Akanmu Epo Akara, bíríkìlà tó gbé orin Àwúrebe ga, tí ọmọ rẹ̀ tún tẹ́wọ́ gbàá

Akanmu Epo Akara, bíríkìlà tó gbé orin Àwúrebe ga, tí ọmọ rẹ̀ tún tẹ́wọ́ gbàá

Dauda Akanmu epo Akara jẹ gbajumọ olorin to milẹ titi lawọn ọdun sẹyin.

Ọdun 1943 ni wọn bii, to si kọ iṣẹ birikila ki o to di pe o bẹrẹ si ni kọ orin Awurebe.

Orin Awurebe jẹ ọkan lara awọn orin to gbajumọ nigba naa nilẹ Yoruba.

Suliat Epo Akara, ọmọ Akanmu epo Akara to n kọ Awurebe

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Suliat to jẹ ọmọ Alhaji Akanmu epo akara ṣalaye pe o wu oun lati gbe iṣẹ baba oun larugẹ ni ati wi pe gẹgẹbi obinrin, awọn ipenija ti wa, ṣugbọn oun n lo wọn gẹgẹbi ọpakutẹlẹ fun itẹsiwaju afojusun oun ni.