Yoruba Movies: Àwọn òṣèré Yollywood tó ń pàrònú rẹ́

Published

Nínú àwọn apanilẹ́rìín òṣèré Yorùbá yìí, èwo ló ń pa ìrònú rẹ́ fún un yín jù?

Oṣere Adewale Adeoye
Àkọlé àwòrán, Ẹnu pọ bii atakara. Eleso ni wọn mọ ọ si, Adewale Adeoye gangan ni orukọ rẹ. Gbajugbaja ni lagbo ere Yoruba pẹlu ọpọlọpọ awada rẹ ti ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin.
Wale Akorede Okunnu
Àkọlé àwòrán, Wale Akorede Okunnu jẹ ọmọ bibi ilu Ogbomoṣo ni ipinlẹ Oyo ṣugbọn ilu Ibadan ni wọn bi i si. Iṣẹ owo ṣiṣe lo yan laayo ko to kan wọ agbami ere Tiata.
Babatunde Omidina
Àkọlé àwòrán, Baba Suwe ti orukọ rẹ gangan n jẹ Babatunde Omidina jẹ ọmọ bibi ilu Eko ni Ikorodu. Agba oṣere ni Baba Suwe jẹ to si ti dẹrin pẹẹkẹ ọpọlọpọ ninu awọn fiimu agbelewo to ṣe ko to di pe aisan da a lulẹ laipẹ to si ti n dara ya bayii.
Olatayo Omokade
Àkọlé àwòrán, Ọkan lara awọn ọdọ lagbo oṣere ni Olatayo Omokade ti gbogbo eniyan mọ si Ijebu. Lọdun 2019 lo pe ogoji Ọdun. Nipasẹ ile ẹkọ oṣere ti Muyiwa Ademola ni Ijebu lo gba a wọ agbo oṣere.
Alhaji Kareem Adepoju
Àkọlé àwòrán, Agba oṣere ni Alhaji Kareem Adepoju ti ọpọ mọ si Baba Wande. Oṣere, onkọwe, atọkun ni. Ninu ere Ti Oluwa Ni Ile ni irawọ Baba Wande ti yọ to si ti n tan lati igba naa pẹlu awọn awada a-wo-ma-le-e-lọ rẹ.
Olaniyi Mikail Afonja
Àkọlé àwòrán, Olaniyi Mikail Afonja gan an ni Orukọ ti baba ati iya sọ ẹni ti ẹ mọ si Sanyẹri ninu ere Yoruba. Isọwọ pa ni lẹrin rẹ kọja afẹnusọ. Diẹ lara awọn ere to ti ko pa ni Obakeye, Awero, Edun Ara, Jenifa, Opa Kan, Omo Carwash ati bẹẹ bẹẹ lọ.