alli sọ pe:
"Ibaṣepọ̀ mi pẹ̀lú Olubadan ló jẹ́ kí wọ́n fẹ́ràn mi nínú gbogbo àwá tí à ń dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo.



