Soun Ogbomoso ti pín ìlú yẹ́lẹyẹ̀lẹ pẹ̀lú ìwà kíìgbọ́-kìígbà rẹ̀, èmi ò sì lè báa ṣiṣẹ́ mọ́ ni mo ṣe kọ̀wé fipò Máyégún sílẹ̀ -Sẹ́nétọ̀ Adeseun

Àkọlé fídíò, Mo wulẹ̀ ti fi oyè ọ̀hún sílẹ̀ -Sẹ́nétọ̀ Adeseun fèsì sí ìgbésẹ̀ Ṣọ̀ún Ogbomoso tó ní kó ṣe gáfárà fún oyè tí wọ́n fi jẹ
Soun Ogbomoso ti pín ìlú yẹ́lẹyẹ̀lẹ pẹ̀lú ìwà kíìgbọ́-kìígbà rẹ̀, èmi ò sì lè báa ṣiṣẹ́ mọ́ ni mo ṣe kọ̀wé fipò Máyégún sílẹ̀ -Sẹ́nétọ̀ Adeseun

Pẹlu gbogbo gbun-gbun-gbun to n waye laarin Ṣọun ilu Ọgbomọṣọ ati Sẹnetọ Ayọ̀ade Adeṣeun to jẹ Mayegun ilu naa, eyi to ti wa di iṣu ata yan-an-yan bayii to bẹẹ gẹ ti Kabiyesi fi kede pe oun ti gba oye Mayegun kuro lọwọ Sẹnetọ fun saa yii na.

Ko pẹ pupọ lẹyin ti Ọba Ghandi Adeoye kede eyi ti Sẹnetọ Adeṣeun funrarẹ fi bọ sita lati kede pe oun gan ti kọwe fi oye naa silẹ paapaa.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ ninu fọnran yii, Sẹnetọ Adeṣeun ni oun ti 'binu fi oye naa silẹ, mo finufindọ bun wọn.

Ki ni ipilẹ ọrọ yii gan?

Ninu ifọrọwerọ rẹ, Adeṣeun sọ pe Ṣọun ana, Ọba Oyewunmi Ajagungbade III lo fi oye naa da oun lọla ni nnkan bii ọdun marun un sẹyin to si jẹ kayeefi fun oun pe ọba Ghandi le wa sọ pe ki oun yẹra fun oye naa na.

O ni nigba ti oun wo saakun rẹ wo loun war ii pe kikọ ti ara Ṣọun Adeoye kọ awọ̀n imọran ti oun n gba wọn lo mu ki o gbe igbesẹ naa.

Sẹnetọ Adeṣeun ni ireti ọpọ araalu ni pe asiko Ọba Adeoye Ghandi gẹgẹbi ẹni to ti jade kaakiri agbaye yoo mu idagbasoke ba ilu Ogbomọṣọ, amọṣa nisinsinyii, ohun ti awọn ri ni pe 'ọba to maa n gba imọran ara rẹ nikan ni'.

'Eyi ti wọn n ṣe yii pe awọn ni ki n lọ rọọkun naa, ki wọn maṣe wulẹ jẹ ki n lọ rọọkun, emi gan o fẹ ipo yẹn mọ nitori ẹni ti eeyan ba ṣiṣẹ pọ tik ii fi ọrọ lọ eeyan; a kii ṣe ọmọ kekere ninu ohun ti an ṣe yii…'

O fi kun un pe Kabiyesi Ọba Ghandi Laooye ti pin ilu Ogbomọṣọ yẹlẹyẹlẹ nipa ihuwasi rẹ lasiko to yẹ ki wọn maa wa alaafia ilu, ki gbogbo ilu maa ri wọn sa ba ko si maa ko awọn araalu jọ.

'Ọba to yẹ ko maa ko gbogbo eeyan jọ, ki wọn olubadamọran ni ilu, awọn lo wa jẹ okuta idigbolu fun alaafia niluu Ogbomọṣọ.'

O tọka si awọn igbesẹ Ọba Ghandi Laoye lori ọrọ oye Imaamu agba ilu Ogbomọṣọ ati igbimọ akoso ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ ti a mọ si Ogbomọṣọ parapọ gẹgẹbi ara awọn apẹrẹ ihuwasi Ṣọun ti ko le jẹ ki oun le baa ṣiṣẹ pọ mọ gẹgẹbi oloye.