Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Ijọba apapọ ti fesi si awọn ọmọ orilẹede Ghana ti wọn ni ki awọn ọmọ Naijiria pada sorilẹede wọn latari iwa laabi ti wọn n wu nibẹ

Ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okere, NIDCOM sọ pe, awọn ọmọ Naijiria kii ṣe ọdaran bi wọn ṣe sọ, ati pe ọmọ iya kan naa ni Ghana ati Naijiria

_________________________

Lọ soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ

Ẹgbẹ awọn nọọsi lawọn ile iwosan ijọba apapọ kaakiri Naijiria ti bẹrẹ iyanṣẹlodi laarọ oni Ọjọru

Eredi iyanṣẹlodi ọhun ko ṣẹyin ọwọ ti ijọba fi mu owo oṣu atawọn ajẹmọnu mii to tọ si wọn

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn dokita, NMA naa ti sọ pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi tiwọn laipẹ

_________________________

Ni Ivory Coast

Aarẹ Alassane Ouattara ti kede pe oun yoo dije du ipo fun saa kẹrin

Ẹni ọdun mẹtalelọgọrin naa ni ilera oun ti ko duro dede ko le ṣakoba kankan fun ijọba oun

Ọdun 2011 ni Ouattara gba ọpa aṣẹ Ivory Coast lẹyin ogun abẹle to waye nibẹ

Fun ẹkunrẹrẹ