Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Keere re o, konile o gbọ , ko sọ fun to'ko

Pe ki ni o?

Pe o ti di eewọ bayii fun awọn ọmọ Niajiria lati maa gba fisa lọ ilẹ Amẹrika lati lọ bimọ

Hmmmmm

Ileeṣẹ ijọba Amẹrika ni awọn ko ni maa fun ẹnikẹni ni fisa ilẹ naa mọ pẹlu rongba lati lọ bimọ sibẹ

Lọ soju opo BBC Yoruba fun ekunrẹrẹ

____________________

Ajọ to n ri si ifidimulẹ ofin n'ipinlẹ Ọyọ ti fi kele ofin gbe darandaran kan

To da maalu wọ oko ijoba ti wọn gbin ẹgẹ si niluu Isẹyin

Alukoro ajọ naa, Opeyemi Ogunniyi sọ ninu atẹjade kan pe awọn akẹgbẹ darandaran naa salọ pẹlu awọn maalu wọn

Lọ soju opo wa fun ẹkunrẹrẹ

_____________________

Lorilẹede Angola

Eeyan mẹrin ti ku, ti ẹẹdẹgbẹta mii si dero atimọle lẹyin ifẹhonuhan to waye niluu Luanda

Iwọde naa bẹrẹ lẹyin ti awọn awakọ igboro da iṣẹ silẹ nitori ọwọngogo epo bẹntiro

A gbọ pe bi awọn oluwọde naa ṣe ko igi di oju popo lawọn mii n ja ṣọọbu oniṣọọbu

Lati mọ ẹkunrrẹrẹ