Olóòtú Ìjọba Senegal Sonko di adarí ilé aṣòfin lẹ́yìn tí Ààrẹ Faye yọ ọ́ nípò

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ile aṣofin orilẹede Senegal ti dibo yan Olootu ijọba orilẹede naa, Ousmane Sonko, gẹgẹ bii adari ile aṣofin, lẹyin ti Aarẹ Bassirou Diomaye Faye yọ ọ nipo lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.
O ti to oṣu meloo kan bayii ti faakaja ti n waye laarin Aarẹ Faye ati Olootu ijọba Sonko.
Lọjọ Aiku ọsẹ yii ni adari ile tẹlẹ fipo rẹ silẹ lati jẹ ki Sonko ti ẹgbẹ oṣelu rẹ, Pastef ni ijokoo to pọ julọ nile aṣofin bọ si ipo naa.
Lanaa ọjọ Aje ni Aarẹ Faye yan onimọ nipa ọrọ aje, Ahmadou Al Aminou Lo, lati rọpo Sonko gẹgẹ bii Olootu ijọba tuntun.
Ibaṣepọ laarin Faye ati Sonko ko dan mọran mọ lati igba ti Sonko ti n tako awọn eto ti ijọba Faye n ṣe lori ọrọ aje Senegal papaa julọ lori gbese ti orilẹede naa jẹ.
Ṣaaju ni Sonko ti sọ pe ọrọ to wa nlẹ da lori oṣelu ati ihuwasi to bofin mu.
Amọ, o ti ṣeleri pe oun ko ni i lo ipo adari ile aṣofin toun wa bayii lati ba ẹnikẹni ja, bi ko ṣe lati ṣe nnkan ti araalu n fẹ.
''Ipo ti Sonko wa bayii le din agbara aarẹ ku, tori ile le ma buwọlu eto ti aarẹ ba fẹ ṣe''
Sonko fikun ọrọ rẹ pe iyọnipo oun gẹgẹ bii Olootu ijọba ko tumọ si pe oun ko wulo mọ lagbo oṣelu.
Ipo ti Sonko wa bayii le din agbara aarẹ ku tori ile le ma buwọlu eto ti aarẹ ba fẹ ṣe.
Aarẹ ko si lagbara lati tu ile aṣofin ka ayafi ti wọn ba ti pe ọdun meji loku lẹyin ti araalu dibo yan wọn.
Sonko, ẹni ọdun mọkanlelaadọta, jẹ oloṣelu ti ọpọ araalu fẹran papaa julọ awọn ọdọ inu ẹgbẹ oṣelu Pastef.
Bo tilẹ jẹ pe Sonko ko tako iyansipo Lo to rọpo rẹ, o ni lara nnkan to fa faakaja laari oun ati aarẹ ni ede-ai-yede lori gbese ti Senegal jẹ.
Gẹgẹ bi aṣofin ẹgbẹ alatako, Sonko tako ọpọ eto ti ijọba Aarẹ ana Macky Sall n ṣe, gẹgẹ bi o ṣe n tako Aarẹ Faye naa.

























