'Àwa òṣèré àná ti ṣiṣẹ́ tán, fìkan-makan ló kù tí wọ́n n ṣe lóde òní'
'Àwa òṣèré àná ti ṣiṣẹ́ tán, fìkan-makan ló kù tí wọ́n n ṣe lóde òní'
Published
Agba osẹre, Mamoudou Akanbi Ehysse, ti ọpọ tun mọ si Mr Okeke, ti sọ fun BBC pe ọna to pọ ni Ọlọrun ti fi itan kikọ kẹ oun – ninu bọọlu gbigba, ere itage, ati gẹgẹ bi oloye ni aafin ọba.
Ọgbẹni Okeke sọ pe awọn osẹre nigba atijọ, to fi mọ awọn akọrin, lo ti ṣe ere tan.
O ni amulumala lo ku lode oni, nitori pe pupọ ninu awọn ere ati orin ti wọn n gbe jade lo n ṣi awọn ọmọde lọna.
“Nigba atijọ, awọn iṣẹlẹ inu ile kaluku la fi n ṣe ere.”
Yatọ si ere ori itage ṣiṣe, ọMr Okeke tun gba bọọlu fun ilẹ Dahomey, to ti di orilẹ-ede Benin Republic bayii, laarin 1960 si 1970.
O ni owo ni awọn agbabọọlu ode oni n gbá, kii sẹ bọọlu.





