Coronavirus Cases in Africa: Àwọn àràmọ̀ndà ìbomú-bẹnu tó gbòde lásìkò Coronavirus yìí

Published

Akojọpọ aworan alarambara nipa ọna ti awọn eniyan n gba ṣe ibomu-bẹnu nitori coronavirus

Coronavirus
Àkọlé àwòrán, Lati oke de ile ni wọn ti wọ asọ kan naa pẹlu ibomu.
Coronavirus
Àkọlé àwòrán, Arun Coronavirus ti rogo, ẹwu ogun ni wọn fi ṣe.
Eni to fi ike bori
Àkọlé àwòrán, Ike omi ni ọ̀rọ̀ kan fún ẹni yi láti fi dáa bo bo ara rẹ
Coronavirus
Àkọlé àwòrán, kọmu ni awọn tun fi bomu, njẹ eyi le e daabo bo wọn lọwọ arun Coronavirus.
Coronavirus
Àkọlé àwòrán, Ike ni arakunrin yii fi ṣe ibomu ni ti wọn
Eni to de fila ati ibomu
Àkọlé àwòrán, Àwọn àràmọ̀ndà ìbomú-bẹnu tó gbòde lásìkò Coronavirus yìí
Coronavirus
Àkọlé àwòrán, Awọn ti le wọ ike lati ori de ẹnu ni lati koju arun Coronavirus
Aramọnda! Ọgbọn atinuda ni obinrin yii fi ṣe ibomu-bẹnu pẹlu ankara ati gilaasi.
Àkọlé àwòrán, bọAramọnda! Ọgbọn atinuda ni obinrin yii fi ṣe ibomu-bẹnu pẹlu ankara ati gilaasi.
Baba agba yii naa rọra wa ewe to fẹ daada lati daabo bo ara rẹ lọwọ coronavirus
Àkọlé àwòrán, Baba agba yii naa rọra wa ewe to fẹ daada lati daabo bo ara rẹ lọwọ coronavirus
Eni to de fila ati ibomu
Àkọlé àwòrán, Kìí ṣe imú ati ẹni ni eyi n bò, o bfi bori náà ai baa mọ ti kokoro naa bá fẹ́ gba ori wọle
Orin wo ni ka kọ si gbẹdu ibomu-bẹnu onike yi? Abi ẹ o wa tun ri ẹni to fi agadagodo ṣe ibomu-bẹnu.
Àkọlé àwòrán, Orin wo ni ka kọ si gbẹdu ibomu-bẹnu onike yi? Abi ẹ o wa tun ri ẹni to fi agadagodo ṣe ibomu-bẹnu.
Ba o radan, a foobẹ ṣẹbọ ni iya ati ọmọ fi ọrọ ṣe. Ewe ni wọn rọra fi d'ọgbọn sọrọ ara wọn.
Àkọlé àwòrán, Ba o ri adan, a foobẹ ṣẹbọ ni iya ati ọmọ fi ọrọ ṣe. Ewe ni wọn rọra fi d'ọgbọn sọrọ ara wọn.
Toju-toju ni ọkunrin yii fi ibomu-bẹnu bo. Koju o ma ribi 'Koro'lo fi ọrọ ṣe
Àkọlé àwòrán, Toju-toju ni ọkunrin yii fi ibomu-bẹnu bo. Koju o ma ribi 'Koro'lo fi ọrọ ṣe
Kini ka tun ti pe ibomu-bẹnu yii o? A fi bi igba ti eeyan n lọ sinu oṣupa ni ọkunrin yii bo imu, oju ati ẹnu rẹ.
Àkọlé àwòrán, Kini ka tun ti pe ibomu-bẹnu yii o? A fi bi igba ti eeyan n lọ sinu oṣupa ni ọkunrin yii bo imu, oju ati ẹnu rẹ.
Coronavirus
Àkọlé àwòrán, Ewe ni mama ti le lo fi bo ẹu wọn lọwọ arun Coronavirus
Eyi tun leku. Boya awọn obinrin ti ẹ le maa lo o pẹlu aṣọ iyawo fun ayẹyẹ igbeyawo wọn. Abi ki lẹ ro?
Àkọlé àwòrán, Eyi tun leku. Boya awọn obinrin ti ẹ le maa lo o pẹlu aṣọ iyawo fun ayẹyẹ igbeyawo wọn. Abi ki lẹ ro?
Ibomu-bẹnu
Àkọlé àwòrán, Ara ọtọ ni ibomu-bẹnu yii ti wọn sẹ bi i kọmu obinrin. Koda, iroyin sọ pe ko pe wakati kan ti wọn ko o sita ti awọn eniyan ti ra a tan lorilẹ-ede Japan