Àwọn 'ọlọ́pàá' tó fẹ́ wá fi tipá gbé mi gbá ìdí ìbọn gbá ìyàwó mi, wọ́n sì bá oyún inú rẹ̀ jẹ́ – Tani Olohun
Àwọn 'ọlọ́pàá' tó fẹ́ wá fi tipá gbé mi gbá ìdí ìbọn gbá ìyàwó mi, wọ́n sì bá oyún inú rẹ̀ jẹ́ – Tani Olohun
Published
Ifatimileyin Adeagbo ti ọpọ eeyan mọ si Tani Ọlọhun ti ṣalaye pe awọn ọlọpaa to wa fi tipa gbe oun ni ile lọ si Ilọrun ti ba oyun jẹ mọ iyawo oun ninu nibi ti wọn ti n gbiyanju ati fi tipatipa gbe oun.
Tani Olohun sọ eyi ninu ifọrọwerọ pẹlu akoroyin BBC News yoruba nilu Ibadan.
O ni kikugiri ti awọn eeyan naa ti wọn pe ara wọn ni ọlọpaa ku giri si oun ni kete ti wọn wọ ile oun loun ti wo pe awọn wọnyii ko le jẹ agbefọba pẹlu ihuwa sii wọn lai jẹ wi pe wọn ṣe afihan iwe ipẹjọ kankan ṣaaju.



