You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo kókó ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ lásìkò àbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí Jos, bó ṣe ní kí wọn ri ẹ̀rọ̀ ayàwòrán 5000 sáwọn ojú pópó yíká ìlú náà
Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti bá àwọn èèyàn ìlú Jos, olú ìlú ìpínlẹ̀ Plateau kẹ́dùn lórí ìkọlù àti ìpànìyàn tó wáyé ní ìlú náà.
Ní ọjọ́bọ̀ ni Tinubu ṣàbẹ̀wò sí ìlú Jos látàrí ìpànìyàn tó wáyé níbẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú àti ọjọ́rú níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Tinubu, nígbà tó ń bá àwọn èèyàn náà kẹ́dùn sọ pé kò sí iye owó tàbí ọ̀rọ̀ tí àwọn fẹ́ sọ fún àwọn èèyàn náà tó máa ra ẹ̀mí àwọn èèyàn wọn padà.
Ó ní òun kò kàn yọjú sí ìpínlẹ̀ Plateau láti bá àwọn èèyàn náà kẹ́dùn lásán, ó ní àbẹ̀wò náà jẹ́ ọ̀nà láti wá ojútùú sí làásìgbò tó máa ń wáyé ní agbègbè náà ní gbogbo ìgbà.
"Mo mọ ohun tí ẹ̀ ń kojú, ẹ kò yan àwọn adarí láti máa bá a yín kẹ́dùn, sọ yín di opó àti ẹni tí kò láya nílé mọ̀"
Aarẹ Bola Tinubu tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe "Mo mọ ohun tí ẹ̀ ń kojú, ẹ ò yan àwọn adarí láti máa bá a yín kẹ́dùn, sọ yín di opó àti ẹni tí kò láya nílé mọ̀."
Ó sọ pé òun ń ṣèlérí pé irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní wáyé mọ́ ní ìlú náà, tó sì darí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ṣàwárí àwọn tó wà nídìí ìkọlù náà, kí wọ́n sì fí wọn jófin.
Bákan náà ló tún ṣèlérí pé ìjọba máa fi ẹ̀rọ ayàwòrán ẹgbẹ̀rún márùn-ún sí gbogbo òpópónà lójúnà àti mú ètò ààbò ìpínlẹ̀ Plateau gbópọn síi.
Nígbà tó ń bá àwọn aláṣẹ ìpínlẹ̀ Jos sọ̀rọ̀, ààrẹ ní láti ìgbà pípẹ́ ni irú ìkọlù yìí ti máa ń wáyé ní ìlú Jos, tó sì ní òun kò fẹ́ torí ìkọlù tún balẹ̀ sí ìlú Jos mọ́.
Ààrẹ tún darí rẹ̀ pé kí wọ́n gba àwọn aṣọ́gbó ẹgbẹ̀rún kan káàkiri ìpínlẹ̀ Plateau láti máa ṣe ìrànwọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ ètò ààbò.
Ki lo gbe aarẹ Tinubu lọ silu Jos?
Ibẹru-bojo tun gbalẹ niluu Jos tii ṣe olu ilu ipinlẹ Plateau lẹyin iroyin kan to sọ pe rogbodiyan mii tun bẹ silẹ l'Ọjọru ọjọ kinni oṣu Kẹrin ọdun yii nibi ti eeyan kan ti ku.
Eleyii ṣẹlẹ lẹyin tawọn agbebọn ti kọkọ ṣekupa eeyan mẹrindinlọgbọn lẹkun ariwa ilu naa ti ijọba si ti kede ofin konle-o-gbele latari isẹlẹ naa.
Iroyin ti a gbọ ni pe awọn eeyan kan tun ti ṣekupa eeyan kan eyi to mu ki ibẹru-gbojo tun gbalẹ sii.
Ohun ti awọn araalu sọ ni pe lagbegbe Nasarawa Gwom ni o ṣee ṣe ki awọn ọdọ kan ti ṣekupa eeyan naa.
Iṣẹlẹ yii ni a gbọ pe o ti jẹ kawọn eeyan to n gbe lẹgbẹ agbegbe naa bii Farin Gada, Terminus, Gada Bui ati Filin Ball sa kuro nibi ti wọn n gbe.
Ọjọru ni ijọba dẹ ofin konle-o-gbele ti wọn ni kawọn araalu maa rin lọsan
Fidio kan ti BBC ri lori itakun ayelujara ṣafihan bawọn eeyan ṣe n sa asala fun ẹmi wọn eyi to fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.
Awọn agbebọn ṣekọlu si agbegbe Angwan Rukuba ati Gari Ya Waye lẹkun ariwa ilu Jos to sun mọ ile ẹkọ giga fasiti UNIJOS.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni nnkan bii ago meje aabọ irọlẹ lawọn janduku agbebọn naa de, ti wọn ṣi ṣina ibọn bolẹ lagbegbe naa.
Eeyan mejila nile iṣẹ ọlọpaa kọkọ sọ pe o ku ninu ikọlu naa, nigba to ya ni iroyin gbe e jade pe awọn to ti ku ti di eeyan mẹrindinlọgbọn.
Lẹyin ikọlu naa ni Gomina Caleb Mutfwang ipinlẹ Plateau kede ofin konle-o-gbele fun ọjọ meji ni ẹkun ariwa ilu Jos bẹrẹ lati oru ọjọ Aiku to kọja.
Lanaa Ọjọru ni ijọba dẹ ofin naa ti wọn si ni kawọn araalu maa rin lọsan.
Ẹgbẹ agbesunmọmi kankan ko ti sọ pe awọn lawọn ṣe ikọlu naa, awọn janduku agbebọn ni ijọba pe awọn to ṣe ikọlu naa.
Oriṣiiriṣii ikọlu bayii ti waye lọpọ igba niluu Jos laarin bii ogun ọdun sẹyin.
Ọpọ igba si lawọn eeyan to n gbe nibi ti ikọlu naa ba ti ṣẹlẹ maa n gbẹsan, eyi to maa n da rogbodiyan silẹ.
Tinubu fagile irinajo rẹ si Ogun, morile ilu Jos lẹyin iṣẹlẹ ipaniyan to waye nibẹ
Ẹwẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti sun abẹwo rẹ si ipinlẹ Ogun lonii Ọjọbọ siwaju lati le ṣabẹwo ibanikẹdun si ilu Jos lẹyin ikọlu to waye nibẹ nibi ti eeyan mẹrindinlọgbọn ti padanu ẹmi wọn.
Tinubu gbe igbesẹ yii lẹyin to ṣepade pọ pẹlu Gomina Caleb Mutfwang nileeṣẹ ijọba l'Abuja lanaa Ọjọru lori eto aabo ipinlẹ naa.
Bakan naa ni ọga agba ọlọpaa, Tunji Disu, ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa muba ati ẹka ileeṣẹ ọlọpaa mii lọ si ipinlẹ naa lati pese eto aabo to peye.
Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade to fi sita nirọlẹ Ọjọru.
Onanuga ṣalaye ninu atẹjade naa wi pe Tinubu n lọ siluu Jos lati kẹdun pẹlu ijọba atawọn eeyan ipinlẹ naa lori iṣẹlẹ iṣekupani to waye ni Angwan Rukuba lẹkun ariwa Jos.
Oludamọran aarẹ ni Tinubu yoo lọ silu Eko fun ayajọ Ọjọ Ẹti rere, lati ibẹ si ni yoo ti lọ sibi ifilọlẹ papakọ ofurufu Gateway International Cargo Airport nipinlẹ Ogun lọjọ Abamẹta lopin ọsẹ yii.
Ṣaaju ni Gomina Mutfwang ti sọ fawọn akọroyin pe o ṣee ṣe ki aarẹ ṣabẹwo si ipinlẹ Plateau lati bawọn eeyan ipinlẹ naa kẹdun lori iṣẹlẹ ipaniyan to waye lopin ọsẹ to kọja.
Gomina ni iṣẹlẹ naa jẹ nnkan to ba Aarẹ Tinubu lọkan jẹ gidi gan an, ti o si fẹ wa si ilu Jos fun ra rẹ lati bawọn kẹdun.
Ṣaaju lọjọ Aje ni Tinubu ti kọkọ bu ẹnu ẹtẹ lu ikọlu naa, ti o si ṣeleri pe awọn to wa nidi rẹ yoo foju wina ofin.
Tinubu tun sọ pe oun ranṣẹ pe gomina ipinlẹ Plateau atawọn ọga ileeṣẹ ọmogun to fi mọ ọga ọlọpaa lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ ni ipinlẹ naa.