Obìnrin tó bá fẹ́ fẹ́ mi gbọ́dọ̀ ṣetán láti san owó orí mi – VJ Adams
Gbajugbaja sọrọsọrọ Ibrahim Adebọla Adams ṣalaye ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba pe oun ko kanju lati ṣe igbeyawo nitori pe oun fẹ farabalẹ daadaa.
VJ Adams ni lootọ awọn obi oun fẹ ki oun ti ni iyawo, ṣugbọn gẹgẹbi abigbẹyin, aṣiri oun bo nitori pe wọn ti ni awọn ọmọọmọ nipasẹ awọn ẹgbọn oun mẹrin ti wọn ti niyawo ṣaaju.
Bakan naa lo sọrọ lori awọn itọni ẹsin ti awọn obi rẹ fun un atawọn nnkan miran bii nini iyawo mẹrin lai yannana awọn ilakalẹ ti iwe mimọ fi tii lẹgbẹ.
Awọn to n wo fidio iwa ibajẹ lori ayelujara lo ro 'olodo uprising' lagbara – VJ Adams
Lori ọrọ to n ja ranyinranyin lori ayelujara nipa 'Olodo uprising', VJ Adams ni ko si ẹbi lọwọ awọn to n gbe ọrọ naa jade bikoṣe lọwọ awọn araalu to n wo fọnran wọn.
O ni awọn eeyan to n wo awọn fọnran to n fọnrere idibajẹ lori ayelujara naa lo n ṣe koriya ati ironilagbara fun awọn to n pe ara wọn ni 'olodo uprising'.



